Númérì 2:1-34
2 Wàyí o, Jèhófà bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé:
2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dó, olúkúlùkù ọkùnrin sẹ́gbẹ̀ẹ́ ìpín+ rẹ̀ tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta, sẹ́gbẹ̀ẹ́ àmì ilé baba wọn. Kí wọ́n dó yí ká sí iwájú àgọ́ ìpàdé.
3 “Àwọn tí yóò sì dó sí ìlà-oòrùn síhà yíyọ oòrùn yóò jẹ́ ìpín tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìjòyè àwọn ọmọ Júdà sì ni Náṣónì+ ọmọkùnrin Ámínádábù.
4 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọ́n jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta.+
5 Ẹ̀yà Ísákárì+ ni yóò sì dó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Ísákárì sì ni Nétánélì+ ọmọkùnrin Súárì.
6 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó.+
7 Àti ẹ̀yà Sébúlúnì; ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì sì ni Élíábù+ ọmọkùnrin Hélónì.
8 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ẹgbàá méjì dínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+
9 “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Júdà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé egbèjì lélọ́gbọ̀n nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣí.+
10 “Ìpín ẹ̀yà mẹ́ta ibùdó Rúbẹ́nì+ yóò jẹ́ síhà gúúsù nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì sì ni Élísúrì+ ọmọkùnrin Ṣédéúrì.
11 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tirẹ̀ tí a forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàlélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+
12 Ẹ̀yà Síméónì ni yóò sì dó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì sì ni Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọkùnrin Súríṣádáì.
13 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọ́n sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó dín ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin.+
14 Àti ẹ̀yà Gádì; ìjòyè àwọn ọmọ Gádì sì ni Élíásáfù+ ọmọkùnrin Rúẹ́lì.
15 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjì lélógún ó lé àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ.+
16 “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rin ó lé àádọ́ta-lé-légbèje nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, àwọn sì ni yóò ṣí ṣìkejì .+
17 “Nígbà tí àgọ́ ìpàdé+ bá ní láti ṣí, ibùdó àwọn ọmọ Léfì+ yóò wà ní àárín àwọn ibùdó náà.
“Gẹ́gẹ́ bí wọn yóò ṣe dó gan-an, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n ṣe ṣí,+ olúkúlùkù ní àyè rẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìpín wọn tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta.
18 “Ìpín ẹ̀yà mẹ́ta ibùdó Éfúráímù+ nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn yóò jẹ́ síhà ìwọ̀-oòrùn, ìjòyè àwọn ọmọ Éfúráímù sì ni Élíṣámà+ ọmọkùnrin Ámíhúdù.
19 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta.+
20 Ẹ̀yà Mánásè+ yóò sì wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè sì ni Gàmálíẹ́lì+ ọmọkùnrin Pédásúrì.
21 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé igba.+
22 Àti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì;+ ìjòyè àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì sì ni Ábídánì+ ọmọkùnrin Gídíónì.
23 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínlógún ó lé egbèje.+
24 “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Éfúráímù jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, àwọn sì ni yóò ṣí ṣẹ̀kẹta.+
25 “Ìpín ẹ̀yà mẹ́ta ibùdó Dánì yóò jẹ́ síhà àríwá nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, ìjòyè àwọn ọmọ Dánì sì ni Áhíésérì+ ọmọkùnrin Ámíṣádáì.
26 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin.+
27 Ẹ̀yà Áṣérì ni yóò sì dó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì sì ni Págíẹ́lì+ ọmọkùnrin Ókíránì.
28 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ.+
29 Àti ẹ̀yà Náfútálì; ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì+ sì ni Áhírà+ ọmọkùnrin Énánì.
30 Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ àti àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje.+
31 “Gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Dánì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjì lá. Àwọn ni yóò ṣí kẹ́yìn+—ní ìbámú pẹ̀lú ìpín wọn tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta.”
32 Ìwọ̀nyí ni àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìbámu pẹ̀lú ilé baba wọn; gbogbo àwọn tí a forúkọ wọn sílẹ̀ ní ibùdó nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé egbèjì dínlógún dín àádọ́ta.+
33 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì kò forúkọ sílẹ̀+ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.
34 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tẹ̀ síwájú láti ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.+ Ọ̀nà tí wọ́n gbà dó nìyẹn ní ìpín+ wọn tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta-mẹ́ta, ọ̀nà tí wọ́n sì gbà ṣí nìyẹn,+ olúkúlùkù nínú àwọn ìdílé rẹ̀ nípa ilé àwọn baba rẹ̀.

