Númérì 26:1-65
26 Ó sì ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn òjòjò àrànkálẹ̀+ náà, pé Jèhófà ń bá a lọ láti sọ èyí fún Mósè àti Élíásárì ọmọkùnrin Áárónì àlùfáà pé:
2 “Ẹ ka iye gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ẹni ogún ọdún sókè, ní ìbámu pẹ̀lú ilé àwọn baba wọn, gbogbo àwọn tí ń jáde lọ sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Ísírẹ́lì.”+
3 Mósè àti Élíásárì+ àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn sọ̀rọ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù+ lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò,+ pé:
4 “[Ẹ ka iye wọn] láti ẹni ogún ọdún sókè, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.”+
Wàyí o, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì ni:
5 Rúbẹ́nì, àkọ́bí+ Ísírẹ́lì; àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì: Ti Hánókù+ ìdílé àwọn ọmọ Hánókù; ti Pálù+ ìdílé àwọn ọmọ Pálù;
6 ti Hésírónì+ ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì, ti Kámì+ ìdílé àwọn ọmọ Kámì.
7 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn tí a sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹgbàajì ó dín àádọ́rin.+
8 Ọmọkùnrin Pálù sì ni Élíábù.
9 Àti àwọn ọmọkùnrin Élíábù: Némúẹ́lì àti Dátánì àti Ábírámù. Dátánì+ àti Ábírámù+ yìí jẹ́ àwọn tí a fi ọlá àṣẹ pè nínú àpéjọ, tí wọ́n bá Mósè àti Áárónì jì jàkadì nínú àpéjọ Kórà,+ nígbà tí wọ́n bá Jèhófà jì jàkadì.
10 Nígbà náà ni ilẹ̀ la ẹnu rẹ̀ tí ó sì gbé wọn mì.+ Ní ti Kórà, ó kú nígbà ikú àpéjọ náà nígbà tí iná jó àádọ́ta-lérúgba ọkùnrin run.+ Wọ́n sì wá jẹ́ àpẹẹrẹ.+
11 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ Kórà kò kú.+
12 Àwọn ọmọkùnrin Síméónì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Némúẹ́lì+ ìdílé àwọn ọmọ Némúẹ́lì; ti Jámínì+ ìdílé àwọn ọmọ Jámínì; ti Jákínì+ ìdílé àwọn ọmọ Jákínì;
13 ti Síírà ìdílé àwọn ọmọ Síírà; ti Ṣọ́ọ̀lù+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣọ́ọ̀lù.
14 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Síméónì: ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbọ̀kànlá.+
15 Àwọn ọmọkùnrin Gádì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Séfónì ìdílé àwọn ọmọ Séfónì; ti Hágì ìdílé àwọn ọmọ Hágì; ti Ṣúnì ìdílé àwọn ọmọ Ṣúnì;
16 ti Ósínì ìdílé àwọn ọmọ Ósínì; ti Érì ìdílé àwọn ọmọ Érì;
17 ti Áródù ìdílé àwọn ọmọ Áródù; ti Árélì+ ìdílé àwọn ọmọ Árélì.
18 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọkùnrin Gádì, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+
19 Àwọn ọmọkùnrin Júdà+ ni Éérì+ àti Ónánì.+ Àmọ́ ṣá o, Éérì àti Ónánì kú ní ilẹ̀ Kénáánì.+
20 Àwọn ọmọkùnrin Júdà sì wá jẹ́, nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Ṣélà+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣélà; ti Pérésì+ ìdílé àwọn ọmọ Pérésì; ti Síírà+ ìdílé àwọn ọmọ Síírà.
21 Àwọn ọmọkùnrin Pérésì sì wá jẹ́: Ti Hésírónì+ ìdílé àwọn ọmọ Hésírónì; ti Hámúlù+ ìdílé àwọn ọmọ Hámúlù.
22 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Júdà,+ nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá méjì dínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+
23 Àwọn ọmọkùnrin Ísákárì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Tólà+ ìdílé àwọn Tólà; ti Púfà ìdílé àwọn Púnì;
24 ti Jáṣúbù ìdílé àwọn ọmọ Jáṣúbù; ti Ṣímúrónì+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣímúrónì.
25 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Ísákárì, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá méjì lélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún.+
26 Àwọn ọmọkùnrin Sébúlúnì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Sérédì ìdílé àwọn ọmọ Sérédì; ti Élónì ìdílé àwọn ọmọ Élónì; ti Jálíẹ́lì+ ìdílé àwọn ọmọ Jálíẹ́lì.
27 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Sébúlúnì, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+
28 Àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù+ nípa àwọn ìdílé wọn ni Mánásè+ àti Éfúráímù.
29 Àwọn ọmọkùnrin Mánásè+ ni: Ti Mákírù+ ìdílé àwọn ọmọ Mákírù. Mákírù sì bí Gílíádì. Ti Gílíádì+ ìdílé àwọn ọmọ Gílíádì.
30 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Gílíádì: Ti Yésérì+ ìdílé àwọn ọmọ Yésérì; ti Hélékì ìdílé àwọn ọmọ Hélékì;
31 ti Ásíríélì ìdílé àwọn ọmọ Ásíríélì; ti Ṣékémù ìdílé àwọn ọmọ Ṣékémù;
32 ti Ṣẹ́mídà+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣẹ́mídà; ti Héfà+ ìdílé àwọn ọmọ Héfà.
33 Wàyí o, Sélóféhádì ọmọkùnrin Héfà kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin,+ orúkọ àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì sì ni Málà àti Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà.+
34 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Mánásè, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.+
35 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Éfúráímù+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Ṣútélà+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣútélà; ti Békérì ìdílé àwọn ọmọ Békérì; ti Táhánì+ ìdílé àwọn ọmọ Táhánì.
36 Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọmọkùnrin Ṣútélà: Ti Éránì ìdílé àwọn ọmọ Éránì.
37 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọkùnrin Éfúráímù,+ nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Jósẹ́fù nípa àwọn ìdílé wọn.+
38 Àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Bélà+ ìdílé àwọn ọmọ Bélà; ti Áṣíbélì+ ìdílé àwọn ọmọ Áṣíbélì; ti Áhírámù ìdílé àwọn ọmọ Áhírámù;
39 ti Ṣẹ́fúfámù ìdílé àwọn ọmọ Súfámù; ti Húfámù+ ìdílé àwọn ọmọ Húfámù.
40 Àwọn ọmọkùnrin Bélà wá jẹ́ Áádì àti Náámánì:+ Ti Áádì ìdílé àwọn ọmọ Áádì; ti Náámánì ìdílé àwọn ọmọ Náámánì.
41 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì+ nípa àwọn ìdílé wọn, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ.+
42 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Dánì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Ṣúhámù ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù. Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Dánì+ nípa àwọn ìdílé wọn.
43 Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣúhámù, nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn, jẹ́ ẹgbàá méjì lélọ́gbọ̀n ó lé irínwó.+
44 Àwọn ọmọkùnrin Áṣérì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Ímúnà+ ìdílé àwọn ọmọ Ímúnà; ti Íṣífì+ ìdílé àwọn ọmọ Íṣífì; ti Bẹráyà ìdílé àwọn ọmọ Bẹráyà;
45 ti àwọn ọmọkùnrin Bẹráyà: Ti Hébà ìdílé àwọn ọmọ Hébà; ti Málíkíélì+ ìdílé àwọn ọmọ Málíkíélì.
46 Orúkọ ọmọbìnrin Áṣérì sì ni Sérà.+
47 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Áṣérì,+ nínú àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn: ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+
48 Àwọn ọmọkùnrin Náfútálì+ nípa àwọn ìdílé wọn ni: Ti Jáséélì+ ìdílé àwọn ọmọ Jáséélì; ti Gúnì+ ìdílé àwọn ọmọ Gúnì;
49 ti Jésérì+ ìdílé àwọn ọmọ Jésérì; ti Ṣílẹ́mù+ ìdílé àwọn ọmọ Ṣílẹ́mù.
50 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé Náfútálì+ nípa àwọn ìdílé wọn, àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé egbèje.+
51 Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán ó lé ọgbọ̀n.+
52 Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:
53 “Kí a pín ilẹ̀ náà fún àwọn wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ogún nípa iye orúkọ.+
54 Ní ìbámu pẹ̀lú pípọ̀ iye ni kí o bù sí ogún ẹni, ní ìbámu pẹ̀lú ìkéréníye sì ni kí o dín ogún ẹni kù.+ Kí a fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní ogún ní ìwọ̀n àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀.
55 Kì kì nípasẹ̀ kèké+ ni kí a pín ilẹ̀ náà. Ní ìbámu pẹ̀lú àwọn orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọ́n gba ogún.
56 Nípasẹ̀ ìpinnu kèké ni kí a pín ogún ẹni láàárín àwọn tí ó pọ̀ àti àwọn tí ó kéré.”
57 Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Léfì+ nípa àwọn ìdílé wọn: Ti Gẹ́ṣónì+ ìdílé àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì; ti Kóhátì+ ìdílé àwọn ọmọ Kóhátì; ti Mérárì+ ìdílé àwọn ọmọ Mérárì.
58 Ìwọ̀nyí ni àwọn ìdílé àwọn ọmọ Léfì: ìdílé àwọn ọmọ Líbínì,+ ìdílé àwọn ọmọ Hébúrónì,+ ìdílé àwọn ọmọ Máhílì,+ ìdílé àwọn ọmọ Múṣì,+ ìdílé àwọn ọmọ Kórà.+
Kóhátì+ sì bí Ámúrámù.+
59 Orúkọ aya Ámúrámù sì ni Jókébédì,+ ọmọbìnrin Léfì, ẹni tí aya rẹ̀ bí fún Léfì ní Íjíbítì. Nígbà tí ó ṣe, ó bí Áárónì àti Mósè àti Míríámù arábìnrin wọn fún Ámúrámù.+
60 Lẹ́yìn náà, a bí Nádábù àti Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì+ fún Áárónì.
61 Ṣùgbọ́n Nádábù àti Ábíhù kú nítorí mímú tí wọ́n mú iná aláìbá-ìlànà-mu wá síwájú Jèhófà.+
62 Àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dógún, gbogbo ọkùnrin láti ẹni oṣù kan sókè.+ Nítorí a kò forúkọ wọn sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ nítorí pé a kò ní fún wọn ní ogún kankan láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+
63 Ìwọ̀nyí ni àwọn tí Mósè àti Élíásárì àlùfáà forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Móábù lẹ́bàá Jọ́dánì ní Jẹ́ríkò.+
64 Ṣùgbọ́n nínú àwọn wọ̀nyí kò sí ọkùnrin kan lára àwọn tí Mósè àti Áárónì àlùfáà forúkọ wọn sílẹ̀ nígbà tí wọ́n forúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ ní aginjù Sínáì.+
65 Nítorí pé, Jèhófà ti sọ nípa wọn pé: “Láìkùnà, wọn yóò kú ní aginjù.”+ Nítorí náà, ọkùnrin kan ṣoṣo kò ṣẹ́ kù lára wọn bí kò ṣe Kálébù ọmọkùnrin Jéfúnè àti Jóṣúà ọmọkùnrin Núnì.+

