Mátíù 11:1-30
11 Wàyí o, nígbà tí Jésù parí fífún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá ní àwọn ìtọ́ni, ó mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n láti ibẹ̀ láti kọ́ni àti láti wàásù nínú àwọn ìlú ńlá wọn.+
2 Ṣùgbọ́n Jòhánù, nígbà tí ó ti gbọ́ nínú túbú+ nípa àwọn iṣẹ́ Kristi, ó ránṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tirẹ̀,
3 ó sì wí fún un pé: “Ṣé ìwọ ni Ẹni Tí Ń Bọ̀, tàbí kí a máa fojú sọ́nà fún ẹnì kan tí ó yàtọ̀?”+
4 Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ, kí ẹ sì ròyìn fún Jòhánù ohun tí ẹ ń gbọ́, tí ẹ sì ń rí:
5 Àwọn afọ́jú ń padà ríran,+ àwọn arọ+ sì ń rìn káàkiri, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀+ mọ́, àwọn adití+ sì ń gbọ́ràn, a sì ń gbé àwọn òkú+ dìde, a sì ń polongo ìhìn rere+ fún àwọn òtòṣì;
6 aláyọ̀ sì ni ẹni tí kò rí okùnfà kankan fún ìkọ̀sẹ̀ nínú mi.”+
7 Nígbà tí àwọn wọ̀nyí ń lọ ní ọ̀nà wọn, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn ogunlọ́gọ̀ náà nípa Jòhánù pé: “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aginjù?+ Ṣé esùsú tí ẹ̀fúùfù ń bì síwá-sẹ́yìn ni?+
8 Kí wá ni ẹ jáde lọ wò? Ṣé ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù múlọ́múlọ́ ni? Họ́wù, àwọn tí wọ́n wọ ẹ̀wù múlọ́múlọ́ ń bẹ ní ilé àwọn ọba.+
9 Ní ti gidi, nígbà náà, èé ṣe tí ẹ fi jáde lọ? Ṣé láti rí wòlíì kan ni? Bẹ́ẹ̀ ni, mo sọ fún yín, àti èyí tí ó ju wòlíì kan lọ́pọ̀lọpọ̀.+
10 Èyí ni ẹni tí a kọ̀wé nípa rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Èmi fúnra mi yóò rán ońṣẹ́ mi jáde níwájú rẹ, ẹni tí yóò palẹ̀ ọ̀nà rẹ mọ́ ṣáájú rẹ!’+
11 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé, Láàárín àwọn tí obìnrin bí,+ a kò tíì gbé ẹnì kan dìde tí ó tóbi ju Jòhánù Oníbatisí lọ; ṣùgbọ́n ẹnì kan tí ó jẹ́ ẹni tí ó kéré jù nínú ìjọba+ ọ̀run tóbi jù ú.
12 Ṣùgbọ́n láti àwọn ọjọ́ Jòhánù Oníbatisí títí di ìsinsìnyí, ìjọba ọ̀run ni góńgó tí àwọn ènìyàn ń fi ìsapá lépa, àwọn tí ń fi ìsapá tẹ̀ síwájú sì ń gbá a mú.+
13 Nítorí pé gbogbo wọn, àwọn Wòlíì àti Òfin, sọ tẹ́lẹ̀ títí di ìgbà Jòhánù;+
14 bí ẹ bá sí fẹ́ láti tẹ́wọ́ gbà á, Òun fúnra rẹ̀ ni ‘Èlíjà tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti wá.’+
15 Kí ẹni tí ó bá ní etí fetí sílẹ̀.+
16 “Ta ni èmi yóò fi ìran yìí wé?+ Ó dà bí àwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n jókòó ní àwọn ibi ọjà, tí wọ́n ń ké jáde sí àwọn alájùmọ̀-ṣeré wọn,+
17 pé, ‘Àwa fọn fèrè fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò jó; àwa pohùn réré ẹkún, ṣùgbọ́n ẹ kò lu ara yín nínú ẹ̀dùn-ọkàn.’+
18 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jòhánù wá, kò jẹ bẹ́ẹ̀ ni kò mu,+ síbẹ̀ àwọn ènìyàn sọ pé, ‘Ó ní ẹ̀mí èṣù’;
19 Ọmọ ènìyàn sì wá, ó ń jẹ, ó sì ń mu,+ síbẹ̀ àwọn ènìyàn sọ pé, ‘Wò ó! Ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alájẹkì, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún mímu wáìnì, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’+ Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rẹ̀.”+
20 Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí gan àwọn ìlú ńlá nínú èyí tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn iṣẹ́ agbára rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀, nítorí pé wọn kò ronú pìwà dà:+
21 “Ègbé ni fún ọ, Kórásínì! Ègbé ni fún ọ, Bẹtisáídà!+ nítorí pé bí àwọn iṣẹ́ agbára tí ó ti ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ti ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì, wọn ì bá ti ronú pìwà dà tipẹ́tipẹ́ nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú.+
22 Nítorí náà, mo wí fún yín, Yóò ṣeé fara dà fún Tírè àti Sídónì ní Ọjọ́ Ìdájọ́+ jù fún yín lọ.+
23 Àti ìwọ, Kápánáúmù,+ ó ha lè jẹ́ pé a óò gbé ọ ga dé ọ̀run? Hédíìsì+ nísàlẹ̀ ni ìwọ yóò wá;+ nítorí pé bí àwọn iṣẹ́ agbára tí ó ṣẹlẹ̀ nínú rẹ bá ti ṣẹlẹ̀ ní Sódómù, ì bá wà títí di òní yìí gan-an.
24 Nítorí náà, mo wí fún yín pé, Yóò ṣeé fara dà fún ilẹ̀ Sódómù ní Ọjọ́ Ìdájọ́ jù fún yín lọ.”+
25 Ní àkókò yẹn, Jésù sọ ní ìdáhùnpadà pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.+
26 Bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ Baba, nítorí pé láti ṣe bẹ́ẹ̀ wá jẹ́ ọ̀nà tí ìwọ tẹ́wọ́ gbà.
27 Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi lé mi lọ́wọ́,+ kò sì sí ẹnì kankan tí ó mọ Ọmọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Baba,+ bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò mọ Baba ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ bí kò ṣe Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ fẹ́ láti ṣí i payá fún.+
28 Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn,+ dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára.
29 Ẹ gba àjàgà+ mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi,+ nítorí onínú tútù+ àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura+ fún ọkàn yín.
30 Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.”+

