Lúùkù 10:1-42

10  Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Olúwa yan àwọn àádọ́rin+ mìíràn sọ́tọ̀, ó sì rán wọn jáde ní méjìméjì+ ṣáájú rẹ̀ sínú gbogbo ìlú ńlá àti ibi tí òun fúnra rẹ̀ yóò dé. 2  Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn pé: “Ìkórè+ pọ̀, ní tòótọ́, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́+ kére níye. Nítorí náà, ẹ bẹ+ Ọ̀gá ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́+ jáde sínú ìkórè rẹ̀. 3  Ẹ jáde lọ. Wò ó! Èmi ń rán yín jáde gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn+ sí àárín àwọn ìkookò. 4  Ẹ má ṣe gbé àpò, tàbí àsùnwọ̀n oúnjẹ,+ tàbí sálúbàtà, kí ẹ má sì ṣe gbá ẹnikẹ́ni mọ́ra+ nínú ìkíni ní ojú ọ̀nà. 5  Ibì yòówù tí ẹ bá ti wọ ilé kan, ẹ kọ́kọ́ sọ pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’+ 6  Bí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e.+ Ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò padà sọ́dọ̀ yín.+ 7  Nítorí náà, ẹ dúró nínú ilé yẹn,+ kí ẹ máa jẹ, kí ẹ sì máa mu ohun tí wọ́n bá pèsè,+ nítorí òṣìṣẹ́ yẹ fún owó ọ̀yà+ rẹ̀. Ẹ má ṣe máa ṣí láti ilé dé ilé.+ 8  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ibì yòówù tí ẹ bá ti wọ ìlú ńlá kan, tí wọ́n sì gbà yín, ẹ jẹ ohun tí a bá gbé ka iwájú yín, 9  ẹ sì wo àwọn aláìsàn tí ń bẹ nínú rẹ̀ sàn,+ kí ẹ sì máa bá a lọ ní sísọ fún wọn pé, ‘Ìjọba+ Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí yín.’ 10  Ṣùgbọ́n ibì yòówù tí ẹ bá ti wọ ìlú ńlá kan, tí wọn kò sì gbà+ yín, ẹ jáde lọ sí àwọn ọ̀nà rẹ̀ fífẹ̀, kí ẹ sì wí pé, 11  ‘Kódà, ekuru tí ó lẹ̀ mọ́ ẹsẹ̀ wa láti inú ìlú ńlá yín ni àwa nù kúrò lòdì sí yín.+ Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi èyí sọ́kàn, pé ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́ tòsí.’ 12  Mo sọ fún yín pé yóò ṣeé fara dà fún Sódómù+ ní ọjọ́ yẹn jù fún ìlú ńlá náà lọ. 13  “Ègbé ni fún ọ, Kórásínì!+ Ègbé ni fún ọ, Bẹtisáídà!+ nítorí pé bí àwọn iṣẹ́ agbára tí ó ti ṣẹlẹ̀ nínú yín bá ti ṣẹlẹ̀ ní Tírè àti Sídónì, tipẹ́tipẹ́ ni wọn ì bá ti ronú pìwà dà ní jíjókòó nínú aṣọ àpò ìdọ̀họ àti eérú.+ 14  Nítorí náà, yóò ṣeé fara dà fún Tírè àti Sídónì ní ìdájọ́ jù fún yín lọ.+ 15  Àti ìwọ, Kápánáúmù, ó ha lè jẹ́ pé a óò gbé ọ ga dé ọ̀run?+ Hédíìsì+ nísàlẹ̀ ni ìwọ yóò wá! 16  “Ẹni tí ó bá fetí sí+ yín, fetí sí mi pẹ̀lú. Ẹni tí ó bá sì ṣàìkà yín sí, ṣàìkà mí sí pẹ̀lú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹni tí ó bá ṣàìkà mí sí, ṣàìka ẹni tí ó rán mi jáde sí+ pẹ̀lú.” 17  Lẹ́yìn náà, àwọn àádọ́rin náà padà dé pẹ̀lú ìdùnnú, wọ́n wí pé: “Olúwa, àwọn ẹ̀mí èṣù pàápàá ni a mú tẹrí ba+ fún wa nípasẹ̀ lílo orúkọ rẹ.” 18  Látàrí èyíinì, ó wí fún wọn pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí rí Sátánì tí ó ti já bọ́+ ná bí mànàmáná láti ọ̀run. 19  Wò ó! Mo ti fún yín ní ọlá àṣẹ láti tẹ àwọn ejò+ àti àkekèé+ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀, àti lórí gbogbo agbára ọ̀tá,+ kò sì sí nǹkan kan tí yóò ṣe yín lọ́ṣẹ́ lọ́nàkọnà. 20  Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ má ṣe yọ̀ lórí èyí, pé a mú àwọn ẹ̀mí tẹrí ba fún yín, ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ nítorí pé a ti ṣàkọọ́lẹ̀ orúkọ yín+ ní ọ̀run.” 21  Ní wákàtí yẹn gan-an, ó wá ní ayọ̀ púpọ̀+ nínú ẹ̀mí mímọ́, ó sì wí pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n+ àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó. Bẹ́ẹ̀ ni, Ìwọ Baba, nítorí pé láti ṣe bẹ́ẹ̀ wá di ọ̀nà tí ìwọ tẹ́wọ́ gbà. 22  Ohun gbogbo ni Baba mi ti fi lé mi lọ́wọ́,+ kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́ bí kò ṣe Baba;+ ẹni tí Baba sì jẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe Ọmọ,+ àti ẹni tí Ọmọ bá fẹ́ láti ṣí i payá fún.” 23  Pẹ̀lú èyíinì, ó yíjú sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ní àwọn nìkan, ó sì wí pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ojú tí ó rí àwọn ohun tí ẹ ń rí.+ 24  Nítorí mo wí fún yín, Ọ̀pọ̀ wòlíì àti àwọn ọba ní ìfẹ́-ọkàn láti rí+ àwọn ohun tí ẹ ń rí ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn, àti láti gbọ́ àwọn ohun tí ẹ ń gbọ́ ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́ wọn.” 25  Wàyí o, wò ó! ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin+ dìde dúró, láti dán an wò, ó sì wí pé: “Olùkọ́, nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 26  Ó wí fún un pé: “Kí ni a kọ sínú Òfin?+ Báwo ni ìwọ ṣe kà á?” 27  Ní ìdáhùn, ó wí pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ,’+ ati, ‘aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”+ 28  Ó wí fún un pé: “Ìdáhùn rẹ tọ́; ‘máa bá a nìṣó ní ṣíṣe èyí, ìwọ yóò sì rí ìyè.’”+ 29  Ṣùgbọ́n, ní fífẹ́ láti fi ara rẹ̀ hàn ní olódodo, ọkùnrin náà sọ fún Jésù pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?”+ 30  Ní ìfèsìpadà, Jésù wí pé: “Ọkùnrin kan ń sọ̀ kalẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Jẹ́ríkò, ó sì bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà, àwọn tí wọ́n bọ́ ọ láṣọ, tí wọ́n sì lù ú, wọ́n sì lọ, ní fífi í sílẹ̀ láìkú tán. 31  Wàyí o, ní ìṣekòńgẹ́, àlùfáà kan ń sọ̀ kalẹ̀ lọ ní ojú ọ̀nà yẹn, ṣùgbọ́n, nígbà tí ó rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ.+ 32  Bákan náà, ọmọ Léfì kan pẹ̀lú, nígbà tí ó sọ̀ kalẹ̀ dé ibẹ̀, tí ó sì rí i, ó gba ẹ̀gbẹ́ òdì-kejì kọjá lọ.+ 33  Ṣùgbọ́n ará Samáríà+ kan tí ó ń rin ìrìn àjò gba ojú ọ̀nà náà ṣàdédé bá a pàdé, bí ó sì ti rí i, àánú ṣe é. 34  Nítorí náà, ó sún mọ́ ọn, ó sì di àwọn ọgbẹ́ rẹ̀, ó da òróró àti wáìnì sórí wọn.+ Lẹ́yìn náà, ó gbé e gun orí ẹranko tirẹ̀, ó sì gbé e wá sí ilé èrò kan, ó sì tọ́jú rẹ̀. 35  Ó sì mú owó dínárì méjì jáde ní ọjọ́ kejì, ó fi fún olùtọ́jú ilé èrò náà, ó sì wí pé, ‘Tọ́jú rẹ̀, ohun yòówù tí ìwọ bá sì ná ní àfikún sí èyí, èmi yóò san án padà fún ọ nígbà tí mo bá padà wá síhìn-ín.’ 36  Lójú tìrẹ, ta ni nínú àwọn mẹ́ta wọ̀nyí ni ó ṣe ara rẹ̀ ní aládùúgbò+ fún ọkùnrin tí ó bọ́ sí àárín àwọn ọlọ́ṣà?” 37  Ó wí pé: “Ẹni tí ó hùwà sí i tàánú-tàánú.”+ Nígbà náà ni Jésù wí fún un pé: “Máa bá ọ̀nà rẹ lọ, kí ìwọ alára sì máa ṣe+ bákan náà.” 38  Wàyí o, bí wọ́n tí ń bá ọ̀nà wọn lọ, ó wọ abúlé kan. Níhìn-ín, obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Màtá+ gbà á lálejò sínú ilé náà. 39  Obìnrin yìí tún ní arábìnrin kan tí a ń pè ní Màríà, ẹni tí, bí ó ti wù kí ó rí, ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀+ Olúwa, tí ó sì ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. 40  Màtá, ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ní ìpínyà-ọkàn+ nítorí bíbójútó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúṣe. Nítorí náà, ó wá sí tòsí, ó sì wí pé: “Olúwa, kò ha jámọ́ nǹkan kan fún ọ pé arábìnrin mi ti fi èmi nìkan sílẹ̀ láti bójútó àwọn nǹkan?+ Sọ fún un, nígbà náà, kí ó dara pọ̀ ní ríràn mí lọ́wọ́.” 41  Ní ìdáhùn, Olúwa wí fún un pé: “Màtá, Màtá, ìwọ ń ṣàníyàn,+ o sì ń ṣèyọnu nípa ohun púpọ̀.+ 42  Bí ó ti wù kí ó rí, nǹkan díẹ̀+ tàbí ẹyọ kan ṣoṣo ni a nílò. Ní tirẹ̀, Màríà yan ìpín rere,+ a kì yóò sì gbà á kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé