Máàkù 4:1-41
4 Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni lẹ́bàá òkun.+ Ogunlọ́gọ̀ ńláǹlà sì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi wọ ọkọ̀ ojú omi kan, ó sì jókòó lókèèrè lórí òkun, ṣùgbọ́n gbogbo ogunlọ́gọ̀ tí ń bẹ lẹ́bàá òkun wà ní èbúté.+
2 Nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àpèjúwe+ kọ́ wọn ní ohun púpọ̀, ó sì ń sọ fún wọn nínú ẹ̀kọ́+ rẹ̀ pé:
3 “Ẹ fetí sílẹ̀. Wò ó! Afúnrúgbìn jáde lọ láti fúnrúgbìn.+
4 Bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, irúgbìn díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ojú ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ.+
5 Irúgbìn mìíràn sì bọ́ sórí ibi àpáta níbi tí, ó dájú pé, kò ti ní erùpẹ̀ púpọ̀, ó sì rúyọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí ṣíṣàìní erùpẹ̀ jíjinlẹ̀.+
6 Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn là, a jó o gbẹ, àti nítorí ṣíṣàìní gbòǹgbò, ó rọ.+
7 Irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàárín àwọn ẹ̀gún, àwọn ẹ̀gún náà sì yọ, wọ́n sì fún un pa, kò sì so èso kankan.+
8 Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn bọ́ sórí erùpẹ̀ àtàtà,+ àti pé, ní jíjáde wá àti ní gbígbèrú sí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí so èso, wọ́n sì ń so ní ìlọ́po ọgbọ̀n, àti ọgọ́ta àti ọgọ́rùn-ún.”+
9 Nítorí náà, ó fi ọ̀rọ̀ náà kún un pé: “Kí ẹni tí ó ní etí láti fetí sílẹ̀, fetí sílẹ̀.”+
10 Wàyí o, nígbà tí ó wà ní òun nìkan, àwọn tí wọ́n yí i ká pẹ̀lú àwọn méjìlá náà bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè nípa àwọn àpèjúwe náà.+
11 Ó sì tẹ̀ síwájú ní sísọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin ni a ti fún ní àṣírí ọlọ́wọ̀+ ti ìjọba Ọlọ́run, ṣùgbọ́n fún àwọn tí ń bẹ lẹ́yìn òde, gbogbo nǹkan ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn àpèjúwe,+
12 kí ó bàa lè jẹ́ pé, bí wọ́n tilẹ̀ ń wò, kí wọ́n lè máa wò, síbẹ̀ kí wọ́n má ṣe rí, àti pé, bí wọ́n tilẹ̀ ń gbọ́, kí wọ́n lè gbọ́, síbẹ̀ kí òye rẹ̀ má sì yé wọn, tàbí kí wọ́n má ṣe yí padà láé, kí a sì fún wọn ní ìdáríjì.”+
13 Síwájú sí i, ó wí fún wọn pé: “Ẹ kò mọ àpèjúwe yìí, nítorí náà báwo sì ni ẹ ó ṣe lóye gbogbo àpèjúwe yòókù?
14 “Afúnrúgbìn fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà.+
15 Nígbà náà, ìwọ̀nyí ni àwọn ti ẹ̀bá ojú ọ̀nà níbi tí a gbin ọ̀rọ̀ náà sí; ṣùgbọ́n gbàrà tí wọ́n ti gbọ́ ọ, Sátánì wá,+ ó sì mú ọ̀rọ̀ tí a gbìn sínú wọn kúrò.+
16 Bákan náà, ìwọ̀nyí sì ni àwọn tí a fún sórí àwọn ibi àpáta: gbàrà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, wọ́n fi ìdùnnú tẹ́wọ́ gbà á.+
17 Síbẹ̀, wọn kò ní gbòǹgbò kankan nínú ara wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń bá a lọ fún àkókò kan; lẹ́yìn náà, gbàrà tí ìpọ́njú tàbí inúnibíni dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n kọsẹ̀.+
18 Àwọn mìíràn ṣì wà tí a fún sáàárín àwọn ẹ̀gún; ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà,+
19 ṣùgbọ́n àníyàn+ ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀+ àti àwọn ìfẹ́-ọkàn+ fún àwọn nǹkan yòókù gbógun wọlé, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso.+
20 Níkẹyìn, àwọn tí a fún sórí erùpẹ̀ àtàtà ni àwọn tí wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ náà, tí wọ́n sì fi ọkàn rere gbà á, tí wọ́n sì ń so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n àti ọgọ́ta àti ọgọ́rùn-ún.”+
21 Ó sì ń bá a lọ ní sísọ fún wọn pé: “A kì í gbé fìtílà wá láti gbé e sábẹ́ apẹ̀rẹ̀ ìdíwọ̀n tàbí sábẹ́ ibùsùn, àbí? A máa ń gbé e wá láti gbé e sórí ọ̀pá fìtílà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?+
22 Nítorí kò sí ohun tí a fi pa mọ́ bí kò ṣe fún ète fífi í hàn síta; kò sí ohun tí a rọra tọ́jú pa mọ́ bí kò ṣe fún ète wíwá sí ojútáyé.+
23 Ẹnì yòówù tí ó bá ní etí láti fetí sílẹ̀, kí ó fetí sílẹ̀.”+
24 Ó wí fún wọn síwájú sí i pé: “Ẹ fiyè sí ohun tí ẹ ń gbọ́.+ Òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni a ó fi díwọ̀n fún yín,+ bẹ́ẹ̀ ni, a ó fi púpọ̀ sí i kún un fún yín.+
25 Nítorí ẹni tí ó ní ni a ó fi púpọ̀ sí i fún; ṣùgbọ́n ẹni tí kò ní, ohun tí ó ní pàápàá ni a ó gbà lọ́wọ́ rẹ̀.+
26 Nítorí náà, ó ń bá a lọ ní sísọ pé: “Lọ́nà yìí, ìjọba Ọlọ́run rí gan-an gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ẹnì kan sọ irúgbìn sórí ilẹ̀,+
27 ó sì sùn ní òru, ó sì dìde ní ojúmọ́, irúgbìn náà sì rú jáde, ó sì dàgbà sókè, gan-an bí ó ṣe ṣẹlẹ̀, òun kò mọ̀.+
28 Ilẹ̀ fúnra rẹ̀ ń so èso ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lákọ̀ọ́kọ́ ewé koríko, lẹ́yìn náà pòròpórò erínkà, ní ìkẹyìn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkà nínú erínkà.
29 Ṣùgbọ́n gbàrà tí èso bá gba èyí láyè, òun a ti dòjé bọ̀ ọ́, nítorí àkókò ìkórè ti dé.”
30 Ó sì ń bá a lọ ní sísọ pé: “Kí ni ohun tí a ó fi ìjọba Ọlọ́run wé, tàbí àpèjúwe wo ni a ó fi gbé e kalẹ̀?+
31 Bí hóró músítádì kan, tí ó jẹ́ pé ní àkókò tí a gbìn ín sínú ilẹ̀, ó jẹ́ tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé+—
32 ṣùgbọ́n nígbà tí a ti gbìn ín, ó yọ, ó sì tóbi ju gbogbo ọ̀gbìn oko yòókù, ó sì mú àwọn ẹ̀ka ńlá jáde,+ tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run+ lè rí ibùwọ̀ lábẹ́ òjìji rẹ̀.”+
33 Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àpèjúwe+ tí ó jẹ́ irú èyí ni òun fi ń bá wọn sọ̀rọ̀, bí wọ́n ti lè fetí sílẹ̀ tó.
34 Ní tòótọ́, kì í bá wọn sọ̀rọ̀ láìsí àpèjúwe, ṣùgbọ́n ní ìdákọ́ńkọ́, yóò ṣàlàyé ohun gbogbo+ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.
35 Nígbà tí ó sì di ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ yẹn, ó wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí a sọdá sí èbúté kejì.”+
36 Nítorí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti rán ogunlọ́gọ̀ náà lọ, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi náà gbé e, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, àwọn ọkọ̀ ojú omi mìíràn sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+
37 Wàyí o, ìjì ẹlẹ́fùúùfù ńlá lílenípá kan bẹ́ sílẹ̀, ìgbì sì ń rọ́ wọnú ọkọ̀ ojú omi ṣáá, tó bẹ́ẹ̀ tí omi fi fẹ́rẹ̀ẹ́ bo ọkọ̀ ojú omi náà mọ́lẹ̀.+
38 Ṣùgbọ́n ó wà ní ìdí ọkọ̀, ó ń sùn lórí ìrọ̀rí kan. Nítorí náà, wọ́n jí i, wọ́n sì wí fún un pé: “Olùkọ́, ìwọ kò ha bìkítà pé a ti fẹ́ẹ̀rẹ́ ṣègbé?”+
39 Pẹ̀lú ìyẹn, ó gbéra nílẹ̀, ó sì bá ẹ̀fúùfù náà wí lọ́nà mímúná, ó sì wí fún òkun náà pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!”+ Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé.+
40 Nítorí náà, ó wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń ṣọkàn ojo? Ṣé síbẹ̀síbẹ̀ ẹ kò tíì ní ìgbàgbọ́ kankan ni?”
41 Ṣùgbọ́n ìbẹ̀rù àrà ọ̀tọ̀ mú wọn, wọ́n sì ń wí fún ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì pé: “Ta nìyí ní ti gidi, nítorí ẹ̀fúùfù àti òkun pàápàá ń ṣègbọràn sí i?”+

