Mátíù 21:1-46
21 Tóò, nígbà tí wọ́n sún mọ́ Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì dé Bẹtifágè lórí Òkè Ńlá Ólífì, nígbà náà ni Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn méjì jáde,+
2 ó wí fún wọn pé: “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n lọ sínú abúlé tí ẹ ń wò yìí, lójú-ẹsẹ̀ ni ẹ ó sì rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, àti agódóńgbó kan pẹ̀lú rẹ̀; ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi.+
3 Bí ẹnì kan bá sì sọ ohunkóhun fún yín, kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa nílò wọn.’ Látàrí ìyẹn, yóò fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.”
4 Èyí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi kí ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì náà lè ṣẹ, pé:
5 “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé, ‘Wò ó! Ọba rẹ ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ,+ onínú tútù,+ ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, bẹ́ẹ̀ ni, lórí agódóńgbó, ọmọ ẹranko arẹrù.’”+
6 Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn.
7 Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà àti agódóńgbó rẹ̀ wá, wọ́n sì tẹ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn sórí ìwọ̀nyí, òun fúnra rẹ̀ sì jókòó lórí wọn.+
8 Ọ̀pọ̀ jù lọ lára ogunlọ́gọ̀ náà tẹ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè+ wọn sí ojú ọ̀nà, nígbà tí àwọn mìíràn bẹ̀rẹ̀ sí gé àwọn ẹ̀ka lulẹ̀ láti ara àwọn igi, tí wọ́n sì ń tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.+
9 Ní ti àwọn ogunlọ́gọ̀ náà, àwọn tí ń lọ níwájú rẹ̀ àti àwọn tí ń tẹ̀ lé e ń ké jáde ṣáá pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì+ là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!+ Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà!+ Gbà á là, ni àwa bẹ̀bẹ̀, ní ibi gíga lókè!”+
10 Wàyí o, nígbà tí ó wọ Jerúsálẹ́mù,+ arukutu sọ ní gbogbo ìlú ńlá náà, wọ́n ń sọ pé: “Ta ni èyí?”
11 Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà ń sọ ṣáá pé: “Èyí ni wòlíì+ náà Jésù, láti Násárétì ti Gálílì!”
12 Jésù sì wọ inú tẹ́ńpìlì, ó sì lé gbogbo àwọn tí ń tà, tí wọ́n sì ń rà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì sojú tábìlì àwọn olùpààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tí ń ta àdàbà.+
13 Ó sì wí fún wọn pé: “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi ni a óò máa pè ní ilé àdúrà,’+ ṣùgbọ́n ẹ ń sọ ọ́ di hòrò àwọn ọlọ́ṣà.”+
14 Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, ó sì wò wọ́n sàn.
15 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin rí àwọn ohun ìyanu tí ó ṣe+ àti àwọn ọmọdékùnrin tí ń ké jáde ní tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì ń sọ pé: “Gba Ọmọkùnrin Dáfídì+ là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!”+ ìkannú wọ́n ru
16 wọ́n sì sọ fún un pé: “Ìwọ ha gbọ́ ohun tí àwọn wọ̀nyí ń sọ?” Jésù sọ fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ kò tíì ka+ èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?”+
17 Àti ní fífi wọ́n sílẹ̀ sẹ́yìn, ó jáde kúrò ní ìlú ńlá náà lọ sí Bẹ́tánì, ó sì sùn mọ́jú níbẹ̀.+
18 Nígbà tí ó ń padà sí ìlú ńlá náà ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ebi ń pa á.+
19 Ó sì tajú kán rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan ní ojú ọ̀nà, ó sì lọ sí ìdí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò rí nǹkan kan+ lórí rẹ̀ àyàfi ewé nìkan, ó sì wí fún un pé: “Kí èso kankan má ṣe so lórí rẹ mọ́ títí láé.”+ Igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì rọ ní ìṣẹ́jú akàn.
20 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, wọ́n ṣe kàyéfì, wí pé: “Èé ti rí tí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà fi rọ ní ìṣẹ́jú akàn?”+
21 Ní ìdáhùn, Jésù wí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹ bá sáà ti ní ìgbàgbọ́, tí ẹ kò sì ṣiyèméjì,+ kì í ṣe pé ẹ ó ṣe ohun ti mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan ni, ṣùgbọ́n bí ẹ bá sọ fún òkè ńlá yìí pẹ̀lú pé, ‘Gbéra sọ sínú òkun,’ yóò ṣẹlẹ̀.+
22 Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ni ẹ óò rí gbà.”+
23 Wàyí o, lẹ́yìn tí ó lọ sínú tẹ́ńpìlì, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń kọ́ni, wọ́n sì wí pé:+ “Ọlá àṣẹ wo ni ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ta ní sì fún ọ ní ọlá àṣẹ yìí?”+
24 Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Dájúdájú, èmi, pẹ̀lú, yóò béèrè ohun kan lọ́wọ́ yín. Bí ẹ bá sọ ọ́ fún mi, dájúdájú, èmi pẹ̀lú yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín:+
25 Ìbatisí láti ọwọ́ Jòhánù, láti orísun wo ni ó ti wá? Ṣé láti ọ̀run ni tàbí láti ọ̀dọ̀ ènìyàn?”+ Ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fèrò wérò láàárín ara wọn, pé: “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ yóò sọ fún wa pé, ‘Èé ṣe, nígbà náà, tí ẹ kò gbà á gbọ́?’+
26 Ṣùgbọ́n, bí àwa bá sọ pé, ‘Láti ọ̀dọ̀ ènìyàn,’ ẹ̀rù ogunlọ́gọ̀ yìí ń bà wá,+ nítorí gbogbo wọn ka Jòhánù sí wòlíì.”+
27 Nítorí náà, ní dídá Jésù lóhùn, wọ́n sọ pé: “Àwa kò mọ̀.” Òun, ẹ̀wẹ̀, sọ fún wọn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò sọ ọlá àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí fún yín.+
28 “Kí ni ẹ̀yin rò? Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì.+ Ní lílọ sọ́dọ̀ èyí àkọ́kọ́, ó wí pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ lónìí nínú ọgbà àjàrà.’
29 Ní ìdáhùn, ẹni yìí wí pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò lọ, sà,’+ ṣùgbọ́n kò jáde lọ.
30 Ní títọ èkejì lọ, ó sọ ohun kan náà. Ní ìfèsìpadà, ẹni yìí wí pé, ‘Dájúdájú, èmi kì yóò lọ.’ Lẹ́yìn ìgbà náà, ó pèrò dà,+ ó sì jáde lọ.
31 Èwo nínú àwọn méjì náà ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?”+ Wọ́n wí pé: “Èyí èkejì.” Jésù wí fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó ń lọ sínú ìjọba Ọlọ́run ṣáájú yín.
32 Nítorí Jòhánù wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo,+ ṣùgbọ́n ẹ kò gbà á gbọ́.+ Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn agbowó orí àti àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́,+ àti pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ rí èyí, ẹ kò pèrò dà lẹ́yìn ìgbà náà kí ẹ lè gbà á gbọ́.
33 “Ẹ gbọ́ àpèjúwe mìíràn: Ọkùnrin kan wà, baálé ilé kan,+ tí ó gbin ọgbà àjàrà kan, ó ṣe ọgbà yí i ká, ó sì gbẹ́ ibi ìfúntí wáìnì sínú rẹ̀, ó sì gbé ilé gogoro kan nà ró,+ ó sì gbé e fún àwọn aroko, ó sì rin ìrìn àjò lọ sí ìdálẹ̀.+
34 Nígbà tí àsìkò èso dé, ó rán àwọn ẹrú rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn aroko náà láti gba àwọn èso rẹ̀.
35 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn aroko náà mú àwọn ẹrú rẹ̀, wọ́n sì lu ọ̀kan ní ìlùkulù, òmíràn ni wọ́n pa, òmíràn ni wọ́n sọ lókùúta.+
36 Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn lọ, tí iye wọ́n ju ti àkọ́kọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe ohun kan náà sí àwọn wọ̀nyí.+
37 Níkẹyìn, ó rán ọmọ rẹ̀ sí wọn, ó wí pé, ‘Wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ọmọ mi.’
38 Nígbà tí wọ́n rí ọmọ náà, àwọn aroko náà sọ láàárín ara wọn pé, ‘Ajogún nìyí;+ ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì gba ogún rẹ̀!’+
39 Nítorí náà, wọ́n mú un, wọ́n sì sọ ọ́ sóde ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.+
40 Nítorí náà, nígbà tí ẹni tí ó ni ọgbà àjàrà náà bá dé, kí ni yóò ṣe fún àwọn aroko wọnnì?”
41 Wọ́n wí fún un pé: “Nítorí wọ́n jẹ́ ẹni búburú, òun yóò mú ìparun búburú+ wá sórí wọn, yóò sì gbé ọgbà àjàrà náà fún àwọn aroko mìíràn, àwọn tí yóò fún un ní àwọn èso nígbà tí àkókò wọ́n bá tó.”+
42 Jésù wí fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì kà nínú Ìwé Mímọ́ rí pé, ‘Òkúta tí àwọn akọ́lé kọ̀ tì+ ni èyí tí ó ti di olórí òkúta igun ilé.+ Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá, ó sì jẹ́ ohun ìyanu ní ojú wa’?
43 Ìdí nìyí tí mo fi wí fún yín pé, A ó gba ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ jáde.+
44 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí ni a óò fọ́ túútúú. Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá bọ́ lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”+
45 Wàyí o, nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí ti gbọ́ àwọn àpèjúwe rẹ̀, wọ́n ṣàkíyèsí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa wọn.+
46 Ṣùgbọ́n, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbá a mú, wọ́n bẹ̀rù àwọn ogunlọ́gọ̀, nítorí pé àwọn wọ̀nyí kà á sí wòlíì.+