Mátíù 14:1-36

14  Ní àkókò yẹn gan-an ni Hẹ́rọ́dù, olùṣàkóso àgbègbè náà, gbọ́ ìròyìn nípa Jésù,+  ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Èyí ni Jòhánù Oníbatisí. A gbé e dìde kúrò nínú òkú, ìdí sì nìyí tí àwọn iṣẹ́ agbára fi ń ṣe nínú rẹ̀.”+  Nítorí Hẹ́rọ́dù ti fi àṣẹ ọba mú Jòhánù, ó sì dè é, ó sì fi í sínú ẹ̀wọ̀n ní tìtorí Hẹrodíà aya Fílípì arákùnrin rẹ̀.+  Nítorí Jòhánù ti ń sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún ọ láti ní in.”+  Àmọ́ ṣá o, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹ́ pa á, ó bẹ̀rù ogunlọ́gọ̀ náà, nítorí pé wọ́n kà á sí wòlíì.+  Ṣùgbọ́n nígbà tí a ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Hẹ́rọ́dù,+ ọmọbìnrin Hẹrodíà jó níbẹ̀, ó sì mú inú Hẹ́rọ́dù dùn tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́  tí ó fi ṣe ìlérí pẹ̀lú ìbúra láti fún un ní ohun yòówù tí ó bá béèrè.+  Nígbà náà ni òun, lábẹ́ ìtọ́ni ìyá rẹ̀, wí pé: “Fi orí Jòhánù Oníbatisí+ fún mi níhìn-ín nínú àwo pẹrẹsẹ.”  Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dùn-ọkàn bá a, ọba pàṣẹ pé kí a fi í fún un ní tìtorí ìbúra rẹ̀ àti nítorí àwọn tí wọ́n rọ̀gbọ̀kú pẹ̀lú rẹ̀;+ 10  ó sì ránṣẹ́, ó sì mú kí wọ́n bẹ́ Jòhánù lórí nínú ẹ̀wọ̀n. 11  A sì gbé orí rẹ̀ wá nínú àwo pẹrẹsẹ, a sì fi fún omidan náà, ó sì gbé e wá fún ìyá rẹ̀.+ 12  Níkẹyìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n sì gbé òkú rẹ̀ kúrò, wọ́n sì sin ín,+ wọ́n sì wá, wọ́n sì ròyìn fún Jésù. 13  Nígbà tí ó gbọ́ èyí, Jésù bá ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó dá, láti dá nìkan wà;+ ṣùgbọ́n àwọn ogunlọ́gọ̀, ní gbígbọ́ nípa rẹ̀, fi ẹsẹ̀ rìn tẹ̀ lé e láti àwọn ìlú ńlá náà. 14  Wàyí o, nígbà tí ó jáde wá, ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá; àánú wọ́n ṣe é,+ ó sì wo àwọn aláìsàn wọn sàn.+ 15  Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé: “Ibí yìí dá, wákàtí ọjọ́ sì ti lọ jìnnà nísinsìnyí; rán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ, kí wọ́n lè lọ sínú àwọn abúlé, kí wọ́n sì ra àwọn ohun jíjẹ fún ara wọn.”+ 16  Bí ó ti wù kí ó rí, Jésù wí fún wọn pé: “Wọn kò ní láti lọ: ẹ̀yin ẹ fún wọn ní nǹkan láti jẹ.”+ 17  Wọ́n wí fún un pé: “Àwa kò ní nǹkan kan níhìn-ín bí kò ṣe ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì.”+ 18  Ó wí pé: “Ẹ mú wọn wá fún mi níhìn-ín.” 19  Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà láti rọ̀gbọ̀kú sórí koríko, ó sì mú ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì náà, àti, ní wíwo òkè ọ̀run, ó súre,+ lẹ́yìn bíbu àwọn ìṣù búrẹ́dì náà, ó sì pín wọn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀wẹ̀ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà.+ 20  Nítorí náà, gbogbo wọ́n jẹ, wọ́n sì yó, wọ́n sì kó àṣẹ́kùsílẹ̀ àwọn èébù jọ, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ méjìlá.+ 21  Síbẹ̀, àwọn tí wọ́n jẹ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, láìka àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké.+ 22  Nígbà náà, láìjáfara, ó ṣe é ní ọ̀ranyàn fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n sì lọ ṣáájú rẹ̀ sí ìhà kejì, nígbà tí ó rán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ.+ 23  Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, lẹ́yìn rírán àwọn ogunlọ́gọ̀ náà lọ, ó gun òkè ńlá lọ ní òun nìkan láti gbàdúrà.+ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti lọ, ó wà níbẹ̀ ní òun nìkan ṣoṣo. 24  Ní báyìí, ọkọ̀ ojú omi náà wà ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwọ̀n yáàdì sí orí ilẹ̀, wọ́n dojú kọ ìṣòro láti ọwọ́ ìgbì,+ nítorí pé ẹ̀fúùfù ṣọwọ́ òdì sí wọn. 25  Ṣùgbọ́n ní sáà ìṣọ́ kẹrin òru, ó wá sọ́dọ̀ wọn, ní rírìn lórí òkun.+ 26  Nígbà tí wọ́n tajú kán rí i tí ó ń rìn lórí òkun, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dààmú, wọ́n wí pé: “Ìran abàmì kan ni!”+ Wọ́n sì ké jáde nínú ìbẹ̀rù wọn. 27  Ṣùgbọ́n ní kíá, Jésù fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí bá wọn sọ̀rọ̀: “Ẹ mọ́kànle, èmi ni;+ ẹ má bẹ̀rù.” 28  Ní ìfèsìpadà, Pétérù wí fún un pé: “Olúwa, bí ìwọ bá ni, pàṣẹ fún mi láti wá bá ọ lórí omi.” 29  Ó wí pé: “Máa bọ̀!” Lójú ẹsẹ̀, ní sísọ̀ kalẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi,+ Pétérù rìn lórí omi, ó sì gbọ̀nà ọ̀dọ̀ Jésù lọ. 30  Ṣùgbọ́n ní wíwo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ó fòyà àti pé, lẹ́yìn tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí rì, ó ké jáde pé: “Olúwa, gbà mí là!” 31  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ní nína ọwọ́ rẹ̀, Jésù dì í mú, ó sì wí fún un pé: “Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?”+ 32  Lẹ́yìn tí wọ́n sì ti gòkè sínú ọkọ̀ ojú omi, ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà rọlẹ̀. 33  Nígbà náà ni àwọn tí ń bẹ nínú ọkọ̀ ojú omi wárí fún un, wọ́n wí pé: “Ọmọ Ọlọ́run+ ni ìwọ jẹ́ ní ti tòótọ́.” 34  Wọ́n sì sọdá, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+ 35  Nígbà tí wọ́n mọ̀ dájú pé òun ni, àwọn ènìyàn ibẹ̀ ránṣẹ́ jáde sí gbogbo ìgbèríko tí ó wà ní àyíká yẹn, àwọn ènìyàn sì mú gbogbo àwọn tí ń ṣàmódi wá sọ́dọ̀ rẹ̀.+ 36  Wọ́n sì ń pàrọwà fún un pé kí wọ́n sáà lè fọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀;+ gbogbo àwọn tí wọ́n sì fọwọ́ kàn án ni a mú lára dá ṣáṣá.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé