Léfítíkù 9:1-24

9  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ+ pé, Mósè pe Áárónì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti àwọn àgbà ọkùnrin Ísírẹ́lì.  Ó sì wí fún Áárónì pé: “Mú ọmọ màlúù kan fún ara rẹ fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ àti àgbò kan fún ọrẹ ẹbọ sísun,+ àwọn tí ara wọ́n dá ṣáṣá, kí o sì mú wọn wá síwájú Jèhófà.+  Ṣùgbọ́n kí o sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Ẹ mú akọ ewúrẹ́+ kan fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọmọ màlúù kan àti ẹgbọrọ àgbò+ kan, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọlọ́dún kan, àwọn tí ara wọ́n dá ṣáṣá, fún ọrẹ ẹbọ sísun,  àti akọ màlúù kan àti àgbò kan fún ẹbọ ìdàpọ̀+ láti fi wọ́n rúbọ níwájú Jèhófà, àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ tí a fi òróró rin fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, nítorí pé òní ni Jèhófà yóò fara hàn yín dájúdájú.’”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, wọ́n mú ohun tí Mósè pa láṣẹ wá síwájú àgọ́ ìpàdé. Nígbà náà ni gbogbo àpéjọ náà sún mọ́ tòsí, wọ́n sì dúró níwájú Jèhófà.+  Mósè sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà pàṣẹ pé kí ẹ ṣe, kí ògo Jèhófà lè fara hàn yín.”+  Nígbà náà ni Mósè wí fún Áárónì pé: “Sún mọ́ pẹpẹ, kí o sì rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ rẹ àti ọrẹ ẹbọ sísun rẹ, kí o sì ṣe ètùtù+ nítorí ara rẹ àti nítorí ilé rẹ; kí o sì rú ọrẹ ẹbọ àwọn ènìyàn náà,+ kí o sì ṣe ètùtù+ nítorí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pa á láṣẹ.”  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áárónì sún mọ́ pẹpẹ, ó sì pa ọmọ màlúù ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọkùnrin Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀+ náà wá fún un, ó sì tẹ ìka rẹ̀ bọ ẹ̀jẹ̀+ náà, ó sì fi sára àwọn ìwo pẹpẹ,+ ó sì da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìhà ìsàlẹ̀ pẹpẹ. 10  Ó sì mú ọ̀rá+ àti àwọn kíndìnrín àti àmọ́ ara ẹ̀dọ̀ láti inú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè. 11  Ó sì fi iná sun ẹran àti awọ náà ní òde ibùdó.+ 12  Lẹ́yìn náà, ó pa ọrẹ ẹbọ sísun, àwọn ọmọkùnrin Áárónì sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lé e lọ́wọ́, ó sì wọ́n ọn sórí pẹpẹ yíká-yíká.+ 13  Wọ́n sì kó àwọn ègé àti orí ọrẹ ẹbọ sísun náà lé e lọ́wọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 14  Síwájú sí i, ó fọ ìfun àti tete, ó sì mú wọn rú èéfín lórí ọrẹ ẹbọ sísun tí ó wà lórí pẹpẹ.+ 15  Wàyí o, ó mú ọrẹ ẹbọ àwọn ènìyàn náà wá, ó sì mú ewúrẹ́ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn+ náà, ó sì pa á, ó sì fi í rú ọrẹ ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ bí ti àkọ́kọ́. 16  Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ ẹbọ sísun wá, ó sì ṣe é ní ọ̀nà tí a ń gbà ṣe é.+ 17  Lẹ́yìn náà, ó mú ọrẹ ẹbọ ọkà+ wá, ó sì fi lára rẹ̀ kún ọwọ́ rẹ̀, ó sì mú un rú èéfín lórí pẹpẹ, yàtọ̀ sí ọrẹ ẹbọ sísun ti òwúrọ̀.+ 18  Lẹ́yìn ìyẹn, ó pa akọ màlúù àti àgbò ẹbọ ìdàpọ̀+ tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn náà. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọkùnrin Áárónì gbé ẹ̀jẹ̀ náà lé e lọ́wọ́, ó sì wọ́n ọn sórí pẹpẹ yíká-yíká.+ 19  Ní ti ọ̀rá+ ara akọ màlúù náà àti ìrù ọlọ́ràá+ ti àgbò náà àti ọ̀rá àti àwọn kíndìnrín àti àmọ́ ara ẹ̀dọ̀, 20  nísinsìnyí, wọ́n fi ọ̀rá sórí igẹ̀,+ lẹ́yìn náà, ó mú ọ̀rá náà rú èéfín lórí pẹpẹ. 21  Ṣùgbọ́n igẹ̀ àti ẹsẹ̀ ọ̀tún ni Áárónì fì síwá-sẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ fífì+ níwájú Jèhófà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Mósè ti pa á láṣẹ. 22  Nígbà náà ni Áárónì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè síhà ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn náà, ó sì súre fún wọn,+ ó sì sọ̀ kalẹ̀+ kúrò níbi rírú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ ìdàpọ̀. 23  Níkẹyìn, Mósè àti Áárónì lọ sínú àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì jáde wá, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà.+ Nígbà náà ni ògo+ Jèhófà fara han gbogbo àwọn ènìyàn náà, 24  iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jó ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀rá tí ó wà lórí pẹpẹ run. Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn náà rí i, wọ́n hó yèè,+ wọ́n sì dojú bolẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé