Máàkù 14:1-72

14  Wàyí o, ìrékọjá+ àti àjọyọ̀+ àkàrà aláìwú ku ọjọ́ méjì.+ Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin sì ń wá ọ̀nà láti fi ọgbọ́n àrékérekè gbá a mú, kí wọ́n sì pa á;+ 2  nítorí wọ́n sọ léraléra pé: “Kì í ṣe nígbà àjọyọ̀; bóyá ìrọ́kẹ̀kẹ̀ lè bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn náà.”+ 3  Nígbà tí ó sì wà ní Bẹ́tánì ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀,+ bí ó ti rọ̀gbọ̀kú nídìí oúnjẹ, obìnrin kan wá tí ó ní orùba alabásítà òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì, olówó ńlá gan-an. Bí ó ti já orùba alabásítà náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí dà á sí orí rẹ̀.+ 4  Látàrí èyí, àwọn kan wà tí wọ́n ń fi ìkannú hàn láàárín ara wọn pé: “Èé ṣe tí ìfiṣòfò òróró onílọ́fínńdà yìí fi ṣẹlẹ̀?+ 5  Nítorí òróró onílọ́fínńdà yìí ni à bá ti tà ní nǹkan tí ó ju ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì kí a sì fi fún àwọn òtòṣì!” Wọ́n sì ní ìbìnújẹ́ ńláǹlà sí i.+ 6  Ṣùgbọ́n Jésù wí pé: “Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́. Èé ṣe tí ẹ fi ń gbìyànjú láti dà á láàmú? Ó ṣe iṣẹ́ tí ó dára púpọ̀ sí mi.+ 7  Nítorí ẹ ní àwọn òtòṣì+ pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, nígbàkigbà tí ẹ bá sì fẹ́, ẹ lè ṣe rere fún wọn nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n èmi ni ẹ kò ní nígbà gbogbo.+ 8  Ó ṣe ohun tí ó lè ṣe; ó dáwọ́ lé e ṣáájú àkókò láti da òróró onílọ́fínńdà sí ara mi nítorí ìsìnkú.+ 9  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ibikíbi tí a bá ti wàásù ìhìn rere ní gbogbo ayé,+ ohun tí obìnrin yìí ṣe ni a ó sọ pẹ̀lú ní ìrántí rẹ̀.”+ 10  Júdásì Ísíkáríótù, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá náà, lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà láti fi í lé wọn lọ́wọ́.+ 11  Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n yọ̀, wọ́n sì ṣèlérí láti fún un ní owó fàdákà.+ Nítorí náà, ó ń wá ọ̀nà láti fi í lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú ìdẹ̀rùn.+ 12  Wàyí o, ní ọjọ́ kìíní àkàrà aláìwú,+ nígbà tí wọ́n máa ń fi ẹran ẹbọ ìrékọjá rúbọ lọ́nà àṣà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn+ rẹ̀ wí fún un pé: “Ibo ni o fẹ́ kí a lọ múra sílẹ̀ fún ọ láti jẹ ìrékọjá?”+ 13  Pẹ̀lú èyíinì, ó rán méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde, ó sì wí fún wọn pé: “Ẹ lọ sínú ìlú ńlá náà, ọkùnrin kan tí ó ru ládugbó omi yóò sì bá yín pàdé.+ Ẹ tẹ̀ lé e, 14  ibikíbi tí ó bá sì ti wọlé, ẹ sọ fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ sọ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà fún mi, níbi tí mo ti lè jẹ ìrékọjá+ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi?”’+ 15  Yóò sì fi yàrá ńlá kan ní òkè hàn yín, tí a ti pèsè àwọn ohun èlò ilé sí ní ìmúrasílẹ̀; kí ẹ sì múra ibẹ̀ sílẹ̀ fún wa.”+ 16  Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà jáde lọ, wọ́n sì wọ ìlú ńlá náà, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn gẹ́lẹ́; wọ́n sì múra sílẹ̀ fún ìrékọjá.+ 17  Lẹ́yìn tí alẹ́ ti lẹ́, ó wá pẹ̀lú àwọn méjìlá náà.+ 18  Bí wọ́n sì ti rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, tí wọ́n sì ń jẹun, Jésù wí pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ọ̀kan nínú yín, tí ń jẹun+ pẹ̀lú mi, yóò dà mí.”+ 19  Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ẹ̀dùn-ọkàn, wọ́n sì ń sọ fún un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan pé: “Kì í ṣe èmi, àbí èmi ni?”+ 20  Ó wí fún wọn pé: “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá náà ni, tí ń tiwọ́ bọ inú àwokòtò kan náà pẹ̀lú mi.+ 21  Lóòótọ́, Ọmọ ènìyàn ń lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin yẹn tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi Ọmọ ènìyàn léni lọ́wọ́! Ì bá ti sàn fún ọkùnrin yẹn ká ní a kò bí i.”+ 22  Bí wọ́n sì ti ń jẹun lọ, ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó súre, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó sì wí pé: “Ẹ gbà á, èyí túmọ̀ sí ara mi.”+ 23  Bí ó sì ti mú ife, ó dúpẹ́, ó sì fi í fún wọn, gbogbo wọ́n sì mu nínú rẹ̀.+ 24  Ó sì wí fún wọn pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀+ májẹ̀mú’+ mi, tí a óò tú+ jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.+ 25  Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kì yóò mu nínú àmújáde àjàrà mọ́ lọ́nàkọnà títí di ọjọ́ yẹn nígbà tí èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”+ 26  Níkẹyìn, lẹ́yìn kíkọrin ìyìn,+ wọ́n jáde lọ sí Òkè Ńlá Ólífì.+ 27  Jésù sì wí fún wọn pé: “A óò mú gbogbo yín kọsẹ̀, nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò kọlu olùṣọ́ àgùntàn,+ àwọn àgùntàn ni a ó sì tú ká káàkiri.’+ 28  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí a bá ti gbé mi dìde, dájúdájú, èmi yóò lọ ṣáájú yín sí Gálílì.”+ 29  Ṣùgbọ́n Pétérù wí fún un pé: “Àní bí a bá mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀, síbẹ̀ a kì yóò mú èmi kọsẹ̀.”+ 30  Látàrí ìyẹn, Jésù wí fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, Ìwọ lónìí, bẹ́ẹ̀ ni, ní òru yìí, kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, àní ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+ 31  Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ kíkankíkan pé: “Bí mo bá ní láti kú pẹ̀lú rẹ, dájúdájú, èmi kì yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ lọ́nàkọnà.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbogbo àwọn yòókù bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun kan náà.+ 32  Nítorí náà, wọ́n dé ibi tí a ń pè ní Gẹtisémánì, ó sì wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ jókòó níhìn-ín nígbà tí èmi yóò máa gbàdúrà.”+ 33  Ó sì mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù+ lọ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìdàrú-ọkàn, ó sì dààmú gidigidi.+ 34  Ó sì wí fún wọn pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi,+ àní títí dé ikú. Ẹ dúró síhìn-ín, kí ẹ sì máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”+ 35  Bí ó sì ti lọ síwájú díẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí wólẹ̀, ó sì ń gbàdúrà pé, bí ó bá ṣeé ṣe, kí wákàtí náà ré òun kọjá lọ.+ 36  Ó sì ń bá a lọ ní sísọ pé: “Ábà, Baba,+ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ọ; mú ife yìí kúrò lórí mi. Síbẹ̀, kì í ṣe ohun tí èmi fẹ́, bí kò ṣe ohun tí ìwọ fẹ́.”+ 37  Ó sì wá, ó sì bá wọn tí wọ́n ń sùn, ó sì wí fún Pétérù pé: “Símónì, ò ń sùn ni? Ṣé ìwọ kò ní okun láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà fún wákàtí kan ni?+ 38  Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà,+ kí ẹ má bàa wá sínú ìdẹwò. Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.”+ 39  Ó sì tún lọ gbàdúrà, ó ń sọ ọ̀rọ̀ kan náà.+ 40  Ó sì tún wá bá wọn tí wọ́n ń sùn, nítorí ojú wọn kún fún oorun, nítorí náà wọn kò mọ ohun tí wọn yóò fi dá a lóhùn.+ 41  Ó sì wá ní ìgbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé: “Ní irú àkókò yìí, ẹ ń sùn, ẹ sì ń sinmi! Ó tó! Wákàtí náà ti dé!+ Wò ó! A fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.+ 42  Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a lọ.+ Wò ó! Afinihàn mi ti sún mọ́ tòsí.”+ 43  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan lára àwọn méjìlá, dé àti pẹ̀lú rẹ̀ ogunlọ́gọ̀ tí wọ́n ní idà àti ọ̀gọ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbà ọkùnrin.+ 44  Wàyí o, afinihàn rẹ̀ ti fún wọn ní àmì àjọfohùnṣọ̀kan lé lórí, wí pé: “Ẹnì yòówù tí mo bá fẹnu kò lẹ́nu, òun ni ẹni náà; ẹ fi í sínú ìhámọ́, kí ẹ sì mú un lọ láìséwu.”+ 45  Ó sì wá tààràtà, ó sì sún mọ́ ọn, ó sì wí pé: “Rábì!” ó sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu+ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ gan-an. 46  Nítorí náà, wọ́n gbé ọwọ́ lé e, wọ́n sì fi í sínú ìhámọ́.+ 47  Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan lára àwọn tí wọ́n dúró nítòsí fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ dànù.+ 48  Ṣùgbọ́n ní ìdáhùnpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀gọ bí ẹni wá bá ọlọ́ṣà láti fi àṣẹ ọba mú mi?+ 49  Láti ọjọ́ dé ọjọ́ ni mo wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì tí mo ń kọ́ni,+ síbẹ̀síbẹ̀ ẹ kò fi mí sínú ìhámọ́. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí a lè mú Ìwé Mímọ́+ ṣẹ ni.”+ 50  Gbogbo wọ́n sì pa á tì,+ wọ́n sì sá lọ.+ 51  Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó wọ ẹ̀wù aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà bo ìhòòhò ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí; wọ́n sì gbìyànjú láti gbá a mú,+ 52  ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀wù aṣọ ọ̀gbọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn, ó sì sá lọ ní ìhòòhò. 53  Wàyí o, wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ àlùfáà àgbà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbà ọkùnrin àti àwọn akọ̀wé òfin sì péjọ.+ 54  Ṣùgbọ́n Pétérù tẹ̀ lé e+ ní òkèèrè réré títí dé inú àgbàlá àlùfáà àgbà; ó sì jókòó pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹmẹ̀wà inú ilé náà, ó sì ń yáná nídìí iná kan tí ó mọ́lẹ̀ yòò. 55  Láàárín àkókò náà, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo Sànhẹ́dírìn ń wá gbólóhùn ẹ̀rí lòdì sí Jésù láti fi ikú pa á,+ ṣùgbọ́n wọn kò rí ìkankan.+ 56  Ní tòótọ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń jẹ́rìí èké lòdì sí i,+ ṣùgbọ́n gbólóhùn ẹ̀rí wọn kò bára mu.+ 57  Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn kan ń dìde, wọ́n sì ń jẹ́rìí èké lòdì sí i, pé: 58  “Àwa gbọ́ tí ó sọ pé, ‘Dájúdájú, èmi yóò wó tẹ́ńpìlì yìí tí a fi ọwọ́ kọ́ palẹ̀ àti pé ní ọjọ́ mẹ́ta èmi yóò kọ́ òmíràn tí a kò fi ọwọ́ kọ́.’”+ 59  Ṣùgbọ́n lórí ìdí wọ̀nyí pẹ̀lú, gbólóhùn ẹ̀rí wọn kò bára mu. 60  Níkẹyìn, àlùfáà àgbà dìde ní àárín wọn, ó sì bi Jésù léèrè, pé: “Ṣé ìwọ kò sọ ohun kan ní ìfèsìpadà ni? Kí ni ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jẹ́rìí lòdì sí ọ?”+ 61  Ṣùgbọ́n ó dákẹ́, kò sì fèsì kankan rárá.+ Àlùfáà àgbà tún bẹ̀rẹ̀ sí bi í léèrè, ó sì wí fún un pé: “Ṣé ìwọ ni Kristi Ọmọ Ẹni Ìbùkún?”+ 62  Nígbà náà ni Jésù wí pé: “Èmi ni; ẹ ó sì rí Ọmọ ènìyàn+ tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún+ agbára, tí yóò sì máa bọ̀ nínú àwọsánmà ọ̀run.”+ 63  Látàrí èyí, àlùfáà àgbà fa ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ya,+ ó sì wí pé: “Kí ni a tún nílò àwọn ẹlẹ́rìí fún?+ 64  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ òdì náà.+ Kí ni ó hàn gbangba sí yín?” Gbogbo wọ́n dá a lẹ́bi pé ó yẹ fún ikú. 65  Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́+ sí i lára, wọ́n sì bo gbogbo ojú rẹ̀, wọ́n sì ń lù ú ní ẹ̀ṣẹ́, wọ́n sì wí fún un pé: “Sọ tẹ́lẹ̀!” Àti pé, ní gbígbá a lójú, àwọn ẹmẹ̀wà inú kóòtù mú un.+ 66  Wàyí o, nígbà tí Pétérù wà nísàlẹ̀ nínú àgbàlá náà, ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà wá,+ 67  bí ó sì ti rí Pétérù tí ó ń yáná, ó wò ó tààràtà, ó sì wí pé: “Ìwọ, náà, wà pẹ̀lú ará Násárétì náà, Jésù yìí.”+ 68  Ṣùgbọ́n ó sẹ́, pé: “Èmi kò mọ̀ ọ́n, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò lóye ohun tí ìwọ ń sọ,” ó sì jáde lọ sí gbọ̀ngàn àbáwọlé.+ 69  Níbẹ̀, ní rírí i, ìránṣẹ́bìnrin náà tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn tí wọ́n dúró nítòsí pé: “Ọ̀kan lára wọn nìyí.”+ 70  Ó tún ń sẹ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, àwọn tí wọ́n dúró nítòsí bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún Pétérù pé: “Dájúdájú, ọ̀kan lára wọn ni ọ́, nítorí, ní ti tòótọ́, ará Gálílì ni ọ́.”+ 71  Ṣùgbọ́n ó bẹ̀rẹ̀ sí gégùn-ún, ó sì ń búra+ pé: “Èmi kò mọ ọkùnrin yìí tí ẹ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”+ 72  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àkùkọ sì kọ ní ìgbà kejì;+ Pétérù sì rántí àsọjáde tí Jésù sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀mejì, ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+ Ó sì bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé