Númérì 10:1-36

10  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé: 2  “Ṣe kàkàkí+ fàdákà méjì fún ara rẹ. Kí o ṣe wọ́n ní iṣẹ́ òòlù, kí wọ́n sì wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ fún pípe+ àpéjọ àti fún ṣíṣí ibùdó kúrò. 3  Kí wọ́n sì fun méjèèjì , kí gbogbo àpéjọ náà sì pa àdéhùn wọn mọ́ pẹ̀lú rẹ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.+ 4  Bí wọ́n bá sì fun ọ̀kan ṣoṣo, kí àwọn ìjòyè gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì sì pa àdéhùn wọn mọ́ pẹ̀lú rẹ.+ 5  “Kí ẹ sì fun ìró aròkèrodò, kí ibùdó àwọn tí wọ́n dó sí ìlà-oòrùn+ sì ṣí. 6  Kí ẹ sì fun ìró aròkèrodò ní ìgbà kejì , kí ibùdó àwọn tí wọ́n dó sí gúúsù+ sì ṣí. Kí wọ́n fun ìró aròkèrodò fún ìgbà kọ̀ọ̀kan tí ọ̀kan nínú wọ́n bá ṣí. 7  “Wàyí o, nígbà tí ẹ bá ń pe ìjọ pọ̀, kí ẹ fun ún,+ ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe mú kí ìró ìpè aròkèrodò dún. 8  Kí àwọn ọmọkùnrin Áárónì, àwọn àlùfáà, sì fun àwọn kàkàkí+ náà, kí ìlò wọn sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìlànà àgbékalẹ̀ fún yín fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìran-ìran yín. 9  “Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ẹ wọnú ogun nínú ilẹ̀ yín lòdì sí aninilára tí ń fòòró yín,+ kí ẹ mú kí ìpè ogun dún nínú àwọn kàkàkí+ pẹ̀lú, dájúdájú, a óò rántí yín níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín, a ó sì gbà yín là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.+ 10  “Ní ọjọ́ ayọ̀ yíyọ̀+ yín àti ní àwọn àkókò àjọyọ̀+ yín àti ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn oṣù yín,+ kí ẹ sì fun kàkàkí lórí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun+ yín àti ẹbọ+ ìdàpọ̀ yín; kí ìlò wọ́n sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run yín. Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.”+ 11  Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kejì , ní oṣù kejì , ní ọjọ́ ogún oṣù+ náà, àwọsánmà gbé ara rẹ̀ sókè kúrò lórí àgọ́ ìjọsìn+ ti Gbólóhùn Ẹ̀rí. 12  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí ní irú ọ̀nà ìjádelọ+ wọn kúrò ní aginjù Sínáì, àwọsánmà náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní aginjù Páránì.+ 13  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣí fún ìgbà àkọ́kọ́, ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ìtọ́ni Jèhófà nípasẹ̀ Mósè.+ 14  Nítorí náà, ìpín tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Júdà ni ó kọ́kọ́ ṣí ní àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun+ wọn, Náṣónì+ ọmọkùnrin Ámínádábù sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. 15  Nétánélì+ ọmọkùnrin Súárì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì. 16  Élíábù ọmọkùnrin Hélónì+ sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Sébúlúnì. 17  A sì tú àgọ́ ìjọsìn palẹ̀,+ àwọn ọmọ Gẹ́ṣónì+ àti àwọn ọmọ Mérárì+ gẹ́gẹ́ bí àwọn olùru àgọ́ ìjọsìn sì ṣí. 18  Ìpín tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì+ sì ṣí ní àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, Élísúrì+ ọmọkùnrin Ṣédéúrì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. 19  Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọkùnrin Súríṣádáì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Síméónì.+ 20  Élíásáfù+ ọmọkùnrin Déúélì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Gádì. 21  Àwọn ọmọ Kóhátì gẹ́gẹ́ bí àwọn olùru ibùjọsìn+ sì ṣí, níwọ̀n bí wọn yóò ti gbé àgọ́ ìjọsìn nà ró kí wọ́n tó dé. 22  Ìpín tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Éfúráímù+ sì ṣí ní àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, Élíṣámà+ ọmọkùnrin Ámíhúdù sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. 23  Gàmálíẹ́lì+ ọmọkùnrin Pédásúrì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè.+ 24  Ábídánì+ ọmọkùnrin Gídíónì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì.+ 25  Ìpín tí ó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó àwọn ọmọ Dánì+ sì ṣí ní dídi ẹ̀ṣọ́ ìhà ẹ̀yìn+ fún gbogbo ibùdó náà ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn, Áhíésérì+ ọmọkùnrin Ámíṣádáì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀. 26  Págíẹ́lì+ ọmọkùnrin Ókíránì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì.+ 27  Áhírà+ ọmọkùnrin Énánì sì wà lórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfútálì.+ 28  Irú ọ̀nà yìí ni jíjáde lọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn nígbà tí wọ́n bá ṣí.+ 29  Nígbà náà ni Mósè sọ fún Hóbábù ọmọkùnrin Réúẹ́lì+ ọmọ Mídíánì, baba ìyàwó Mósè pé: “Àwa ń ṣí lọ sí ibi tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Èmi yóò fi í fún yín.’+ Wá bá wa lọ, dájúdájú, àwa yóò sì ṣe rere fún ọ,+ nítorí tí Jèhófà ti sọ ohun rere nípa Ísírẹ́lì.”+ 30  Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé: “Èmi kì yóò bá yín lọ, ṣùgbọ́n èmi yóò lọ sí ilẹ̀ mi+ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan mi.” 31  Látàrí èyí, ó wí pé: “Jọ̀wọ́, má fi wá sílẹ̀, nítorí, fún ìdí náà pé o mọ ibi tí a lè dó sí nínú aginjù dunjú, kí o ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ojú fún wa. 32  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé bí o bá bá wa lọ,+ bẹ́ẹ̀ ni, yóò ṣẹlẹ̀ pé ohun rere tí Jèhófà bá fi ṣe wá lóore, ni àwa, ẹ̀wẹ̀, yóò fi ṣe rere fún ọ dájúdájú.” 33  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ kúrò ní òkè ńlá Jèhófà+ ní ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta, àpótí májẹ̀mú Jèhófà+ sì ń lọ níwájú wọn ní ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta láti wá ibi ìsinmi fún wọn.+ 34  Àwọsánmà+ Jèhófà sì wà lórí wọn ní ọ̀sán bí wọ́n ti ń jáde kúrò ní ibi ìdósí. 35  A sì ṣẹlẹ̀ pé nígbà tí Àpótí náà bá ṣí, Mósè a wí pé: “Dìde, Jèhófà, sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá rẹ tú ká;+ sì jẹ́ kí àwọn tí ó kórìíra rẹ lọ́nà gbígbóná janjan sá lọ kúrò níwájú rẹ.”+ 36  Nígbà tí ó bá sì sinmi, a wí pé: “Jèhófà, padà sọ́dọ̀ ẹgbẹẹgbàárùn-ún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ísírẹ́lì.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé