Mátíù 17:1-27

17  Ọjọ́ mẹ́fà lẹ́yìn náà, Jésù mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì mú wọn wá sí orí òkè ńlá kan tí ó ga fíofío ní àwọn nìkan.+  A sì yí i padà di ológo níwájú wọn, ojú rẹ̀ sì tàn bí oòrùn,+ ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀ sì wá tàn yòò bí ìmọ́lẹ̀.+  Sì wò ó! Mósè àti Èlíjà sì fara hàn wọ́n níbẹ̀, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀.+  Ní ìdáhùnpadà, Pétérù wí fún Jésù pé: “Olúwa, ó dára púpọ̀ fún wa láti wà níhìn-ín. Bí ìwọ bá fẹ́, dájúdájú, èmi yóò gbé àgọ́ mẹ́ta nà ró síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ àti ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.”+  Nígbà tí ó ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! àwọsánmà mímọ́lẹ̀ yòò ṣíji bò wọ́n, sì wò ó! ohùn kan láti inú àwọsánmà náà, wí pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà;+ ẹ fetí sí i.”+  Nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dojú bolẹ̀, àyà sì fò wọ́n gidigidi.+  Nígbà náà ni Jésù wá sí tòsí, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó sì wí pé: “Ẹ dìde, ẹ má sì bẹ̀rù.”+  Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnì kankan bí kò ṣe Jésù fúnra rẹ̀ nìkan.+  Bí wọ́n sì ti ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè ńlá náà, Jésù pàṣẹ fún wọn, pé: “Ẹ má ṣe sọ ìran náà fún ẹnì kankan títí a ó fi gbé Ọmọ ènìyàn dìde kúrò nínú òkú.”+ 10  Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi í léèrè pé: “Èé ṣe tí àwọn akọ̀wé òfin fi wá ń sọ pé Èlíjà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá?”+ 11  Ní ìfèsìpadà, ó wí pé: “Èlíjà, ní tòótọ́, ń bọ̀, yóò sì mú ohun gbogbo padà bọ̀ sípò.+ 12  Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé Èlíjà ti wá ná, wọn kò sì dá a mọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ sí i. Ní ọ̀nà yìí pẹ̀lú, a ti yan Ọmọ ènìyàn tẹ́lẹ̀ láti jìyà ní ọwọ́ wọn.”+ 13  Nígbà náà ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn róye pé ó ń bá àwọn sọ̀rọ̀ nípa Jòhánù Oníbatisí.+ 14  Nígbà tí wọ́n sì wá sọ́dọ̀ ogunlọ́gọ̀ náà,+ ọkùnrin kan tọ̀ ọ́ wá, ó kúnlẹ̀ fún un, ó sì wí pé: 15  “Olúwa, ṣàánú fún ọmọkùnrin mi, nítorí pé ó jẹ́ alárùn wárápá, ó sì ń ṣàmódi, nítorí ó máa ń ṣubú sínú iná ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti sínú omi ní ọ̀pọ̀ ìgbà;+ 16  mo sì mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.”+ 17  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti onímàgòmágó,+ báwo ni èmi yóò ti máa bá a lọ pẹ̀lú yín pẹ́ tó? Báwo ni èmi yóò ti máa fara dà fún yín pẹ́ tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín.” 18  Nígbà náà ni Jésù bá a wí lọ́nà mímúná, ẹ̀mí èṣù náà sì jáde kúrò nínú rẹ̀;+ a sì wo ọmọdékùnrin náà sàn láti wákàtí yẹn.+ 19  Látàrí èyí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jésù níkọ̀kọ̀, wọ́n sì wí pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé àwa kò lè lé e jáde?”+ 20  Ó wí fún wọn pé: “Nítorí ìgbàgbọ́ yín tí ó kéré ni. Nítorí lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, ẹ ó sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Ṣípò kúrò ní ìhín lọ sí ọ̀hún,’ yóò sì ṣípò, kò sì sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.”+ 21  —— 22  Nígbà tí wọ́n kóra jọpọ̀ ní Gálílì ni Jésù wí fún wọn pé: “Ọmọ ènìyàn ni a ti yàn tẹ́lẹ̀ pé a ó fi lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́,+ 23  wọn yóò sì pa á, a ó sì gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ Nítorí náà, ẹ̀dùn-ọkàn bá wọn gidigidi.+ 24  Lẹ́yìn tí wọ́n dé sí Kápánáúmù, àwọn ọkùnrin tí ń gba dírákímà méjì [owó orí] tọ Pétérù wá, wọ́n sì sọ pé: “Ṣé olùkọ́ yín kì í san dírákímà méjì [owó orí] ni?”+ 25  Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.” Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó wọnú ilé, Jésù ṣáájú rẹ̀ nípa sísọ pé: “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Lọ́wọ́ ta ni àwọn ọba ilẹ̀ ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn ni tàbí lọ́wọ́ àwọn àjèjì?” 26  Nígbà tí ó sọ pé: “Lọ́wọ́ àwọn àjèjì,” Jésù wí fún un pé: “Ní ti gidi, nígbà náà, àwọn ọmọ bọ́ lọ́wọ́ owó orí. 27  Ṣùgbọ́n kí a má bàa mú wọn kọsẹ̀,+ ìwọ lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, sì mú ẹja tí ó kọ́kọ́ jáde wá, nígbà tí o bá sì la ẹnu rẹ̀, ìwọ yóò rí ẹyọ owó sítátà kan. Mú ìyẹn, kí o sì fi í fún wọn fún èmi àti ìwọ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé