Máàkù 1:1-45

1  Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìhìn rere nípa Jésù Kristi:  Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Aísáyà wòlíì pé: “(Wò ó! Èmi yóò rán ońṣẹ́ mi jáde níwájú rẹ, ẹni tí yóò palẹ̀ ọ̀nà rẹ mọ́;)+  fetí sílẹ̀! ẹnì kan ń ké jáde ní aginjù pé, ‘Ẹ palẹ̀ ọ̀nà Jèhófà mọ́, ẹ mú àwọn ojú ọ̀nà rẹ̀ tọ́,’”+  Jòhánù olùbatisí fara hàn ní aginjù, ó ń wàásù ìbatisí gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.+  Nítorí náà, gbogbo ìpínlẹ̀ Jùdíà àti gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù jáde lọ bá a, ó sì batisí wọn nínú Odò Jọ́dánì, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní gbangba.+  Wàyí o, Jòhánù wọ irun ràkúnmí àti àmùrè awọ yí ká abẹ́nú rẹ̀,+ ó sì máa ń jẹ eéṣú+ àti oyin ìgàn.+  A sì máa wàásù, pé: “Lẹ́yìn mi, ẹnì kan tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀; èmi kò tó láti bẹ̀rẹ̀ tú àwọn okùn sálúbàtà rẹ̀.+  Èmi fi omi batisí yín, ṣùgbọ́n òun yóò fi ẹ̀mí mímọ́+ batisí yín.”  Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọnnì, Jésù wá láti Násárétì ti Gálílì, Jòhánù sì batisí rẹ̀ nínú Jọ́dánì.+ 10  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bí ó ti ń jáde sókè kúrò nínú omi, ó rí tí ọ̀run ń pínyà, àti pé, bí àdàbà, ẹ̀mí bà lé e;+ 11  ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.”+ 12  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀mí sún un láti lọ sínú aginjù.+ 13  Nítorí náà, ó ń bá a lọ ní wíwà nínú aginjù náà fún ogójì ọjọ́,+ tí Sátánì ń dẹ ẹ́ wò,+ ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́, ṣùgbọ́n àwọn áńgẹ́lì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.+ 14  Wàyí o, lẹ́yìn tí a ti fi àṣẹ ọba mú Jòhánù, Jésù lọ sí Gálílì,+ ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run,+ 15  ó sì ń wí pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé,+ ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà,+ kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.” 16  Bí ó ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Gálílì, ó rí Símónì+ àti Áńdérù arákùnrin Símónì tí wọ́n ń ju àwọ̀n wọn káàkiri nínú òkun, nítorí wọ́n jẹ́ apẹja.+ 17  Nítorí náà, Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn, èmi yóò sì mú kí ẹ di apẹja ènìyàn.”+ 18  Ní kíá, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀ wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 19  Àti pé lẹ́yìn lílọ síwájú díẹ̀ sí i, ó rí Jákọ́bù ọmọkùnrin Sébédè àti Jòhánù arákùnrin rẹ̀, ní ti tòótọ́, nígbà tí wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi wọn tí wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe;+ 20  ó sì pè wọ́n láìjáfara. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n fi Sébédè baba wọn sílẹ̀ sínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí wọ́n háyà, wọ́n sì tẹ̀ lé e lọ. 21  Wọ́n sì bá ọ̀nà wọn lọ sí Kápánáúmù.+ Gbàrà tí ó ti di sábáàtì ni ó wọ inú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ni. 22  Háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,+ nítorí pé níbẹ̀, ó ń kọ́ wọn bí ẹni tí ó ní ọlá àṣẹ, kì í sì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin.+ 23  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ní àkókò yẹn gan-an nínú sínágọ́gù wọn, ọkùnrin kan wà lábẹ́ agbára ẹ̀mí àìmọ́, ó sì kígbe,+ 24  pé: “Kí ni pa tàwa tìrẹ pọ̀, Jésù ará Násárétì?+ Ṣé ìwọ wá láti pa wá run ni? Mo mọ+ ẹni tí ìwọ jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́+ Ọlọ́run.”+ 25  Ṣùgbọ́n Jésù bá a wí lọ́nà mímúná, pé: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò lára rẹ̀!”+ 26  Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára rẹ̀,+ lẹ́yìn fífi gìrì mú un, tí ó sì ké rara ní bí ohùn rẹ̀ ṣe lè ròkè tó. 27  Tóò, gbogbo ènìyàn náà ni ẹnu yà tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kan láàárín ara wọn, pé: “Kí ni èyí? Ẹ̀kọ́ tuntun ni! Ó ń fi ọlá àṣẹ pa àṣẹ ìtọ́ni fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.”+ 28  Nítorí náà, ìròyìn nípa rẹ̀ tàn kálẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní ìhà gbogbo jákèjádò ìgbèríko tí ń bẹ ní àyíká Gálílì.+ 29  Wọ́n sì jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ kúrò nínú sínágọ́gù, wọ́n sì lọ sí ilé Símónì+ àti Áńdérù pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù. 30  Wàyí o, ìyá ìyàwó Símónì+ ni ibà dá dùbúlẹ̀,+ ní kíá wọ́n sọ fún un nípa rẹ̀. 31  Àti ní lílọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó gbé e dìde, ní dídì í ní ọwọ́ mú; ibà náà sì fi í sílẹ̀,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.+ 32  Lẹ́yìn tí ó di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ti wọ̀, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú gbogbo àwọn tí ń ṣàmódi+ àti àwọn tí ó jẹ́ òǹdè ẹ̀mí èṣù+ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; 33  gbogbo ìlú ńlá náà sì kóra jọ sí ẹnu ilẹ̀kùn gangan. 34  Nítorí náà, ó ṣe ìwòsàn ọ̀pọ̀ àwọn tí onírúurú àìsàn+ ń mú kí wọn ṣàmódi, ó sì lé ọ̀pọ̀ ẹ̀mí èṣù jáde, ṣùgbọ́n kì í jẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù náà sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kristi.+ 35  Ní kùtùkùtù òwúrọ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tíì mọ́, ó sì dìde, ó sì jáde lọ sí ibi tí ó dá,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà níbẹ̀.+ 36  Bí ó ti wù kí ó rí, Símónì àti àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ wá a kàn 37  wọ́n sì rí i, wọ́n sì wí fún un pé: “Gbogbo ènìyàn ń wá ọ.” 38  Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibòmíràn, sí àwọn ìlú abúlé tí ó wà nítòsí, kí èmi lè wàásù+ níbẹ̀ pẹ̀lú, nítorí fún ète yìí ni mo ṣe jáde lọ.”+ 39  Ó sì lọ ní tòótọ́, ó ń wàásù nínú àwọn sínágọ́gù wọn jákèjádò Gálílì, ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.+ 40  Adẹ́tẹ̀ kan pẹ̀lú sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ń pàrọwà fún un àní lórí ìkúnlẹ̀, ó wí fún un pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.”+ 41  Látàrí ìyẹn, àánú ṣe é,+ ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.”+ 42  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀, ó sì mọ́.+ 43  Síwájú sí i, ó fún un ní àṣẹ ìtọ́ni aláìgbagbẹ̀rẹ́, ó sì rán an lọ kíákíá, 44  ó sì wí fún un pé: “Rí i pé ìwọ kò sọ ohun kan fún ẹnikẹ́ni, ṣùgbọ́n lọ fi ara rẹ han àlùfáà,+ àwọn ohun tí Mósè lànà sílẹ̀+ sì ni kí o pèsè fún ìwẹ̀nùmọ́ rẹ, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.”+ 45  Ṣùgbọ́n lẹ́yìn lílọ kúrò, ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí pòkìkí rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ń tan ìròyìn náà káàkiri, tó bẹ́ẹ̀ tí Jésù kò lè wọ ìlú ńlá náà mọ́ ní gbangba, ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ lẹ́yìn òde ní àwọn ibi tí ó dá. Síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá láti ìhà gbogbo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé