Míkà 7:1-20

7  Ó mà ṣe fún mi+ o, nítorí mo ti dà bí ìkójọ+ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, bí èéṣẹ́ àkójọ èso àjàrà! Kò sí òṣùṣù èso àjàrà láti jẹ, kò sí ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́kọ́, èyí tí ọkàn mi máa ń ṣe àfẹ́rí!+  Ẹni ìdúróṣinṣin ti ṣègbé kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kò sì sí ẹni adúróṣánṣán+ nínú aráyé. Gbogbo wọn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni wọ́n ń lúgọ+ dèni fún. Olúkúlùkù wọn ń fi àwọ̀n ńlá+ ṣọdẹ arákùnrin tirẹ̀.  Ọwọ́ wọn wà lára ohun tí ó burú, láti ṣe é dáadáa;+ ọmọ aládé ń béèrè fún nǹkan, ẹni tí ń ṣèdájọ́ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún èrè,+ ẹni ńlá sì ń sọ ìfàsí ọkàn tirẹ̀ jáde, àní tirẹ̀;+ wọ́n sì hun ún pọ̀ mọ́ra.  Ẹni tí ó dára jù lọ nínú wọn dà bí ẹ̀gún ọ̀gàn,+ ẹni tí ó dúró ṣánṣán jù lọ nínú wọn burú ju ọgbà ẹ̀gún. Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ, tí a óò fún ọ ní àfiyèsí, yóò dé.+ Ìsinsìnyí ni mímú ẹnu wọn wọhò yóò ṣẹlẹ̀.+  Ẹ má ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú alábàákẹ́gbẹ́. Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ àfinúhàn.+ Ṣọ́ líla ẹnu rẹ lọ́dọ̀ obìnrin tí ń dùbúlẹ̀ ní oókan àyà rẹ.+  Nítorí ọmọkùnrin ń tẹ́ńbẹ́lú baba; ọmọbìnrin ń dìde sí ìyá rẹ̀;+ aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀;+ àwọn ọ̀tá ènìyàn ni àwọn ènìyàn agbo ilé rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n ní tèmi, Jèhófà ni èmi yóò máa wá.+ Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà+ mi. Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.+  Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi+ obìnrin. Bí mo tilẹ̀ ṣubú, dájúdájú, èmi yóò dìde;+ bí mo tilẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn,+ Jèhófà yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.+  Èmi yóò mú ìhónú Jèhófà mọ́ra—nítorí mo ti ṣẹ̀ sí i+—títí yóò fi bá mi dá ẹjọ́ mi, tí yóò sì mú ìdájọ́ òdodo ṣẹ ní kíkún fún mi+ ní ti tòótọ́. Òun yóò mú mi wá sí ìmọ́lẹ̀; èmi yóò wo òdodo+ rẹ̀. 10  Ọ̀tá mi yóò sì rí i, ìtìjú yóò sì bò ó,+ ẹni tí ń sọ fún mi pé: “Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, òun dà?” Ojú mi yóò wò ó.+ Nísinsìnyí, yóò di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀, bí ẹrẹ̀ ojú pópó.+ 11  Ọjọ́ mímọ ògiri òkúta rẹ, ọjọ́ yẹn ni àṣẹ àgbékalẹ̀ yóò jìnnà réré.+ 12  Ní ọjọ́ yẹn, àní iyàn-níyàn ọ̀dọ̀ rẹ ni wọn yóò wá láti Ásíríà àti àwọn ìlú ńlá Íjíbítì, àti láti Íjíbítì àní dé iyàn-níyàn Odò;+ àti láti òkun dé òkun, àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.+ 13  Ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro ní tìtorí àwọn olùgbé rẹ̀, nítorí èso ìbánilò+ wọn. 14  Fi ọ̀pá+ rẹ ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ, agbo ẹran tí ó jẹ́ ogún rẹ, ẹni tí ń dá gbé nínú igbó—ní àárín ọgbà igi eléso.+ Jẹ́ kí wọ́n fi Báṣánì àti Gílíádì+ ṣe oúnjẹ bí àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.+ 15  “Bí ó ti rí ní àwọn ọjọ́ tí o jáde wá láti ilẹ̀ Íjíbítì, èmi yóò fi àwọn ohun àgbàyanu+ hàn án. 16  Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí i, gbogbo agbára ńlá+ wọn yóò sì tì wọ́n lójú. Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu;+ àní etí wọn yóò di. 17  Wọn yóò lá ekuru bí ejò;+ bí ti àwọn ẹranko afàyàfà ilẹ̀ ayé, wọn yóò fi ṣìbáṣìbo jáde wá láti inú àwọn odi ààbò+ wọn. Wọn yóò sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa, wọn yóò sì fòyà rẹ.”+ 18  Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ,+ ẹni tí ń dárí ìrélànàkọjá+ jì, tí ó sì ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún+ rẹ̀ kọjá? Dájúdájú, òun kì yóò máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé, nítorí ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.+ 19  Òun yóò tún fi àánú+ hàn sí wa; yóò tẹ àwọn ìṣìnà+ wa lórí ba. Ìwọ yóò sì sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀+ wọn sínú ibú òkun. 20  Ìwọ yóò fúnni ní òótọ́ tí a fún Jékọ́bù, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí a fún Ábúráhámù, èyí tí o búra fún àwọn baba ńlá wa láti àwọn ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé