Númérì 17:1-13

17  Wàyí o, Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:  “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, kí o sì gba ọ̀pá+ kan lọ́wọ́ wọn fún ìdí ilé baba kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ gbogbo ìjòyè+ wọn, nípa ilé àwọn baba wọn, ọ̀pá méjì lá. Kí o kọ orúkọ olúkúlùkù sára ọ̀pá rẹ̀.  Kí o sì kọ orúkọ Áárónì sára ọ̀pá Léfì, nítorí pé ọ̀pá kan ni ó wà fún olórí ilé àwọn baba wọn.  Kí o sì kó wọn lélẹ̀ nínú àgọ́ ìpàdé níwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí,+ níbi tí èmi yóò ti máa pàdé yín déédéé.+  Ohun tí yóò sì ṣẹlẹ̀ ni pé, ọkùnrin náà tí èmi yóò yàn,+ ọ̀pá rẹ̀ yóò rudi, dájúdájú, èmi yóò sì mú kí ìkùnsínú+ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣíwọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi, èyí tí wọ́n ń kùn sí yín.”+  Nítorí náà, Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, gbogbo ìjòyè wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fún un ní ọ̀pá fún ìjòyè kọ̀ọ̀kan, ọ̀pá kan fún ìjòyè kọ̀ọ̀kan, nípa ilé àwọn baba wọn, ọ̀pá+ méjì lá; ọ̀pá Áárónì sì wà lára àwọn ọ̀pá+ wọn.  Nígbà náà ni Mósè kó àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀ níwájú Jèhófà nínú àgọ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí.+  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì pé, nígbà tí Mósè wọnú àgọ́ Gbólóhùn Ẹ̀rí, wò ó! ọ̀pá Áárónì fún ilé Léfì ti rudi, ó sì mú ìrudi jáde, ó sì yọ ìtànná òdòdó, ó sì so àwọn èso álímọ́ńdì pípọ́n.  Nígbà náà ni Mósè kó gbogbo ọ̀pá náà jáde kúrò níwájú Jèhófà tọ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wò ó, olúkúlùkù ọkùnrin sì ń mú ọ̀pá tirẹ̀. 10  Lẹ́yìn náà, Jèhófà wí fún Mósè pé: “Dá ọ̀pá+ Áárónì padà síwájú Gbólóhùn Ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí ohun tí a ó pa mọ́ fún àmì+ fún àwọn ọmọ ìṣọ̀tẹ̀,+ kí ìkùnsínú wọn sí mi lè kásẹ̀ nílẹ̀, kí wọ́n má bàa kú.” 11  Ní kíá, Mósè ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. 12  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ èyí fún Mósè pé: “Wàyí o, ó dájú pé àwa yóò gbẹ́mìí mì, ó dájú pé àwa yóò ṣègbé, ó dájú pé gbogbo wa yóò ṣègbé.+ 13  Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá,+ tí ó bá sún mọ́ àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, yóò kú!+ Ó ha yẹ kí a wá sópin ní gbígbẹ́mìí mì lọ́nà yìí bí?”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé