Máàkù 3:1-35
3 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ó wọ inú sínágọ́gù kan, ọkùnrin kan sì wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ gbẹ hangogo.+
2 Nítorí náà, wọ́n ń ṣọ́ ọ lójú méjèèjì láti rí i bóyá yóò wo ọkùnrin náà sàn ní sábáàtì, kí wọ́n bàa lè fẹ̀sùn kàn án.+
3 Ó sì wí fún ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé: “Dìde, kí o sì wá sí àárín.”
4 Lẹ́yìn náà, ó wí fún wọn pé: “Ó ha bófin mu ní sábáàtì láti ṣe iṣẹ́ rere tàbí láti ṣe iṣẹ́ búburú, láti gba ọkàn là tàbí láti pa á?”+ Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́.
5 Lẹ́yìn tí ó sì ti wò wọ́n yí ká pẹ̀lú ìkannú, nítorí tí ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi sí yíyigbì ọkàn-àyà wọn,+ ó sọ fún ọkùnrin náà pé: “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì nà án, a sì mú ọwọ́ rẹ̀ padà bọ̀ sípò.+
6 Látàrí ìyẹn, àwọn Farisí jáde lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbìmọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú àjọ ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Hẹ́rọ́dù+ lòdì sí i, láti pa á run.+
7 Ṣùgbọ́n Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ sí òkun; ògìdìgbó ńlá láti Gálílì àti láti Jùdíà sì tẹ̀ lé e.+
8 Àní láti Jerúsálẹ́mù àti láti Ídúmíà àti láti òdì-kejì Jọ́dánì àti àyíká Tírè+ àti Sídónì, ni ògìdìgbó ńlá ti wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa bí àwọn ohun tí ó ń ṣe ti pọ̀ tó.
9 Ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo fún ìlò òun, kí ogunlọ́gọ̀ má bàa há a gádígádí.
10 Nítorí tí ó wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn, pẹ̀lú ìyọrísí náà pé gbogbo àwọn tí wọ́n ní òkùnrùn burúkú ń ṣù mọ́ ọn láti fọwọ́ kàn án.+
11 Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá,+ nígbàkigbà tí wọ́n bá rí i, wọn a wólẹ̀ níwájú rẹ̀, wọn a sì ké jáde, pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.”+
12 Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ó pàṣẹ kíkankíkan fún wọn láti má ṣe sọ òun di mímọ̀.+
13 Ó sì gun òkè ńlá kan, ó sì fi ọlá àṣẹ pe àwọn tí ó fẹ́,+ wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.+
14 Ó sì kó àwùjọ àwọn méjìlá jọ, àwọn tí ó pè ní “àpọ́sítélì” pẹ̀lú, kí wọ́n lè máa bá a lọ ní wíwà pẹ̀lú òun, kí ó sì lè rán wọn jáde láti wàásù+
15 àti láti ní ọlá àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+
16 Àwùjọ àwọn méjìlá tí ó kó jọ sì ni Símónì, ẹni tí ó fún ní orúkọ àpèlé náà Pétérù,+
17 àti Jákọ́bù ọmọkùnrin Sébédè àti Jòhánù arákùnrin Jákọ́bù+ (ó tún fún àwọn wọ̀nyí ní orúkọ àpèlé náà Bóánágè, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn Ọmọ Ààrá),
18 àti Áńdérù àti Fílípì àti Bátólómíù àti Mátíù àti Tọ́másì àti Jákọ́bù ọmọkùnrin Áfíọ́sì àti Tádéọ́sì àti Símónì tí í ṣe Kánánéánì
19 àti Júdásì Ísíkáríótù, ẹni tí ó dà á níkẹyìn.+
Ó sì wọ ilé kan.
20 Lẹ́ẹ̀kan sí i, ogunlọ́gọ̀ náà kóra jọ, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè jẹ oúnjẹ pàápàá.+
21 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ẹbí+ rẹ̀ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n jáde lọ láti gbá a mú, nítorí wọ́n ń wí pé: “Orí rẹ̀ ti yí.”+
22 Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn akọ̀wé òfin tí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ wá láti Jerúsálẹ́mù ń wí pé: “Ó ní Béélísébúbù, ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípasẹ̀ olùṣàkóso àwọn ẹ̀mí èṣù.”+
23 Nítorí náà, lẹ́yìn tí ó ti pè wọ́n wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn àpèjúwe sọ fún wọn pé: “Báwo ni Sátánì ṣe lè lé Sátánì jáde?
24 Họ́wù, bí ìjọba kan bá pínyà sí ara rẹ̀, ìjọba yẹn kò ní lè dúró;+
25 bí ilé kan bá sì pínyà sí ara rẹ̀, ilé yẹn kì yóò lè dúró.+
26 Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí Sátánì bá ti dìde lòdì sí ara rẹ̀, tí ó sì pínyà, kò ní lè dúró, ṣùgbọ́n ó ń bọ̀ wá sí òpin.+
27 Ní ti tòótọ́, kò sí ẹnì kan tí ó dé inú ilé ọkùnrin alágbára kan tí ó lè piyẹ́+ àwọn ẹrù rẹ̀ tí ó ṣeé gbé, láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ de ọkùnrin alágbára náà, lẹ́yìn náà, yóò sì piyẹ́ ilé rẹ̀.+
28 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé ohun gbogbo ni a óò dárí ji àwọn ọmọ ènìyàn, ẹ̀ṣẹ̀ yòówù kí wọ́n dá àti ọ̀rọ̀ òdì yòówù kí wọ́n sọ lọ́nà ọ̀rọ̀ òdì.+
29 Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì yòówù tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, kò ní ìdáríjì kankan títí láé, ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ àìnípẹ̀kun.”+
30 Èyí jẹ́, nítorí wọ́n ń wí pé: “Ó ní ẹ̀mí àìmọ́.”+
31 Wàyí o, ìyá rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀+ wá, àti pé, bí wọ́n ṣe dúró lòde, wọ́n ránṣẹ́ wọlé lọ bá a láti pè é wá.+
32 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́, ogunlọ́gọ̀ jókòó yí i ká, nítorí náà wọ́n wí fún un pé: “Wò ó! Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ ń wá ọ lóde.”+
33 Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà ó wí fún wọn pé: “Ta ni ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi?”+
34 Lẹ́yìn tí ó sì ti wo àwọn tí wọ́n jókòó yí i ká bìrìkìtì, ó wí pé: “Wò ó, ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!+
35 Ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹni yìí ni arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá mi.”+

