Míkà 5:1-15

5  “Lọ́tẹ̀ yìí, ìwọ kọ ara rẹ ní abẹ,+ ìwọ ọmọbìnrin ìgbóguntì;+ ó ti sàga tì wá. Wọn yóò fi ọ̀pá lu ẹ̀rẹ̀kẹ́ onídàájọ́ Ísírẹ́lì.+ 2  “Àti ìwọ, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù Éfúrátà,+ ẹni tí ó kéré jù láti wà lára àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún Júdà,+ inú rẹ+ ni ẹni tí yóò di olùṣàkóso Ísírẹ́lì+ yóò ti jáde tọ̀ mí wá, ẹni tí orírun rẹ̀ jẹ́ láti àwọn àkókò ìjímìjí, láti àwọn ọjọ́ tí ó jẹ́ àkókò tí ó lọ kánrin.+ 3  “Nítorí náà, òun yóò jọ̀wọ́ wọn lọ́wọ́+ títí di àkókò tí ẹni tí ó fẹ́ bímọ yóò fi bímọ+ ní ti tòótọ́. Ìyókù àwọn arákùnrin rẹ̀ yóò sì padà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 4  “Òun yóò sì dúró dájúdájú, yóò sì ṣe olùṣọ́ àgùntàn nínú okun Jèhófà,+ nínú ìlọ́lájù orúkọ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ̀. Dájúdájú, wọn yóò sì máa gbé,+ nítorí nísinsìnyí òun yóò tóbi títí dé òpin ilẹ̀ ayé.+ 5  Ẹni yìí yóò sì di àlàáfíà.+ Ní ti ará Ásíríà, nígbà tí ó bá wá sí ilẹ̀ wa, nígbà tí ó bá sì tẹ àwọn ilé gogoro+ ibùgbé wa mọ́lẹ̀, àwa pẹ̀lú yóò sì ní láti gbé olùṣọ́ àgùntàn méje dìde sí i, bẹ́ẹ̀ ni, mọ́gàjí mẹ́jọ nínú aráyé. 6  Wọn yóò sì fi idà+ ṣe olùṣọ́ àgùntàn ilẹ̀ Ásíríà ní ti tòótọ́, àti ilẹ̀ Nímírọ́dù+ ní àwọn ẹnu ọ̀nà rẹ̀. Dájúdájú, òun yóò mú ìdáǹdè wá kúrò lọ́wọ́ ará Ásíríà,+ nígbà tí ó bá wá sí ilẹ̀ wa àti nígbà tí ó bá tẹ ìpínlẹ̀ wa mọ́lẹ̀. 7  “Àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù+ yóò sì dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà+ ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò lórí ewéko,+ tí kì í retí ènìyàn tàbí kí ó dúró de àwọn ọmọ ará ayé.+ 8  Nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù yóò sì dà bí kìnnìún láàárín àwọn ẹranko igbó, bí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ láàárín agbo àgùntàn, èyí tí, nígbà tí ó bá kọjá lọ ní ti tòótọ́, yóò tẹ̀ mọ́lẹ̀, yóò sì fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ dájúdájú;+ kò sì sí olùdáǹdè. 9  Ọwọ́ rẹ yóò wà lókè àwọn elénìní+ rẹ, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì ké kúrò.”+ 10  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “pé èmi yóò ké àwọn ẹṣin rẹ kúrò ní àárín rẹ dájúdájú, èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin+ rẹ run. 11  Dájúdájú, èmi yóò sì ké àwọn ìlú ńlá ilẹ̀ rẹ kúrò, èmi yóò sì ya gbogbo àwọn ibi olódi+ rẹ lulẹ̀. 12  Dájúdájú, èmi yóò sì ké àwọn iṣẹ́ àjẹ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ, ìwọ kì yóò sì tún ní àwọn pidánpidán mọ́.+ 13  Dájúdájú, èmi yóò sì ké àwọn ère fífín rẹ kúrò, àti àwọn ọwọ̀n rẹ kúrò ní àárín rẹ, ìwọ kì yóò sì tún tẹrí ba fún àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ mọ́.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò sì fa àwọn òpó ọlọ́wọ̀+ rẹ tu kúrò ní àárín rẹ, èmi yóò sì pa àwọn ìlú ńlá rẹ rẹ́ ráúráú. 15  Ìbínú àti ìhónú sì ni èmi yóò fi mú ẹ̀san ṣẹ ní kíkún lára àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ṣègbọràn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé