Máàkù 8:1-38

8  Ní ọjọ́ wọnnì, nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ńlá kan tún ń bẹ, tí wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ, ó fi ọlá àṣẹ pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí fún wọn pé:+ 2  “Àánú+ ogunlọ́gọ̀ náà ń ṣe mí, nítorí pé ó ti di ọjọ́ mẹ́ta báyìí tí wọ́n ti wà pẹ̀lú mi, tí wọn kò sì ní nǹkan kan láti jẹ; 3  bí mo bá sì ní láti rán wọn lọ sí ilé wọn ní gbígbààwẹ̀, okun wọn yóò tán ní ojú ọ̀nà. Ní tòótọ́, àwọn kan lára wọn wá láti ibi jíjìnnàréré.” 4  Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dá a lóhùn pé: “Láti ibo ni ẹnikẹ́ni níhìn-ín ní ibi àdádó yìí ti lè fi ìṣù búrẹ́dì bọ àwọn ènìyàn wọ̀nyí yó?”+ 5  Síbẹ̀, ó ń bá a lọ láti béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ìṣù búrẹ́dì mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n wí pé: “Méje.”+ 6  Ó sì fún ogunlọ́gọ̀ náà ní ìtọ́ni láti rọ̀gbọ̀kú sórí ilẹ̀, ó sì mú ìṣù búrẹ́dì méje náà, ó dúpẹ́,+ ó bù wọ́n, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti fi fúnni, wọ́n sì fi wọ́n fún ogunlọ́gọ̀ náà.+ 7  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ní ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀; àti pé, lẹ́yìn sísúre sí ìwọ̀nyí, ó sọ fún wọn pẹ̀lú láti fi ìwọ̀nyí fúnni.+ 8  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n jẹ, wọ́n sì yó, wọ́n sì kó àṣẹ́kùsílẹ̀ èébù jọ, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ìpèsè méje.+ 9  Síbẹ̀, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin wà níbẹ̀. Níkẹyìn, ó rán wọn lọ.+ 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wá sí àwọn apá Dámánútà.+ 11  Níhìn-ín, àwọn Farisí jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a ṣe awuyewuye, wọ́n ń wá àmì kan láti ọ̀run wá lọ́wọ́ rẹ̀, láti dán an wò.+ 12  Nítorí náà, ó kérora gidigidi+ nínú ẹ̀mí rẹ̀, ó sì wí pé: “Èé ṣe tí ìran yìí fi ń wá àmì kan? Lóòótọ́ ni mo wí, A kì yóò fi àmì kankan fún ìran yìí.”+ 13  Pẹ̀lú èyíinì, ó fi wọ́n sílẹ̀, ó tún wọkọ̀, ó sì lọ sí èbúté òdì-kejì. 14  Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́, wọ́n gbàgbé láti kó ìṣù búrẹ́dì dání, wọn kò sì ní nǹkan kan pẹ̀lú wọn nínú ọkọ̀ ojú omi àyàfi ìṣù búrẹ́dì kan ṣoṣo.+ 15  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa àṣẹ ìtọ́ni fún wọn lọ́nà tí ó ṣe kedere, ó sì wí pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.”+ 16  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ba ara wọn jiyàn lẹ́nì kìíní-kejì lórí òtítọ́ náà pé wọn kò ní ìṣù búrẹ́dì kankan.+ 17  Ní kíkíyèsí èyí, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń jiyàn lórí níní tí ẹ kò ní ìṣù búrẹ́dì kankan?+ Ṣé ẹ kò tíì róye síbẹ̀, kí ẹ sì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀ ni? Ṣé ọkàn-àyà yín pòkúdu nínú lílóye ni?+ 18  ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní ojú, ṣé ẹ kò ríran ni; àti pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ní etí, ṣé ẹ kò gbọ́ran ni?’+ Ẹ kò ha sì rántí, 19  nígbà tí mo bu ìṣù búrẹ́dì márùn-ún+ fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọkùnrin, mélòó ni ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ èébù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n wí fún un pé: “Méjìlá.”+ 20  “Nígbà tí mo bu méje fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọkùnrin, mélòó ni iye ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ìpèsè àwọn èébù tí ẹ kó jọ?” Wọ́n sì wí fún un pé: “Méje.”+ 21  Pẹ̀lú èyíinì, ó wí fún wọn pé: “Ṣé ẹ kò tíì lóye ìtúmọ̀ rẹ̀ síbẹ̀?”+ 22  Wàyí o, wọ́n gúnlẹ̀ ní Bẹtisáídà. Níhìn-ín ni àwọn ènìyàn ti mú ọkùnrin afọ́jú kan wá bá a, wọ́n sì pàrọwà fún un pé kí ó fọwọ́ kàn+ án. 23  Ó sì di ọwọ́ ọkùnrin afọ́jú náà mú, ó mú un jáde sẹ́yìn òde abúlé náà, àti pé, lẹ́yìn tí ó tutọ́+ sí ojú rẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ ha rí ohunkóhun bí?” 24  Ọkùnrin náà sì gbé ojú sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: “Mo rí àwọn ènìyàn, nítorí mo ṣàkíyèsí àwọn ohun tí ó jọ igi, ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn káàkiri.” 25  Lẹ́yìn náà, ó tún gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú ọkùnrin náà, ọkùnrin náà sì ríran kedere, a sì mú un padà bọ̀ sípò, ó sì ń rí ohun gbogbo ní ketekete. 26  Nítorí náà, ó rán an lọ sí ilé, wí pé: “Ṣùgbọ́n má ṣe wọ abúlé.”+ 27  Wàyí o, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí àwọn abúlé Kesaréà Fílípì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè ní ọ̀nà, ní sísọ fún wọn pé: “Ta ni àwọn ènìyàn ń sọ pé mo jẹ́?”+ 28  Wọ́n sọ fún un pé: “Jòhánù Oníbatisí,+ àti àwọn mìíràn, Èlíjà,+ síbẹ̀ àwọn mìíràn, Ọ̀kan nínú àwọn wòlíì.”+ 29  Ó sì bi wọ́n léèrè pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?” Ní ìdáhùn, Pétérù sọ fún un pé: “Ìwọ ni Kristi náà.”+ 30  Látàrí ìyẹn, ó fi àìyẹhùn pàṣẹ fún wọn láti má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni nípa òun.+ 31  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn pé Ọmọ ènìyàn gbọ́dọ̀ fara gba ọ̀pọ̀ ìjìyà, kí àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì kọ̀ ọ́ tì, kí a sì pa á,+ kí ó sì dìde ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà.+ 32  Ní tòótọ́, àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ ni ó fi ń sọ gbólóhùn yẹn. Ṣùgbọ́n Pétérù mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí lọ́nà mímúná.+ 33  Ó yí padà, ó bojú wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì bá Pétérù wí lọ́nà mímúná, ó sì wí pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”+ 34  Wàyí o, ó pe ogunlọ́gọ̀ náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.+ 35  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là yóò pàdánù rẹ̀; ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù ọkàn rẹ̀ nítorí èmi àti ìhìn rere yóò gbà á là.+ 36  Ní ti gidi, àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀?+ 37  Ní ti gidi, kí ni ènìyàn kan yóò fi fúnni ní pàṣípààrọ̀ fún ọkàn rẹ̀?+ 38  Nítorí ẹnì yòówù tí ó bá tijú èmi àti àwọn ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panṣágà àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí, Ọmọ ènìyàn pẹ̀lú yóò tijú+ rẹ̀ nígbà tí ó bá dé nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì mímọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé