Lúùkù 22:1-71
22 Wàyí o, àjọyọ̀ àkàrà aláìwú, tí àwọn ènìyàn ń pè ní Ìrékọjá,+ ti ń sún mọ́lé.
2 Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin ń wá ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ fún wọn láti rẹ́yìn rẹ̀,+ nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.+
3 Ṣùgbọ́n Sátánì wọ inú Júdásì, ẹni tí a ń pè ní Ísíkáríótù, tí a kà mọ́ àwọn méjìlá náà;+
4 ó sì lọ bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ láti fi í lé wọn lọ́wọ́.+
5 Tóò, wọ́n yọ̀, wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fún un ní owó fàdákà.+
6 Nítorí náà, ó gbà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wá àyè ṣíṣí sílẹ̀ tí ó dára láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ogunlọ́gọ̀ nítòsí.+
7 Ọjọ́ àkàrà aláìwú dé wàyí, nínú èyí tí a gbọ́dọ̀ fi ẹran-ẹbọ ìrékọjá rúbọ;+
8 ó sì rán Pétérù àti Jòhánù lọ, wí pé: “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá sílẹ̀+ fún wa láti jẹ.”
9 Wọ́n wí fún un pé: “Ibo ni o fẹ́ kí a pèsè rẹ̀ sílẹ̀ sí?”
10 Ó wí fún wọn pé:+ “Wò ó! Nígbà tí ẹ bá wọ ìlú ńlá náà, ọkùnrin kan tí ó ru ládugbó omi yóò pàdé yín. Ẹ tẹ̀ lé e lọ sínú ilé tí ó bá wọ̀.+
11 Ẹ sì gbọ́dọ̀ sọ fún ẹni tí ó ni ilé náà pé, ‘Olùkọ́ sọ fún ọ pé: “Ibo ni yàrá àlejò wà, nínú èyí tí mo ti lè jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi?”’+
12 Ọkùnrin yẹn yóò sì fi yàrá ńlá kan ní òkè hàn yín, tí a ti pèsè àwọn ohun èlò ilé sí. Ẹ pèsè rẹ̀ sílẹ̀ níbẹ̀.”+
13 Nítorí náà, wọ́n lọ, wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn gẹ́lẹ́, wọ́n sì pèsè ìrékọjá náà sílẹ̀.+
14 Níkẹyìn, nígbà tí wákàtí náà dé, ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì, àti àwọn àpọ́sítélì pẹ̀lú rẹ̀.+
15 Ó sì wí fún wọn pé: “Mo ti ní ìfẹ́-ọkàn gidigidi láti jẹ ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà;
16 nítorí mo sọ fún yín, Dájúdájú, èmi kì yóò tún jẹ ẹ́ mọ́ títí a ó fi mú un ṣẹ nínú ìjọba Ọlọ́run.”+
17 Bí ó sì ti tẹ́wọ́ gba ife kan,+ ó dúpẹ́, ó sì wí pé: “Ẹ gba èyí, kí ẹ sì gbé e láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí èkejì láàárín ara yín;
18 nítorí mo sọ fún yín, Láti ìsinsìnyí lọ, dájúdájú, èmi kì yóò tún mu láti inú àmújáde àjàrà mọ́ títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”+
19 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ìṣù búrẹ́dì+ kan, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ara mi+ tí a ó fi fúnni nítorí yín.+ Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”+
20 Àti ife+ pẹ̀lú, lọ́nà kan náà lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ oúnjẹ alẹ́, ó wí pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun+ nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi,+ tí a óò tú jáde nítorí yín.+
21 “Ṣùgbọ́n, wò ó! ọwọ́ afinihàn+ mi wà pẹ̀lú mi nídìí tábìlì.+
22 Nítorí pé Ọmọ ènìyàn ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a là sílẹ̀;+ síbẹ̀ náà, ègbé ni fún ọkùnrin yẹn tí a tipasẹ̀ rẹ̀ fi í léni lọ́wọ́!”+
23 Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jíròrò láàárín ara wọn ìbéèrè nípa èwo nínú wọn ni yóò jẹ́ ẹni náà ní ti tòótọ́ tí ó fẹ́ ṣe èyí.+
24 Bí ó ti wù kí ó rí, awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.+
25 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn tí wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí wọn ni a ń pè ní àwọn Olóore.+
26 Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀.+ Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín dà bí ẹni tí ó kéré jù lọ,+ kí ẹni tí ó sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olórí dà bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.+
27 Nítorí ta ni ẹni tí ó tóbi jù, ṣé ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni tàbí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́? Kì í ha ṣe ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni? Ṣùgbọ́n èmi wà láàárín yín gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.+
28 “Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá+ nínú àwọn àdánwò mi;+
29 èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan,+ fún ìjọba kan,+
30 kí ẹ lè máa jẹ,+ kí ẹ sì máa mu nídìí tábìlì mi nínú ìjọba mi,+ kí ẹ sì jókòó lórí ìtẹ́+ láti ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.
31 “Símónì, Símónì, wò ó! Sátánì+ ti fi dandan béèrè láti gbà yín, kí ó lè kù yín bí àlìkámà.+
32 Ṣùgbọ́n èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀+ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀; àti ìwọ, ní gbàrà tí o bá ti padà, fún àwọn arákùnrin rẹ lókun.”+
33 Nígbà náà ni ó wí fún un pé: “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sẹ́wọ̀n àti sínú ikú.”+
34 Ṣùgbọ́n ó wí pé: “Mo sọ fún ọ, Pétérù, Àkùkọ kì yóò kọ lónìí títí ìwọ yóò fi sẹ́ ní ìgbà mẹ́ta pé ìwọ kò mọ̀ mí.”+
35 Ó tún wí fún wọn pé: “Nígbà tí mo rán+ yín jáde láìsí àpò àti àsùnwọ̀n oúnjẹ àti sálúbàtà, ẹ kò ṣe aláìní ohunkóhun, àbí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀?” Wọ́n wí pé: “Rárá!”
36 Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé: “Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, kí ẹni tí ó ní àpò gbé e, bákan náà pẹ̀lú ni àsùnwọ̀n oúnjẹ; kí ẹni tí kò sì ní idà ta ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀, kí ó sì ra ọ̀kan.
37 Nítorí mo sọ fún yín pé èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ ṣe parí nínú mi, èyíinì ni, ‘A sì kà á mọ́ àwọn aláìlófin.’+ Nítorí èyíinì tí ó kàn mí ń ní àṣeparí.”+
38 Nígbà náà ni wọ́n wí pé: “Olúwa, wò ó! idà méjì nìyí.” Ó wí fún wọn pé: “Ó ti tó.”
39 Nígbà tí ó jáde, ó lọ sí Òkè Ńlá Olífì gẹ́gẹ́ bí àṣà rẹ̀; àwọn ọmọ ẹ̀yìn pẹ̀lú sì tẹ̀ lé e.+
40 Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó wí fún wọn pé: “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.”+
41 Òun fúnra rẹ̀ sì lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn ní nǹkan bí ìwọ̀n ìsọ̀kò kan, ó sì tẹ eékún rẹ̀ ba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà,
42 pé: “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, mú ife yìí kúrò lórí mi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìfẹ́ mi+ ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”+
43 Nígbà náà ni áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.+
44 Ṣùgbọ́n bí ó ti wà nínú ìroragógó, ó ń bá a lọ ní títúbọ̀ fi taratara gbàdúrà;+ òógùn rẹ̀ sì wá dà bí ẹ̀kán ẹ̀jẹ̀ tí ń já bọ́ sí ilẹ̀.+
45 Ó sì dìde lórí àdúrà, ó lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì bá wọn tí wọ́n ń tòògbé nítorí ẹ̀dùn-ọkàn;+
46 ó sì wí fún wọn pé: “Èé ṣe tí ẹ ń sùn? Ẹ dìde, kí ẹ sì máa gbàdúrà, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.”+
47 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, wò ó! ogunlọ́gọ̀ kan, àti ọkùnrin tí a ń pè ní Júdásì, ọ̀kan lára àwọn méjìlá, ń lọ níwájú wọn;+ ó sì sún mọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó lẹ́nu.+
48 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún un pé: “Júdásì, ìwọ ha fi ìfẹnukonu da Ọmọ ènìyàn?”+
49 Nígbà tí àwọn tí wọ́n yí i ká rí ohun tí ó fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n wí pé: “Olúwa, ṣé kí a máa fi idà jà lọ?”+
50 Ẹnì kan nínú wọ́n tilẹ̀ ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ ọ̀tún dànù.+
51 Ṣùgbọ́n ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: “Ẹ fi mọ sí ibí yìí.” Ó sì fọwọ́ kan etí náà, ó sì mú un lára dá.+
52 Nígbà náà, Jésù wí fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n tìtorí rẹ̀ wá síbẹ̀ pé: “Ẹ ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀gọ bí ẹní wá bá ọlọ́ṣà?+
53 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nínú tẹ́ńpìlì+ láti ọjọ́ dé ọjọ́, ẹ kò na ọwọ́ yín lòdì sí mi.+ Ṣùgbọ́n wákàtí yín+ àti ọlá àṣẹ+ òkùnkùn+ nìyí.”
54 Nígbà náà ni wọ́n fi àṣẹ ọba mú un, wọ́n sì mú un lọ,+ wọ́n sì mú un wá sínú ilé àlùfáà àgbà;+ ṣùgbọ́n Pétérù ń tẹ̀ lé wọn ní òkèèrè.+
55 Nígbà tí wọ́n dá iná kan ní àárín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pa pọ̀, Pétérù jókòó ní àárín wọn.+
56 Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́bìnrin kan rí i tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ iná mímọ́lẹ̀ yòò náà, ó sì wò ó délẹ̀, ó sì wí pé: “[Ọkùnrin] yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”+
57 Ṣùgbọ́n ó sẹ́,+ pé: “Èmi kò mọ̀ ọ́n, obìnrin yìí.”+
58 Lẹ́yìn àkókò kúkúrú kan, ẹlòmíràn tí ó rí i sọ pé: “Ìwọ pẹ̀lú jẹ́ ọ̀kan lára wọn.” Ṣùgbọ́n Pétérù sọ pé: “Èmi kọ́, ọkùnrin yìí.”+
59 Lẹ́yìn ìgbà tí nǹkan bí wákàtí kan ti là á láàárín, ọkùnrin mìíràn kan bẹ̀rẹ̀ sí tẹpẹlẹ mọ́ ọn kíkankíkan pé: “Dájúdájú, ọkùnrin yìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀; nítorí, ní ti tòótọ́, ará Gálílì ni!”+
60 Ṣùgbọ́n Pétérù sọ pé: “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń sọ.” Ní ìṣẹ́jú akàn, nígbà tí ó ṣì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àkùkọ sì kọ.+
61 Olúwa sì yí padà, ó sì bojú wo Pétérù, Pétérù sì rántí àsọjáde Olúwa nígbà tí ó sọ fún un pé: “Kí àkùkọ tó kọ lónìí, ìwọ yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú mi ní ìgbà mẹ́ta.”+
62 Ó sì bọ́ sóde, ó sì sunkún kíkorò.+
63 Wàyí o, àwọn ọkùnrin tí wọ́n fi í sínú ìhámọ́ bẹ̀rẹ̀ sí fi í ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n ń gbá+ a;+
64 lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti fi nǹkan bò ó, wọn yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Sọ tẹ́lẹ̀. Ta ni ó gbá ọ?”+
65 Wọ́n sì tẹ̀ síwájú ní sísọ ọ̀pọ̀ ohun mìíràn ní ìsọ̀rọ̀ òdì+ sí i.
66 Níkẹyìn, nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àjọ àwọn àgbààgbà ọkùnrin àwọn ènìyàn náà, àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kóra jọpọ̀,+ wọ́n sì fà á lọ sínú gbọ̀ngàn Sànhẹ́dírìn wọn, wọ́n wí pé:+
67 “Bí ó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi+ náà, sọ fún wa.” Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: “Bí mo bá tilẹ̀ sọ fún yín, ẹ kò ní gbà á gbọ́ rárá.+
68 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí mo bá bi yín ní ìbéèrè, ẹ kì yóò dáhùn rárá.+
69 Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìsinsìnyí lọ, Ọmọ ènìyàn+ yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún lílágbára+ Ọlọ́run.”+
70 Látàrí èyí, gbogbo wọ́n wí pé: “Ṣé ìwọ wá ni Ọmọ Ọlọ́run?” Ó wí fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ń sọ+ pé èmi ni.”
71 Wọ́n wí pé: “Èé ṣe tí a fi nílò ẹ̀rí síwájú sí i?+ Nítorí àwa fúnra wa tí gbọ́ ọ láti ẹnu òun fúnra rẹ̀.”+

