Máàkù 16:1-20

16  Nítorí náà, nígbà tí sábáàtì+ ti kọjá, Màríà Magidalénì,+ àti Màríà ìyá Jákọ́bù, àti Sàlómẹ̀ ra àwọn èròjà atasánsán kí wọ́n lè wá fi pa á lára.+  Ní kùtù hàì ọjọ́ kìíní+ ọ̀sẹ̀, wọ́n wá síbi ibojì ìrántí náà, nígbà tí oòrùn ti là.+  Wọ́n sì ń sọ, ọ̀kan fún èkejì pé: “Ta ni yóò bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ọ̀nà ibojì ìrántí náà?”  Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé a ti yí òkúta náà kúrò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tóbi gan-an.+  Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì ìrántí náà, wọ́n rí ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ó wọ aṣọ funfun, wọ́n sì ta kìjí.+  Ó wí fún wọn pé: “Ẹ dẹ́kun títakìjí. Jésù ará Násárétì ni ẹ ń wá, ẹni tí a kàn mọ́gi.+ A ti gbé e+ dìde, kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.+  Ṣùgbọ́n ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti Pétérù pé, ‘Ó ń lọ ṣáájú yín sí Gálílì;+ ẹ óò rí i níbẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’”+  Nítorí náà, nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n sá kúrò ní ibojì ìrántí náà, nítorí ìwárìrì àti èrò ìmọ̀lára tí ó lágbára gbá wọn mú. Wọn kò sì sọ ohunkóhun fún ẹnì kankan, nítorí wọ́n ń bẹ̀rù.+ ÌPARÍ KÚKÚRÚ Àwọn ìwé àfọwọ́kọ àti àwọn ẹ̀dà ìtúmọ̀ kan tí wọ́n dé kẹ́yìn ní ìparí kúkúrú kan nínú, tí ó wà lẹ́yìn Máàkù 16:8, tí ó lọ báyìí pé: Ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí a ti pa láṣẹ ni wọ́n ṣèròyìn ní ṣókí fún àwọn tí wọ́n yí Pétérù ká. Síwájú sí i, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jésù fúnra rẹ̀ rán ìpòkìkí mímọ́ àti aláìlè-díbàjẹ́ ti ìgbàlà àìnípẹ̀kun jáde nípasẹ̀ wọn láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn. ÌPARÍ GÍGÙN Àwọn ìwé àfọwọ́kọ (ACD) àti àwọn ẹ̀dà ìtúmọ̀ (VgSyc,p) kan tí wọ́n jẹ́ ti ìgbàanì fi ìparí gígùn tí ó tẹ̀ lé e yìí kún un, ṣùgbọ́n èyí tí אBSysArm fò dá:  Lẹ́yìn tí ó dìde ní kùtùkùtù ní ọjọ́ kìíní ọ̀sẹ̀, ó kọ́kọ́ fara han Màríà Magidalénì, lára ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí èṣù méje jáde. 10  Ó lọ, ó sì ròyìn fún àwọn tí wọ́n ti wà pẹ̀lú rẹ̀, bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọ́n sì ń sunkún. 11  Ṣùgbọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ó ti yè àti pé ó ti rí i, wọn kò gbà gbọ́. 12  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó fara hàn ní ìrísí mìíràn fún méjì lára wọn tí wọ́n jọ ń rìn lọ, bí wọ́n ti ń lọ sí ìgbèríko; 13  wọ́n sì padà wá, wọ́n sì ròyìn fún àwọn yòókù. Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gba àwọn wọ̀nyí gbọ́. 14  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn mọ́kànlá náà fúnra wọn bí wọ́n ti rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, ó sì gan àìnígbàgbọ́ àti líle-ọkàn wọn, nítorí pé wọn kò gba àwọn wọnnì gbọ́, tí wọ́n rí i nísinsìnyí tí a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú. 15  Ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú gbogbo ayé, kí ẹ sì wàásù ìhìn rere fún gbogbo ìṣẹ̀dá. 16  Ẹni tí ó bá gbà gbọ́, tí a sì batisí ni a ó gbà là, ṣùgbọ́n ẹni tí kò bá gbà gbọ́ ni a óò dá lẹ́bi. 17  Síwájú sí i, àmì wọ̀nyí yóò máa bá àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ rìn: Nípa lílo orúkọ mi, wọn yóò lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, wọn yóò máa fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, 18  wọn yóò sì fi ọwọ́ wọn gbé ejò, bí wọ́n bá sì mu ohunkóhun tí ń ṣekú pani, kì yóò ṣe wọ́n lọ́ṣẹ́ rárá. Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé àwọn aláìsàn, àwọn wọ̀nyí yóò sì sàn.” 19  Nítorí bẹ́ẹ̀, lẹ́yìn tí Jésù Olúwa ti bá wọn sọ̀rọ̀, a gbé e lọ sókè sí ọ̀run, ó sì jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 20  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, wọ́n jáde lọ, wọ́n sì wàásù níbi gbogbo, nígbà tí Olúwa ń bá wọn ṣiṣẹ́, tí ó sì kín ìhìn-iṣẹ́ náà lẹ́yìn nípasẹ̀ àwọn àmì tí ń bá wọn rìn.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé