Lúùkù 5:1-39

5  Ní àkókò kan nígbà tí ogunlọ́gọ̀ ń ṣù mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, tí wọ́n sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún Jẹ́nẹ́sárẹ́tì.+ 2  Ó sì rí ọkọ̀ ojú omi méjì tí wọ́n gúnlẹ̀ ní ẹ̀gbẹ́ adágún náà, ṣùgbọ́n àwọn apẹja ti jáde kúrò nínú wọn, wọ́n sì ń fọ àwọ̀n wọn.+ 3  Ní wíwọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ ojú omi náà, èyí tí ó jẹ́ ti Símónì, ó sọ fún un pé kí ó wa ọkọ̀ ojú omi náà lọ síwájú díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ogunlọ́gọ̀ láti inú ọkọ̀ ojú omi+ náà. 4  Nígbà tí ó ṣíwọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó sọ fún Símónì pé: “Wa ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó jindò, kí ẹ sì rọ àwọn àwọ̀n yín sísàlẹ̀+ fún àkópọ̀ ẹja.” 5  Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, Símónì wí pé: “Olùkọ́ni, ní gbogbo òru ni àwa ṣe làálàá, a kò sì mú nǹkan kan,+ ṣùgbọ́n nítorí àṣẹ àsọjáde rẹ, ṣe ni èmi yóò rọ àwọn àwọ̀n náà sísàlẹ̀.” 6  Tóò, nígbà tí wọ́n ṣe èyí, wọ́n kó ògìdìgbó ńlá ẹja. Ní ti tòótọ́, àwọn àwọ̀n wọn bẹ̀rẹ̀ sí fà ya sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. 7  Nítorí náà, wọ́n ṣẹ́wọ́ sí àwọn ẹlẹ́gbẹ́ wọn nínú ọkọ̀ ojú omi kejì láti wá ṣèrànwọ́ fún wọn;+ wọ́n sì wá lóòótọ́, wọ́n sì kún ọkọ̀ ojú omi méjèèjì, tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ̀nyí fi bẹ̀rẹ̀ sí rì. 8  Ní rírí èyí, Símónì Pétérù+ wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jésù, ó wí pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Olúwa.”+ 9  Nítorí pé ìyàlẹ́nu bo òun àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní tìtorí àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó, 10  bákan náà sì ni Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọkùnrin Sébédè,+ tí wọ́n jẹ́ alájọpín pẹ̀lú Símónì. Ṣùgbọ́n Jésù wí fún Símónì pé: “Dẹ́kun fífòyà. Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.”+ 11  Nítorí náà, wọ́n dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.+ 12  Ní àkókò kan lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó wà ní ọ̀kan nínú àwọn ìlú ńlá náà, wò ó! ọkùnrin kan tí ó kún fún ẹ̀tẹ̀! Nígbà tí ó tajú kán rí Jésù, ó dojú bolẹ̀, ó sì bẹ̀ ẹ́, ó wí pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.”+ 13  Àti nítorí náà, ní nína ọwọ́ rẹ̀, ó fọwọ́ kàn án, ó wí pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀tẹ̀ náà sì pòórá kúrò lára rẹ̀.+ 14  Ó sì pa àṣẹ ìtọ́ni fún ọkùnrin náà láti má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni:+ “Ṣùgbọ́n lọ, kí o sì fi ara rẹ han àlùfáà,+ kí o sì rú ẹbọ+ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀nùmọ́ rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ṣe lànà sílẹ̀, láti ṣe ẹ̀rí fún wọn.”+ 15  Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ túbọ̀ ń tàn kálẹ̀ sí i, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá a sì máa kóra jọpọ̀ láti fetí sílẹ̀ àti kí a lè wo àìsàn wọn sàn.+ 16  Bí ó ti wù kí ó rí, ó ń bá a lọ ní wíwà ní ipò àdádó ní àwọn aṣálẹ̀, ó sì ń gbàdúrà.+ 17  Ó sì ṣe ní ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ náà, ó ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n jáde wá láti gbogbo àwọn abúlé Gálílì àti Jùdíà àti Jerúsálẹ́mù sì jókòó níbẹ̀; agbára Jèhófà sì wà níbẹ̀ fún un láti ṣe ìmúláradá.+ 18  Sì wò ó! àwọn ọkùnrin tí ń gbé ọkùnrin kan tí ó jẹ́ alárùn ẹ̀gbà lórí ibùsùn, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti gbé e wọlé, kí wọ́n sì gbé e sí iwájú rẹ̀.+ 19  Nítorí náà, nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e wọlé ní tìtorí ogunlọ́gọ̀ náà, wọ́n gun òkè lọ sí òrùlé, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ pẹ̀lú ibùsùn kékeré náà gba àárín àwo ìbolé sí àárín àwọn tí ń bẹ níwájú Jésù.+ 20  Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé: “Ọkùnrin yìí, a dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”+ 21  Nítorí èyí, àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí gbèrò, ní sísọ pé: “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì?+ Ta ní lè dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo?”+ 22  Ṣùgbọ́n Jésù, ní fífi òye mọ èrò wọn, sọ ní dídá wọn lóhùn pé: “Kí ni ẹ ń gbèrò nínú ọkàn-àyà yín?+ 23  Èwo ni ó rọrùn jù, láti sọ pé, ‘A dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti sọ pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn’?+ 24  Ṣùgbọ́n kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ ènìyàn ní ọlá àṣẹ ní ilẹ̀ ayé láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jini—” ó sọ fún ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà náà pé: “Mo wí fún ọ, Dìde, sì gbé ibùsùn kékeré rẹ, kí o sì mú ọ̀nà ilé rẹ pọ̀n.”+ 25  Ní ìṣẹ́jú akàn, ó dìde níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó ti máa ń dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó ń yin Ọlọ́run lógo.+ 26  Nígbà náà ni ayọ̀ púpọ̀ jọjọ+ kún inú gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí yin Ọlọ́run lógo, wọ́n sì kún fún ìbẹ̀rù, wọ́n wí pé: “Àwa ti rí ohun àjèjì lónìí!”+ 27  Wàyí o, lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ó jáde lọ, ó sì rí agbowó orí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Léfì tí ó jókòó ní ọ́fíìsì owó orí, ó sì wí fún un pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.”+ 28  Ó fi ohun gbogbo+ sílẹ̀ sẹ́yìn, ó dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé e. 29  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Léfì se àsè ìṣenilálejò rẹpẹtẹ fún un ní ilé rẹ̀; ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn agbowó orí sì wà níbẹ̀ àti àwọn mìíràn tí wọ́n wà pẹ̀lú wọn ní rírọ̀gbọ̀kú nídìí oúnjẹ.+ 30  Látàrí èyí, àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé òfin wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pé: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé ẹ ń jẹ, ẹ sì ń mu pẹ̀lú àwọn agbowó orí àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀?”+ 31  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí fún wọn pé: “Àwọn tí ó lera kò nílò oníṣègùn,+ ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣòjòjò nílò rẹ̀.+ 32  Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.”+ 33  Wọ́n wí fún un pé: “Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù a máa gbààwẹ̀ lemọ́lemọ́, wọn a sì máa ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ti àwọn Farisí máa ń ṣe, ṣùgbọ́n àwọn tìrẹ ń jẹ, wọ́n sì ń mu.”+ 34  Jésù wí fún wọn pé: “Ẹ kò lè mú kí àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ̀lú wọn, ẹ lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí?+ 35  Síbẹ̀, àwọn ọjọ́ yóò dé nígbà tí a óò mú ọkọ ìyàwó+ lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn+ ní tòótọ́; nígbà náà, wọn yóò gbààwẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì.”+ 36  Síwájú sí i, ó ń bá a lọ láti fún wọn ní àpèjúwe kan pé: “Kò sí ẹni tí í gé ìrépé lára ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí í sì í rán an sórí ògbólógbòó ẹ̀wù àwọ̀lékè; ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà ìrépé tuntun yóò ya kúrò àti pé ìrépé náà láti ara ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun kò ní bá ògbólógbòó mu.+ 37  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí ẹni tí í fi wáìnì tuntun sínú àwọn ògbólógbòó àpò awọ; ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà wáìnì tuntun yóò bẹ́ àwọn àpò awọ+ náà, yóò sì dà sílẹ̀, àwọn àpò awọ náà yóò sì bàjẹ́.+ 38  Ṣùgbọ́n wáìnì tuntun ni a gbọ́dọ̀ fi sínú àwọn àpò awọ tuntun. 39  Kò sí ẹni tí ó ti mu ògbólógbòó wáìnì tí í fẹ́ tuntun; nítorí òun a sọ pé, ‘Ògbólógbòó+ gbámúṣé.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé