Númérì 29:1-40

29  “‘Àti ní oṣù keje, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, kí ẹ ṣe àpéjọpọ̀+ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú.+ Kí ó jẹ́ ọjọ́ fífun kàkàkí fún yín.+  Kí ẹ sì fi ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá+ rúbọ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun fún òórùn amáratuni sí Jèhófà;  àti ọrẹ ẹbọ ọkà wọn ti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ìdá mẹ́wàá mẹ́ta fún akọ màlúù náà, ìdá mẹ́wàá méjì fún àgbò+ náà,  àti ìdá mẹ́wàá kan fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ méjèèje;  àti akọ ọmọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún yín;+  yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun+ oṣooṣù àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun+ ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe wọ́n, gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni, ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà.+  “‘Àti ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni kí ẹ ṣe àpéjọpọ̀+ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ọkàn+ yín níṣẹ̀ẹ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú.+  Kí ẹ sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan+ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí òórùn amáratuni. Kí wọ́n jẹ́ àwọn tí ara wọn dá ṣáṣá fún yín.+  Àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà wọn ti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ìdá mẹ́wàá mẹ́ta fún akọ màlúù náà, ìdá mẹ́wàá méjì fún àgbò+ náà, 10  ìdá mẹ́wàá ní bí wọ́n ṣe tẹ̀ léra fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ méjèèje; 11  ọmọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ètùtù+ àti ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn. 12  “‘Àti ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún nínú oṣù keje,+ kí ẹ ṣe àpéjọpọ̀+ mímọ́. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú,+ kí ẹ sì ṣe ayẹyẹ àjọyọ̀ sí Jèhófà fún ọjọ́ méje.+ 13  Kí ẹ sì mú ẹgbọrọ akọ màlúù mẹ́tàlá, àgbò méjì , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun,+ ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà. Kí wọ́n jẹ́ àwọn tí ara wọn dá ṣáṣá.+ 14  Àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ọkà wọn ti ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ìdá mẹ́wàá mẹ́ta fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ màlúù mẹ́tàlá náà, ìdá mẹ́wàá méjì fún àgbò kọ̀ọ̀kan nínú àwọn àgbò+ méjèèjì , 15  àti ìdá mẹ́wàá fún akọ ọ̀dọ́ àgùntàn kọ̀ọ̀kan nínú àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn+ mẹ́rìnlá náà; 16  àti ọmọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 17  “‘Àti ní ọjọ́ kejì , ẹgbọrọ akọ màlúù méjì lá, àgbò méjì , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá;+ 18  àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún àwọn akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é;+ 19  àti ọmọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn. 20  “‘Àti ní ọjọ́ kẹta, akọ màlúù mọ́kànlá, àgbò méjì , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá;+ 21  àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún àwọn akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é; 22  àti ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀. 23  “‘Àti ní ọjọ́ kẹrin, akọ màlúù mẹ́wàá, àgbò méjì , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá;+ 24  ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún àwọn akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é;+ 25  àti ọmọ ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun+ ìgbà gbogbo, ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 26  “‘Àti ní ọjọ́ karùn-ún, akọ màlúù mẹ́sàn-án, àgbò méjì, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá;+ 27  àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún àwọn akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é;+ 28  àti ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 29  “‘Àti ní ọjọ́ kẹfà, akọ màlúù mẹ́jọ, àgbò méjì , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá;+ 30  àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún àwọn akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é;+ 31  àti ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 32  “‘Àti ní ọjọ́ keje, akọ màlúù méje, àgbò méjì , akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́rìnlá tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá;+ 33  àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún àwọn akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe wọ́n;+ 34  àti ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ rẹ̀. 35  “‘Àti ní ọjọ́ kẹjọ, kí ẹ ṣe àpéjọ+ ọ̀wọ̀. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe irú iṣẹ́ kankan tí ó ní òpò nínú.+ 36  Kí ẹ sì mú akọ màlúù kan, àgbò kan, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méje tí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, tí ara wọn dá ṣáṣá+ wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ àfinásun, ti òórùn amáratuni sí Jèhófà; 37  àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ wọn àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ wọn fún akọ màlúù, àgbò àti àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn nípa iye wọn ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é;+ 38  àti ewúrẹ́ kan gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo àti ọrẹ ẹbọ ọkà rẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ ohun mímu rẹ̀.+ 39  “‘Ìwọ̀nyí ni ẹ̀yin yóò fi rúbọ sí Jèhófà ní àwọn àjọyọ̀+ yín abágbàyí, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ ẹbọ ẹ̀jẹ́+ yín àti àwọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe+ yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ yín àti àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà+ yín àti àwọn ọrẹ ẹbọ ohun mímu+ yín àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀ yín.’”+ 40  Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé