Númérì 9:1-23
9 Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì ní ọdún kejì tí wọ́n jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, ní oṣù kìíní,+ pé:
2 “Wàyí o, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pèsè ẹbọ ìrékọjá+ sílẹ̀ ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀.+
3 Ọjọ́ kẹrìnlá ní oṣù yìí láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì + ni kí ẹ pèsè rẹ̀ sílẹ̀ ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é ni kí ẹ pèsè rẹ̀ sílẹ̀.”+
4 Nítorí náà, Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n máa pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀.
5 Nígbà náà ni wọ́n pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ ní oṣù kìíní, ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù náà láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì , ní aginjù Sínáì. Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún Mósè, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe.+
6 Wàyí o, àwọn ọkùnrin kan báyìí wà tí ọkàn+ ẹ̀dá ènìyàn ti sọ di aláìmọ́, tí wọn kò fi lè pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ ní ọjọ́ yẹn. Nítorí náà, wọ́n wá sọ́dọ̀ Mósè àti Áárónì ní ọjọ́ náà.+
7 Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn wí fún un pé: “Ọkàn ẹ̀dá ènìyàn ti sọ wá di aláìmọ́. Èé ṣe tí a ó fi dí wa lọ́wọ́ mímú ọrẹ ẹbọ+ wá fún Jèhófà ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?”
8 Látàrí èyí, Mósè wí fún wọn pé: “Ẹ dúró síbẹ̀ yẹn, kí ẹ sì jẹ́ kí n gbọ́ ohun tí Jèhófà yóò pa láṣẹ nípa yín.”+
9 Nígbà náà ni Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:
10 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Bí ó bá tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé ọkàn+ kan sọ ọkùnrin èyíkéyìí nínú yín tàbí nínú àwọn ìran yín di aláìmọ́ tàbí pé ó rin ìrìn àjò jíjì nnà, kí òun pẹ̀lú pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ fún Jèhófà.
11 Ní oṣù kejì ,+ ní ọjọ́ kẹrìnlá láàárín àwọn ìrọ̀lẹ́ méjèèjì , ni kí wọ́n pèsè rẹ̀ sílẹ̀. Kí wọ́n jẹ ẹ́ pa pọ̀ pẹ̀lú àkàrà aláìwú àti ewébẹ̀ kíkorò.+
12 Kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí èyíkéyìí nínú rẹ̀ ṣẹ́ kù títí di òwúrọ̀,+ kí wọ́n má sì ṣe fọ́ egungun kankan nínú rẹ̀.+ Ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ìlànà àgbékalẹ̀ ìrékọjá ni kí wọ́n pèsè rẹ̀ sílẹ̀.+
13 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà bá mọ́ tàbí tí kò ṣẹlẹ̀ pé ó rin ìrìn àjò, tí ó sì ṣàìnáání pípèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀, nígbà náà, ọkàn yẹn ni kí a ké kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀,+ nítorí pé ọrẹ ẹbọ Jèhófà ni kò mú wá ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀. Ọkùnrin yẹn yóò dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+
14 “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àtìpó kan ń ṣe àtìpó lọ́dọ̀ yín, kí òun pẹ̀lú pèsè ẹbọ ìrékọjá sílẹ̀ fún Jèhófà.+ Ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àgbékalẹ̀ ìrékọjá àti ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é ni kí ó ṣe é.+ Ìlànà àgbékalẹ̀ kan ni kí ó wà fún yín, fún àtìpó àti fún ọmọ ìbílẹ̀ ti ilẹ̀ náà.’”+
15 Wàyí o, ní ọjọ́ gbígbé àgọ́ ìjọsìn+ nà ró, àwọsánmà bo àgọ́ ìjọsìn ti àgọ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí,+ ṣùgbọ́n ní ìrọ̀lẹ́ ohun tí ó fara jọ iná+ ń bá a lọ láti wà lórí àgọ́ ìjọsìn títí di òwúrọ̀.
16 Bí ó ṣe ń bá a lọ nígbà gbogbo nìyẹn: Àwọsánmà a bò ó ní ọ̀sán, àti ohun tí ó fara jọ iná ní òru.+
17 Nígbàkigbà tí àwọsánmà bá sì gòkè kúrò lórí àgọ́ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a ṣí kété lẹ́yìn ìgbà náà,+ ibi tí àwọsánmà náà bá sì gbé, ibẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a dó sí.+
18 Nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a ṣí, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì dó.+ Ní gbogbo ọjọ́ tí àwọsánmà bá fi gbé lórí àgọ́ ìjọsìn, wọn a wà ní ibùdó.
19 Nígbà tí àwọsánmà bá sì dúró pẹ́ lórí àgọ́ ìjọsìn ní ọjọ́ púpọ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú a máa pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe wọn mọ́ sí Jèhófà pé kí wọ́n má ṣe ṣí.+
20 Nígbà mìíràn àwọsánmà a sì máa bá a lọ fún ọjọ́ díẹ̀ lórí àgọ́ ìjọsìn. Nípa àṣẹ ìtọ́ni+ Jèhófà, wọn a wà ní ibùdó, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì ṣí.
21 Nígbà mìíràn àwọsánmà+ a sì máa bá a lọ láti ìrọ̀lẹ́ di òwúrọ̀; àwọsánmà náà a sì gbé ara rẹ̀ sókè ní òwúrọ̀, wọn a sì ṣí. Ì báà jẹ́ ọ̀sán tàbí òru ni àwọsánmà náà gbé ara rẹ̀ sókè, wọn a ṣí pẹ̀lú.+
22 Ì báà jẹ́ ọjọ́ méjì tàbí oṣù kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ sí i ni àwọsánmà fi dúró pẹ́ lórí àgọ́ ìjọsìn nípa gbígbé lórí rẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì a wà ní ibùdó, wọn kì yóò sì ṣí, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, wọn a ṣí.+
23 Nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a dó, nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà, wọn a sì ṣí. Wọ́n pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe+ wọn mọ́ sí Jèhófà nípa àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè.+

