Lúùkù 17:1-37

17  Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ó jẹ́ ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ pé àwọn okùnfà ìkọ̀sẹ̀ ní láti wá.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ègbé ni fún ẹni tí wọ́n tipasẹ̀ rẹ̀ wá!+ 2  Àǹfààní púpọ̀ ni ì bá jẹ́ fún un bí a bá so ọlọ rọ̀ sí ọrùn rẹ̀, tí a sì sọ ọ́ sínú òkun+ ju pé kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀.+ 3  Ẹ fiyè sí ara yín. Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, fún un ní ìbáwí mímúná,+ bí ó bá sì ronú pìwà dà, dárí jì í.+ 4  Kódà, bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ìgbà méje lóòjọ́, tí ó sì padà wá bá ọ ní ìgbà méje, tí ó wí pé, ‘Mo ronú pìwà dà,’ ìwọ gbọ́dọ̀ dárí jì í.”+ 5  Wàyí o, àwọn àpọ́sítélì sọ fún Olúwa pé: “Fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i.”+ 6  Nígbà náà ni Olúwa sọ pé: “Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, ẹ óò wí fún igi mọ́líbẹ́rì dúdú yìí pé, ‘Hú tegbòtegbò, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun!’ yóò sì ṣègbọ́ràn sí yín.+ 7  “Ta ni ó wà nínú yín tí ó ní ẹrú kan tí ń túlẹ̀ tàbí tí ń tọ́jú agbo ẹran, tí yóò sọ fún un nígbà tí ó bá wọlé láti inú pápá pé, ‘Wá níhìn-ín ní kíá, kí o sì rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì’? 8  Kàkà bẹ́ẹ̀, òun kì yóò ha sọ fún un pé, ‘Pèsè ohun kan sílẹ̀ fún mi láti fi ṣe oúnjẹ alẹ́ mi, sì gbé épírọ́ọ̀nù kan wọ̀, kí o sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi títí èmi yóò fi parí jíjẹ àti mímu, àti lẹ́yìn náà ìwọ lè jẹ, kí o sì mu’? 9  Kì yóò fi ìmoore hàn fún ẹrú náà nítorí pé ó ṣe àwọn ohun tí a yàn lé e lọ́wọ́, àbí yóò ṣe bẹ́ẹ̀? 10  Bákan náà ni ẹ̀yin, pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe gbogbo ohun tí a yàn lé yín lọ́wọ́ tán, ẹ wí pé, ‘Àwa jẹ́ ẹrú tí kò dára fún ohunkóhun.+ Ohun tí ó yẹ kí a ṣe ni a ṣe.’” 11  Nígbà tí ó sì ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, ó ń la àárín Samáríà àti Gálílì+ kọjá. 12  Bí ó sì ti ń wọ abúlé kan, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá+ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n dúró lókèèrè réré. 13  Wọ́n sì gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì wí pé: “Jésù, Olùkọ́ni, ṣàánú+ fún wa!” 14  Nígbà tí ó sì tajú kán rí wọn, ó wí fún wọn pé: “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.”+ Lẹ́yìn náà, bí wọ́n ṣe ń lọ, ìwẹ̀nùmọ́ wọ́n ṣẹlẹ̀.+ 15  Ọ̀kan nínú wọn, nígbà tí ó rí i pé a ti mú òun lára dá, ó padà, ó ń fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.+ 16  Ó sì dojú bolẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jésù,+ ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; síwájú sí i, ó jẹ́ ará Samáríà.+ 17  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ni a wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn mẹ́sàn-án yòókù wá dà? 18  Ṣé a kò rí kí ẹnì kankan padà láti fi ògo fún Ọlọ́run bí kò ṣe [ọkùnrin] yìí tí ó jẹ́ ará orílẹ̀-èdè mìíràn?” 19  Ó sì wí fún un pé: “Dìde, kí o sì mú ọ̀nà rẹ pọ̀n; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ 20  Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisí béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ìgbà tí ìjọba Ọlọ́run ń bọ̀,+ ó dá wọn lóhùn, ó sì wí pé: “Ìjọba Ọlọ́run kì yóò wá pẹ̀lú ṣíṣeérí tí ń pàfiyèsí, 21  bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kì yóò máa wí pé, ‘Wò ó níhìn-ín!’ tàbí, ‘Lọ́hùn-ún!’+ Nítorí pé, wò ó! ìjọba Ọlọ́run wà ní àárín yín.”+ 22  Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé: “Àwọn ọjọ́ yóò dé nígbà tí ẹ óò ní ìfẹ́-ọkàn láti rí ọ̀kan nínú àwọn ọjọ́ Ọmọ ènìyàn, ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí i.+ 23  Àwọn ènìyàn yóò sì wí fún yín pé, ‘Wò ó lọ́hùn-ún!’ tàbí, ‘Wò ó níhìn-ín!’+ Ẹ má ṣe jáde lọ tàbí sáré tẹ̀ lé wọn.+ 24  Nítorí àní gẹ́gẹ́ bí mànàmáná,+ nípa ìkọmànà rẹ̀, ṣe ń tàn láti apá kan lábẹ́ ọ̀run lọ sí apá ibòmíràn lábẹ́ ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ ènìyàn+ yóò rí. 25  Lákọ̀ọ́kọ́, bí ó ti wù kí ó rí, ó gbọ́dọ̀ fara gba ọ̀pọ̀ ìjìyà, kí a sì kọ̀ ọ́ tì láti ọwọ́ ìran yìí.+ 26  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Nóà,+ bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí pẹ̀lú ní àwọn ọjọ́ Ọmọ ènìyàn:+ 27  wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì, ìkún omi sì dé, ó sì pa gbogbo wọn run.+ 28  Bákan náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Lọ́ọ̀tì:+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé. 29  Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Sódómù, òjò iná àti imí-ọjọ́ rọ̀ láti ọ̀run, ó sì pa gbogbo wọn run.+ 30  Bákan náà ni yóò rí ní ọjọ́ tí a óò ṣí Ọmọ ènìyàn payá.+ 31  “Ní ọjọ́ yẹn, kí ẹni tí ó wà ní orí ilé ṣùgbọ́n tí àwọn nǹkan rẹ̀ tí ó ṣeé gbé wà nínú ilé má ṣe sọ̀ kalẹ̀ lọ kó ìwọ̀nyí, ẹni tí ó bá sì wà níta nínú pápá, kí òun náà má ṣe padà sí àwọn nǹkan tí ń bẹ lẹ́yìn. 32  Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.+ 33  Ẹnì yòówù tí ó bá ń wá ọ̀nà láti pa ọkàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ewu fún ara rẹ̀ yóò pàdánù rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹnì yòówù tí ó bá pàdánù rẹ̀ yóò pa á mọ́ láàyè.+ 34  Mo sọ fún yín, Ní òru yẹn, ọkùnrin méjì yóò wà lórí ibùsùn kan; a óò mú ọ̀kan lọ, ṣùgbọ́n èkejì ni a ó pa tì.+ 35  Obìnrin méjì yóò máa lọ nǹkan lórí ọlọ kan náà; a óò mú ọ̀kan lọ, ṣùgbọ́n èkejì ni a ó pa tì.”+ 36  —— 37  Nítorí náà, ní ìdáhùnpadà, wọ́n wí fún un pé: “Ibo ni, Olúwa?” Ó wí fún wọn pé: “Ibi tí òkú bá wà,+ ibẹ̀ ni àwọn idì yóò kóra jọpọ̀ sí pẹ̀lú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé