Númérì 24:1-25

24  Nígbà tí Báláámù wá rí i pé ó dára ní ojú Jèhófà láti súre fún Ísírẹ́lì, òun kò lọ gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá+ láti ṣalábàápàdé àmì èyíkéyìí tí ń fa orí burúkú,+ ṣùgbọ́n ó dojú kọ aginjù.  Nígbà tí Báláámù gbé ojú rẹ̀ sókè tí ó sì rí Ísírẹ́lì tí ó pàgọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà+ rẹ̀, nígbà náà ni ẹ̀mí Ọlọ́run bà lé e.+  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbólóhùn òwe+ rẹ̀, ó sì wí pé: “Àsọjáde Báláámù ọmọkùnrin Béórì, Àti àsọjáde abarapá ọkùnrin pẹ̀lú ojú tí a kò fi èdìdì dì,+  Àsọjáde ẹni tí ń gbọ́ àwọn àsọjáde Ọlọ́run,+ Tí ó rí ìran Olódùmarè+ Nígbà tí ó wólẹ̀ pẹ̀lú ojú tí ó là sílẹ̀:+  Ẹ wo bí àwọn àgọ́ rẹ ti dára tó ní ìrísí, ìwọ Jékọ́bù, àwọn ibùgbé rẹ, ìwọ Ísírẹ́lì!+  Bí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, wọ́n nasẹ̀ dé ọ̀nà jíjì n,+ Bí àwọn ọgbà lẹ́bàá odò.+ Bí àwọn ọ̀gbìn álóè tí Jèhófà gbìn, Bí àwọn kédárì lẹ́bàá omi.+  Omi ń sun láti inú àwọn korobá awọ rẹ̀ méjì , Irúgbìn rẹ̀ sì wà lẹ́bàá omi púpọ̀.+ Ọba+ rẹ̀ pẹ̀lú yóò ga ju Ágágì lọ,+ A ó sì gbé ìjọba rẹ̀ sókè.+  Ọlọ́run ń mú un jáde láti Íjíbítì; Ipa ọ̀nà yíyára ti akọ màlúù ìgbẹ́ ni tirẹ̀.+ Òun yóò jẹ àwọn orílẹ̀-èdè run, àwọn tí ń ni ín lára,+ Yóò sì gé egungun wọn jẹ,+ yóò sì fi àwọn ọfà+ rẹ̀ fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́.  Ó tẹrí ba, ó dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, Àti, bí kìnnìún, ta ní gbójúgbóyà láti ta á jí?+ Àwọn tí ń súre+ fún ọ jẹ́ alábùkún, Àwọn tí ó sì ń fi ọ́ gégùn-ún jẹ ẹni ègún.”+ 10  Látàrí ìyẹn, ìbínú Bálákì ru sí Báláámù, ó sì pàtẹ́wọ́,+ Bálákì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Báláámù pé: “Láti fi àwọn ọ̀tá mi bú+ ni mo ṣe pè ọ́, sì wò ó! ìwọ ti súre fún wọn dé góńgó ní ìgbà mẹ́ta yìí. 11  Wàyí o, máa sá lọ sí ipò rẹ. Mo ti sọ fún ara mi pé láìkùnà, èmi yóò bọlá fún ọ,+ ṣùgbọ́n, wò ó! Jèhófà ti fà ọ́ sẹ́yìn kúrò nínú ọlá.” 12  Ẹ̀wẹ̀, Báláámù wí fún Bálákì pé: “Èmi kò ha sọ fún àwọn ońṣẹ́ rẹ pẹ̀lú tí ìwọ rán sí mi, pé, 13  ‘Bí Bálákì yóò bá fún mi ní ilé rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kì yóò lè ré àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà kọjá lọ ṣe ohun tí ó dára tàbí tí ó burú láti inú ọkàn-àyà mi wá. Ohun yòówù tí Jèhófà bá sọ ni ohun tí èmi yóò sọ’?+ 14  Wàyí o, sì kíyè sí i, èmi ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mi. Wá, jẹ́ kí n fi ohun tí àwọn ènìyàn yìí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ní òpin àwọn ọjọ́+ tó ọ létí.”+ 15  Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbólóhùn òwe+ rẹ̀, ó sì wí pé: “Àsọjáde Báláámù ọmọkùnrin Béórì, Àti àsọjáde abarapá ọkùnrin pẹ̀lú ojú tí a kò fi èdìdì dì,+ 16  Àsọjáde ẹni tí ń gbọ́ àwọn àsọjáde Ọlọ́run,+ Àti ẹni tí ó ń mọ ìmọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ— Ìran Olódùmarè ni ó rí+ Nígbà tí ó wólẹ̀ pẹ̀lú ojú tí ó là sílẹ̀:+ 17  Èmi yóò rí i,+ ṣùgbọ́n kì í ṣe nísinsìnyí; Èmi yóò rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe nítòsí. Dájúdájú, Ìràwọ̀+ kan yóò sì yọ láti inú Jékọ́bù wá, Ọ̀pá aládé kan yóò sì dìde ní tòótọ́ láti inú Ísírẹ́lì.+ Dájúdájú, òun yóò sì fọ́ àwọn ẹ̀bátí orí+ Móábù sí wẹ́wẹ́ Àti egungun agbárí gbogbo àwọn ọmọ ìrúkèrúdò ogun. 18  Édómù yóò sì di ohun ìní,+ Bẹ́ẹ̀ ni, Séírì+ yóò di ohun ìní àwọn ọ̀tá rẹ̀,+ Nígbà tí Ísírẹ́lì ń fi ìgbóyà rẹ̀ hàn. 19  Láti inú Jékọ́bù ẹnì kan yóò sì máa ṣẹ́gun lọ,+ Òun yóò sì pa olùlàájá èyíkéyìí run láti inú ìlú ńlá.”+ 20  Nígbà tí ó wá rí Ámálékì, ó tún gbẹ́nu lé gbólóhùn òwe rẹ̀, ó sì ń bá a lọ wí pé:+ “Ámálékì ni ẹni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè,+ Ṣùgbọ́n òpin rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà yóò jẹ́ àní ìṣègbé rẹ̀.”+ 21  Nígbà tí ó wá rí àwọn Kénì,+ ó tún gbẹ́nu lé gbólóhùn òwe rẹ̀, ó sì ń bá a lọ wí pé: “Àlòpẹ́ ni ibùgbé rẹ, àgbékalẹ̀ sórí àpáta sì ni àpáta gàǹgà ibùjókòó rẹ. 22  Ṣùgbọ́n ẹni tí yóò sun Kénì+ kanlẹ̀ yóò wà. Yóò ti pẹ́ tó tí Ásíríà yóò fi kó ọ lọ ní òǹdè?”+ 23  Ó sì tún gbẹ́nu lé gbólóhùn òwe rẹ̀, ó sì ń bá a lọ wí pé: “Ègbé! Ta ni yóò là á já nígbà tí Ọlọ́run bá mú un wá?+ 24  Àwọn ọkọ̀ òkun yóò sì wá láti etí òkun Kítímù,+ Wọn yóò sì ṣẹ́ Ásíríà+ níṣẹ̀ẹ́ dájúdájú, Wọn yóò sì ṣẹ́ Ébérì níṣẹ̀ẹ́ ní tòótọ́. Ṣùgbọ́n òun náà yóò ṣègbé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” 25  Lẹ́yìn ìyẹn, Báláámù dìde, ó sì lọ, ó sì padà+ sí ipò rẹ̀. Bálákì pẹ̀lú sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé