Númérì 23:1-30
23 Nígbà náà ni Báláámù wí fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ+ méje fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí.”
2 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Bálákì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Báláámù ti wí. Lẹ́yìn ìyẹn, Bálákì àti Báláámù fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.+
3 Báláámù sì ń bá a lọ láti wí fún Bálákì pé: “Dúró lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun+ rẹ, sì jẹ́ kí n lọ. Bóyá Jèhófà yóò kàn sí mi, kí ó sì pàdé mi.+ Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ohun yòówù ti òun yóò fi hàn mí, ni èmi yóò sọ fún ọ dájúdájú.” Nítorí náà, ó lọ sí òkè kékeré dídán borokoto kan.
4 Nígbà tí Ọlọ́run kàn sí Báláámù,+ nígbà náà ni ó wí fún Un pé: “Mo gbé pẹpẹ méje náà kalẹ̀ ní ẹsẹẹsẹ, mo sì tẹ̀ síwájú láti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.”+
5 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jèhófà fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu Báláámù,+ ó sì wí pé: “Padà tọ Bálákì lọ, èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò sọ.”+
6 Nítorí náà, ó padà tọ̀ ọ́ lọ, sì wò ó! òun àti gbogbo àwọn ọmọ aládé Móábù dúró lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀.
7 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbólóhùn òwe+ rẹ̀, ó sì wí pé:
“Láti Árámù+ ni Bálákì ọba Móábù ti gbìyànjú láti mú mi wá,
Láti àwọn òkè ńlá ìlà-oòrùn:
‘Wá, bá mi gégùn-ún fún Jékọ́bù.
Bẹ́ẹ̀ ni, wá, dá Ísírẹ́lì lẹ́bi.’+
8 Báwo ni mo ṣe lè fi àwọn tí Ọlọ́run kò fi bú bú?+
Báwo sì ni mo ṣe lè dá àwọn tí Jèhófà kò dá lẹ́bi ní ẹ̀bi?+
9 Nítorí láti orí àwọn àpáta ni mo ti rí wọn,
Láti àwọn òkè kéékèèké ni mo sì ti rí wọn.
Wọ́n pàgọ́ síbẹ̀ ní àdádó gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan,+
Wọn kò sì ka ara wọn mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.+
10 Ta ni ó ti ka iye àwọn egunrín ekuru Jékọ́bù,+
Ta sì ni ó ti ka ìdá mẹ́rin Ísírẹ́lì?
Jẹ́ kí ọkàn mi kú ikú àwọn ẹni adúróṣánṣán,+
Sì jẹ́ kí òpin mi rí gẹ́gẹ́ bí tiwọn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”+
11 Látàrí èyí, Bálákì wí fún Báláámù pé: “Kí ni ohun tí ìwọ ṣe sí mi? Kí o lè fi àwọn ọ̀tá mi bú ni mo ṣe mú ọ wá, sì kíyè sí i ìwọ tí súre fún wọn dé góńgó.”+
12 Ẹ̀wẹ̀, ó dáhùn, ó sì wí pé: “Kì í ha ṣe ohun yòówù tí Jèhófà bá fi sí mi ní ẹnu ni èmi yóò kíyè sí láti sọ bí?”+
13 Nígbà náà ni Bálákì wí fún un pé: “Jọ̀wọ́, bá mi ká lọ sí ibòmíràn láti ibi tí ìwọ ti lè rí wọn. Kì kì ìkángun wọn ni ìwọ yóò rí,+ ìwọ kì yóò sì rí gbogbo wọn. Kí o sì bá mi fi wọ́n bú láti ibẹ̀.”+
14 Nítorí náà, ó mú un lọ sí pápá Sófímù, sí orí Písígà,+ ó sì tẹ̀ síwájú láti mọ pẹpẹ méje, ó sì fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.+
15 Lẹ́yìn ìyẹn, ó wí fún Bálákì pé: “Dúró níhìn-ín lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, ní ti èmi, sì jẹ́ kí n kàn sí i níbẹ̀ yẹn.”
16 Lẹ́yìn náà, Jèhófà kàn sí Báláámù, ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ẹnu rẹ̀, ó sì wí pé:+ “Padà tọ Bálákì+ lọ, èyí sì ni ohun tí ìwọ yóò sọ.”
17 Nítorí náà, ó tọ̀ ọ́ lọ, sì wò ó! ó dúró lẹ́bàá ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀, àti àwọn ọmọ aládé Móábù pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà náà ni Bálákì sọ fún un pé: “Kí ni ohun tí Jèhófà sọ?”
18 Látàrí èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ gbólóhùn òwe rẹ̀, ó sì wí pé:+
“Dìde, Bálákì, sì fetí sílẹ̀.
Fi etí sí mi, ìwọ ọmọkùnrin Sípórì.+
19 Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn tí yóò fi purọ́,+
Tàbí ọmọ aráyé tí yóò fi kábàámọ̀.+
Òun fúnra rẹ̀ ha ti sọ ọ́ tí kì yóò sì ṣe é,
Ó ha sì ti sọ̀rọ̀ tí kì yóò sì mú un ṣẹ?+
20 Wò ó! A ti mú mi láti súre,
Ó sì ti súre,+ èmi kì yóò sì yí i padà.+
21 Òun kò rí agbára abàmì+ èyíkéyìí lòdì sí Jékọ́bù,
Òun kò sì rí ìdààmú kankan kí ó dé bá Ísírẹ́lì.
Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀,+
Ìhó ìyìn ọba sì wà ní àárín rẹ̀.
22 Ọlọ́run ń mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì.+
Ipa ọ̀nà yíyára bí ti akọ màlúù ìgbẹ́ ni tirẹ̀.+
23 Nítorí kò sí ìsàsí kankan sí Jékọ́bù,+
Tàbí ìwoṣẹ́ èyíkéyìí sí Ísírẹ́lì.+
Ní àkókò yìí, a lè sọ ní ti Jékọ́bù àti Ísírẹ́lì pé,
‘Ẹ wo ohun tí Ọlọ́run ṣe!’+
24 Kíyè sí i, àwọn ènìyàn kan yóò dìde bí kìnnìún,
Bí kìnnìún ni yóò sì gbé ara rẹ̀ sókè.+
Kì yóò dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ẹran ọdẹ,
Ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa ni yóò sì mu.”+
25 Látàrí èyí, Bálákì wí fún Báláámù pé: “Bí ó bá jẹ́ pé, ní ọwọ́ kan, ìwọ kò lè fi í bú rárá, nígbà náà, ní ọwọ́ kejì , kí ìwọ má ṣe súre fún un rárá.”
26 Ẹ̀wẹ̀, Báláámù dáhùn, ó sì sọ fún Bálákì pé: “Èmi kò ha sọ fún ọ, pé, ‘Gbogbo ohun tí Jèhófà yóò sọ ni ohun tí èmi yóò ṣe’?”+
27 Nígbà náà ni Bálákì wí fún Báláámù pé: “Wá, jọ̀wọ́. Jẹ́ kí n ṣì tún mú ọ lọ sí ibòmíràn. Bóyá yóò tọ̀nà ní ojú Ọlọ́run tòótọ́ kí o lè bá mi fi í bú dájúdájú láti ibẹ̀.”+
28 Pẹ̀lú ìyẹn, Bálákì mú Báláámù lọ sí orí Péórù, tí ó dojú kọ ìhà Jéṣímónì.+
29 Nígbà náà ni Báláámù+ wí fún Bálákì pé: “Mọ pẹpẹ méje fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí, kí o sì pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje sílẹ̀ fún mi ní ọ̀gangan ibí yìí.”+
30 Nítorí náà, Bálákì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Báláámù ti wí, ó sì tẹ̀ síwájú láti fi akọ màlúù kan àti àgbò kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.+

