Mátíù 27:1-66
27 Nígbà tí ó di òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà ṣe ìfikùnlukùn lòdì sí Jésù láti fi ikú pa á.+
2 Lẹ́yìn tí wọ́n dè é, wọ́n sì mú un lọ, wọ́n sì fi í lé Pílátù gómìnà lọ́wọ́.+
3 Nígbà náà ni Júdásì, ẹni tí ó dà á, ní rírí i pé a ti dá a lẹ́bi, ní ìmọ̀lára ẹ̀dùn ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ọgbọ̀n+ ẹyọ fàdákà náà padà fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin,
4 ó wí pé: “Mo dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí mo fi ẹ̀jẹ̀ olódodo lé yín lọ́wọ́.”+ Wọ́n wí pé: “Èwo ni ó kàn wá nínú ìyẹn? Ìwọ ni kí o lọ bójú tó ìyẹn!”+
5 Nítorí náà, ó da àwọn ẹyọ fàdákà náà sínú tẹ́ńpìlì, ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ pokùnso.+
6 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà kó àwọn ẹyọ fàdákà náà, wọ́n sì wí pé: “Kò bófin mu láti dà wọ́n sínú ibi ìṣúra ọlọ́wọ̀, nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n.”
7 Lẹ́yìn jíjùmọ̀ fikùn lukùn, wọ́n fi ra pápá amọ̀kòkò láti máa fi sìnkú àwọn àjèjì.
8 Nítorí náà, pápá yẹn ni a ń pè ní “Pápá Ẹ̀jẹ̀”+ títí di òní yìí gan-an.
9 Nígbà náà ni ohun tí a sọ nípasẹ̀ Jeremáyà wòlíì ní ìmúṣẹ, pé: “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n ẹyọ fàdákà,+ iye owó lórí ọkùnrin tí a dá iye owó lé, ẹni tí àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá iye owó kan lé,
10 wọ́n sì fi wọ́n ra pápá amọ̀kòkò,+ gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún mi.”
11 Wàyí o, Jésù dúró níwájú gómìnà; gómìnà sì bi í léèrè pé: “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù bí?”+ Jésù fèsì pé: “Ìwọ fúnra rẹ wí i.”+
12 Ṣùgbọ́n, bí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin ti ń fẹ̀sùn kàn án,+ kò dáhùn.+
13 Nígbà náà ni Pílátù wí fún un pé: “Ṣé ìwọ kò gbọ́ bí àwọn ohun tí wọ́n ń jẹ́rìí lòdì sí ọ ti pọ̀ tó ni?”+
14 Síbẹ̀, kò dá a lóhùn rárá, àní kì í tilẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ kan, tó bẹ́ẹ̀ tí gómìnà fi ṣe kàyéfì gidigidi.+
15 Wàyí o, láti àjọyọ̀ dé àjọyọ̀, ó jẹ́ àṣà gómìnà láti tú ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún ogunlọ́gọ̀, ẹni tí wọ́n bá fẹ́.+
16 Ní àkókò yẹn gan-an, wọ́n ní ẹlẹ́wọ̀n olókìkí burúkú kan lọ́wọ́, tí a ń pè ní Bárábà.+
17 Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n kóra jọpọ̀, Pílátù wí fún wọn pé: “Ta ni ẹ fẹ́ kí n tú sílẹ̀ fún yín, Bárábà ni tàbí Jésù tí àwọn ènìyàn ń pè ní Kristi?”+
18 Nítorí ó mọ̀ pé nítorí ìlara+ ni wọ́n ṣe fi í lé òun lọ́wọ́.+
19 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó ti jókòó lórí ìjókòó ìdájọ́, aya rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, pé: “Má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọkùnrin olódodo+ yẹn, nítorí mo jìyà gidigidi lónìí nínú àlá+ nítorí rẹ̀.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin yí àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lérò padà láti béèrè fún Bárábà,+ ṣùgbọ́n kí wọ́n pa Jésù run.
21 Wàyí o, ní dídáhùnpadà, gómìnà wí fún wọn pé: “Èwo nínú àwọn méjèèjì ni ẹ fẹ́ kí èmi tú sílẹ̀ fún yín?” Wọ́n wí pé: “Bárábà.”+
22 Pílátù wí fún wọn pé: “Kí wá ni kí èmi ti ṣe Jésù tí àwọn ènìyàn ń pè ní Kristi?” Gbogbo wọ́n wí pé: “Kí a kàn án mọ́gi!”+
23 Ó wí pé: “Họ́wù, ohun búburú wo ni ó ṣe?” Síbẹ̀, wọ́n túbọ̀ ń ké jáde ṣáá pé: “Kí a kàn án mọ́gi!”+
24 Ní rírí i pé kò gbéṣẹ́ rárá, kàkà bẹ́ẹ̀, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, Pílátù bu omi,+ ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ogunlọ́gọ̀ náà, ó wí pé: “Ọwọ́ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ lọ bójú tó ìyẹn.”
25 Látàrí ìyẹn, gbogbo àwọn ènìyàn náà sọ ní ìdáhùn pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí wa àti sórí àwọn ọmọ wa.”+
26 Nígbà náà ni ó tú Bárábà sílẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ó mú kí a na Jésù ní pàṣán,+ ó sì fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn án mọ́gi.+
27 Nígbà náà ni àwọn ọmọ ogun gómìnà mú Jésù wọnú ààfin gómìnà, wọ́n sì kó gbogbo ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun jọpọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.+
28 Àti ní bíbọ́ ẹ̀wù rẹ̀, wọ́n fi aṣọ ìlékè rírẹ̀dòdò kan wọ̀ ọ́,+
29 wọ́n sì fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n sì fi dé orí rẹ̀, wọ́n sì fi ọ̀pá esùsú sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Àti pé, ní kíkúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n wí pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ìwọ Ọba àwọn Júù!”+
30 Wọ́n sì tutọ́+ sí i lára, wọ́n sì gba ọ̀pá esùsú náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbá a ní orí.
31 Níkẹyìn, nígbà tí wọ́n ti fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n bọ́ aṣọ ìlékè náà, wọ́n sì fi ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n sì mú un lọ fún kíkànmọ́gi.+
32 Bí wọ́n ti ń jáde lọ, wọ́n rí ọmọ ìbílẹ̀ Kírénè kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Símónì.+ Wọ́n fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọkùnrin yìí láti gbé òpó igi oró rẹ̀ nílẹ̀.
33 Nígbà tí wọ́n sì dé ibì kan tí a ń pè ní Gọ́gọ́tà,+ èyíinì ni, Ibi Agbárí,
34 wọ́n fi wáìnì tí a pò pọ̀ mọ́ òróòró+ fún un láti mu; ṣùgbọ́n, lẹ́yìn títọ́ ọ wò, ó kọ̀ láti mu ún.+
35 Nígbà tí wọ́n ti kàn án mọ́gi,+ wọ́n pín ẹ̀wù àwọ̀lékè+ rẹ̀ nípa ṣíṣẹ́ kèké,+
36 bí wọ́n sì ti jókòó, wọ́n ń ṣọ́ ọ níbẹ̀.
37 Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n gbé àkọlé ẹ̀sùn lòdì sí i sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ọ́ pé: “Èyí ni Jésù Ọba Àwọn Júù.”+
38 Nígbà náà, àwọn ọlọ́ṣà méjì ni a kàn mọ́gi pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan ní ọ̀tún rẹ̀ àti ọ̀kan ní òsì rẹ̀.+
39 Nítorí náà, àwọn tí ń kọjá lọ bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú,+ wọ́n ń mi orí wọn síwá sẹ́yìn+
40 wọ́n sì ń wí pé: “Ìwọ tí o máa wó tẹ́ńpìlì+ palẹ̀, tí o sì máa fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ, gba ara rẹ là! Bí ìwọ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, sọ̀ kalẹ̀ kúrò lórí òpó igi oró!”+
41 Lọ́nà kan náà pẹ̀lú ni àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbà ọkùnrin bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń wí pé:+
42 “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kò lè gba ara rẹ̀ là! Òun ni Ọba+ Ísírẹ́lì; kí ó sọ̀ kalẹ̀ nísinsìnyí kúrò lórí òpó igi oró, dájúdájú, àwa yóò sì gbà á gbọ́.+
43 Ó ti fi ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ sínú Ọlọ́run; kí Ó gbà á sílẹ̀+ nísinsìnyí bí ó bá jẹ́ pé Ó fẹ́ ẹ, nítorí ó wí pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni èmi.’”+
44 Ní ọ̀nà kan náà, àní àwọn ọlọ́ṣà tí a kàn mọ́gi pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gàn án.+
45 Láti wákàtí kẹfà lọ, òkùnkùn kan ṣú bo+ gbogbo ilẹ̀ náà, títí di wákàtí kẹsàn-án.+
46 Ní nǹkan bí wákàtí kẹsàn-án, Jésù ké ní ohùn rara, pé: “Élì, Élì, lama sabakitani?” èyíinì ni, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?”+
47 Ní gbígbọ́ èyí, àwọn kan lára àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “[Ọkùnrin] yìí ń pe Èlíjà.”+
48 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọ̀kan lára wọ́n sáré, ó sì mú kànrìnkàn, ó sì rẹ ẹ́ sínú wáìnì kíkan,+ ó sì fi í sórí ọ̀pá esùsú, ó sì lọ ń fún un mu.+
49 Ṣùgbọ́n àwọn yòókù lára wọ́n wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́ [rẹ̀]! Ẹ jẹ́ kí a wò ó bóyá Èlíjà yóò wá láti gbà á là.”+ [[Ọkùnrin mìíràn mú ọ̀kọ̀, ó sì fi gún ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde.]]+
50 Jésù tún fi ohùn rara ké jáde, ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.+
51 Sì wò ó! aṣọ ìkélé+ ibùjọsìn ya sí méjì, láti òkè dé ìsàlẹ̀,+ ilẹ̀ ayé sì mì tìtì, àwọn àpáta ràbàtà sì là sí wẹ́wẹ́.+
52 Àwọn ibojì ìrántí sì ṣí sílẹ̀, ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí wọ́n ti sùn ni a gbé dìde,
53 (ati pé àwọn ènìyàn, tí ń jáde bọ̀ láti àárín àwọn ibojì ìrántí lẹ́yìn tí a ti gbé e dìde, wọ ìlú ńlá mímọ́ náà,)+ wọ́n sì di rírí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
54 Ṣùgbọ́n ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ́ Jésù fòyà gidigidi, nígbà tí wọ́n rí ìsẹ̀lẹ̀ náà àti àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé: “Dájúdájú, Ọmọ Ọlọ́run ni èyí.”+
55 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wòran láti òkèèrè,+ àwọn tí wọ́n ti bá Jésù wá láti Gálílì láti ṣe ìránṣẹ́ fún un;+
56 lára àwọn tí Màríà Magidalénì wà, pẹ̀lú Màríà ìyá Jákọ́bù àti Jósè, àti ìyá àwọn ọmọkùnrin Sébédè.+
57 Wàyí o, bí ó tí di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan ará Arimatíà dé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jósẹ́fù, ẹni tí òun fúnra rẹ̀ ti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.+
58 Ọkùnrin yìí lọ sọ́dọ̀ Pílátù, ó sì béèrè fún òkú Jésù.+ Pílátù wá pàṣẹ pé kí a gbé e fún un.+
59 Jósẹ́fù sì gbé òkú náà, ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà tí ó mọ́ dì í,+
60 ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì ìrántí rẹ̀ tuntun,+ èyí tí ó ti gbẹ́ sínú àpáta ràbàtà. Àti pé, lẹ́yìn yíyí òkúta ńlá sí ẹnu ọ̀nà ibojì ìrántí náà, ó lọ.+
61 Ṣùgbọ́n Màríà Magidalénì àti Màríà kejì ń bá a lọ ní wíwà níbẹ̀, wọ́n jókòó níwájú sàréè náà.+
62 Ní ọjọ́ kejì, tí ó jẹ́ lẹ́yìn Ìpalẹ̀mọ́,+ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí kóra jọpọ̀ síwájú Pílátù,
63 wọ́n wí pé: “Ọ̀gá, àwa ti rántí pé afàwọ̀rajà yẹn sọ nígbà tí ó ṣì wà láàyè pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta,+ a óò gbé mi dìde.’
64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a sé sàréè náà mọ́ títí di ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ má bàa wá, kí wọ́n sì jí i gbé,+ kí wọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn pé, ‘A ti gbé e dìde kúrò nínú òkú!’ ìfàwọ̀rajà ìkẹyìn yìí yóò sì burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65 Pílátù wí fún wọn pé: “Ẹ ní ẹ̀ṣọ́.+ Ẹ lọ sé e mọ́ dé àyè ibi tí ẹ bá lè ṣe é dé.”
66 Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n sì sé sàréè náà mọ́ nípa fífi èdìdì sí òkúta+ náà àti nípa fífi ẹ̀ṣọ́ ṣọ́ ọ.

