Léfítíkù 26:1-46
26 “‘Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí fún ara yín,+ ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbé ère gbígbẹ́+ tàbí ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ kalẹ̀ fún ara yín, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbé òkúta kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun àfihàn+ ní ilẹ̀ yín láti tẹrí ba fún un;+ nítorí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.
2 Kí ẹ máa pa àwọn sábáàtì+ mi mọ́, kí ẹ sì ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ibùjọsìn mi. Èmi ni Jèhófà.
3 “‘Bí ẹ bá ń bá a lọ́ láti máa rìn nínú àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi, tí ẹ sì ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì ń mú wọn ṣẹ,+
4 Dájúdájú, èmi yóò fún yín ní ọ̀wààrà òjò ní àkókò rẹ̀ tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,+ ilẹ̀ yóò sì mú èso rẹ̀ wá+ ní ti gidi, igi pápá yóò sì fi èso rẹ̀ fúnni.+
5 Dájúdájú, ìpakà yín yóò dé ìgbà kíkó èso àjàrà jọ, ìgbà kíkó èso àjàrà jọ yóò sì dé ìgbà fífún irúgbìn; ẹ ó sì jẹ oúnjẹ yín ní àjẹyó,+ ẹ ó sì máa gbé ní ààbò ní ilẹ̀ yín.+
6 Dájúdájú, èmi yóò fi àlàáfíà sí ilẹ̀ náà,+ ẹ ó sì dùbúlẹ̀ ní ti gidi, ẹnì kankan kì yóò mú yín wárìrì;+ èmi yóò sì mú kí aṣeniléṣe ẹranko ẹhànnà kásẹ̀ nílẹ̀ ní ilẹ̀ náà,+ idà kì yóò sì la ilẹ̀ yín já.+
7 Dájúdájú, ẹ óò lépa àwọn ọ̀tá yín,+ wọn yóò sì ṣubú ní ti gidi níwájú yín nípa idà.
8 Dájúdájú, márùn-ún nínú yín yóò lépa ọgọ́rùn-ún, ọgọ́rùn-ún nínú yín yóò sì lépa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá, àwọn ọ̀tá yín yóò sì ṣubú ní ti gidi níwájú yín nípa idà.+
9 “‘Dájúdájú, èmi yóò yíjú sí yín,+ èmi yóò sì mú kí ẹ so èso, èmi yóò sì sọ yín di púpọ̀,+ èmi yóò sì mú májẹ̀mú mi pẹ̀lú yín ṣẹ.+
10 Dájúdájú, ẹ ó jẹ ẹ̀gbẹ ti ọdún tí ó ṣáájú,+ ẹ ó sì mú ẹ̀gbẹ jáde ṣáájú tuntun.
11 Dájúdájú, èmi yóò sì gbé àgọ́ ìjọsìn mi kalẹ̀ sí àárín yín,+ ọkàn mi kì yóò sì kórìíra yín tẹ̀gàntẹ̀gàn.+
12 Ní ti gidi, èmi yóò rìn ní àárín yín, èmi yóò sì fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin ní tiyín, yóò sì fi hàn pé ẹ jẹ́ ènìyàn mi.+
13 Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, kúrò nínú ṣíṣe ẹrú fún wọn,+ mo sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́ àwọn ọ̀pá àjàgà yín, mo sì mú yín rìn ní ìnàróṣánṣán.+
14 “‘Àmọ́ ṣá o, bí ẹ kò bá ní fetí sí mi tàbí kí ẹ pa gbogbo àṣẹ wọ̀nyí mọ́,+
15 bí ẹ bá sì kọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi sílẹ̀,+ bí ọkàn yín bá sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi láti má ṣe pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, dé àyè pé ẹ da májẹ̀mú mi,+
16 nígbà náà, èmi, ní tèmi, yóò ṣe ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí sí yín, ní ti ìyà, èmi yóò mú ìyọlẹ́nu pẹ̀lú ikọ́ ẹ̀gbẹ+ àti ibà amára-gbóná-fòfò wá sórí yín, tí yóò mú kí ojú kọṣẹ́,+ tí yóò sì mú kí ọkàn joro dànù.+ Ẹ ó sì wulẹ̀ fún irúgbìn yín lásán, nítorí àwọn ọ̀tá yín yóò jẹ ẹ́ tán dájúdájú.+
17 Èmi yóò sì dojú kọ yín, a ó sì ṣẹ́gun yín dájúdájú níwájú àwọn ọ̀tá yín;+ àwọn tí ó kórìíra yín yóò sì wulẹ̀ tẹ̀ yín mọ́lẹ̀,+ ẹ ó sì sá lọ ní ti tòótọ́ nígbà tí ẹnì kankan kò lépa yín.+
18 “‘Ṣùgbọ́n, láìka nǹkan wọ̀nyí sí, bí ẹ kò bá ní fetí sí mi, nígbà náà, èmi yóò nà yín ní ìlọpo méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.+
19 Èmi yóò sì ṣẹ́ ìgbéraga okun yín, èmi yóò sì ṣe ojú ọ̀run yín bí irin+ àti ilẹ̀ yín bí bàbà.
20 Ẹ ó sì lo agbára yín lásán, nítorí tí ilẹ̀ yín kì yóò mú èso rẹ̀ jáde,+ igi ilẹ̀ kì yóò sì mú èso rẹ̀ jáde.+
21 “‘Ṣùgbọ́n bí ẹ bá ń rìn nìṣó ní ìlòdì sí mi, tí ẹ kò sì fẹ́ láti fetí sí mi, nígbà náà, èmi yóò mú ìyọnu àgbálù púpọ̀ sí i wá bá yín ní ìgbà méje gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín.+
22 Dájúdájú, èmi yóò rán àwọn ẹranko ẹhànnà inú pápá sí àárín yín,+ wọn yóò sì mú kí ẹ ṣòfò ọmọ+ yín dájúdájú, wọn yóò sì ké àwọn ẹran agbéléjẹ̀ yín kúrò, wọn yóò sì dín iye yín kù, àwọn ojú ọ̀nà yín yóò sì di ahoro+ ní ti tòótọ́.
23 “‘Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹ kò bá gba ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ mi nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí,+ dájúdájú, tí ẹ wulẹ̀ ń rìn ní ìlòdì sí mi,
24 èmi, bẹ́ẹ̀ ni, èmi, nígbà náà, yóò rìn ní ìlòdì sí yín;+ èmi, àní èmi, yóò sì lù yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.+
25 Dájúdájú, èmi yóò mú idà wá sórí yín, èyí tí ń mú ẹ̀san+ ṣẹ fún májẹ̀mú+ náà; ẹ ó sì kó ara yín jọ ní ti gidi sínú ìlú ńlá yín, dájúdájú, èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀ àrùn sí àárín yín,+ a ó sì fi yín lé ọwọ́ ọ̀tá.+
26 Nígbà tí mo bá bá yín ṣẹ́ àwọn ọ̀pá tí a fi àwọn ìṣù búrẹ́dì onírìísí òrùka rọ̀ sí,+ nígbà náà, obìnrin mẹ́wàá yóò yan búrẹ́dì yín nínú ààrò kan, wọn yóò sì fi búrẹ́dì yín fúnni padà nípasẹ̀ ìwọ̀n;+ ẹ ó sì jẹ, ṣùgbọ́n ẹ kì yóò yó.+
27 “‘Àmọ́ ṣá o, bí ẹ kò bá ní fetí sí mi nípa èyí, tí ẹ wulẹ̀ ń rin ní ìlòdì sí mi,+
28 nígbà náà, èmi yóò rìn ní ìlòdì sí yín+ lọ́nà gbígbóná, èmi, bẹ́ẹ̀ ni, èmi yóò nà yín ní ìgbà méje nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.+
29 Nítorí náà, ẹ óò ní láti jẹ ẹran ara àwọn ọmọkùnrin yín, ẹ ó sì jẹ ẹran ara àwọn ọmọbìnrin yín.+
30 Dájúdájú, èmi yóò sì pa àwọn ibi gíga+ ọlọ́wọ̀ yín rẹ́ ráúráú, èmi yóò sì ké pẹpẹ tùràrí yín kúrò, èmi yóò sì gbé òkú yín lé òkú àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín;+ ọkàn mi yóò wulẹ̀ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra yín.+
31 Èmi yóò sì fi àwọn ìlú ńlá yín fún idà+ ní ti gidi, èmi yóò sì sọ àwọn ibùjọsìn yín di ahoro,+ èmi kì yóò sì gbọ́ òórùn amáratuni yín.+
32 Èmi, ní tèmi, yóò sì sọ ilẹ̀ náà di ahoro,+ àwọn ọ̀tá yín tí ń gbé inú rẹ̀ yóò wulẹ̀ wò ó sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì.+
33 Èmi yóò sì tú yín ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ èmi yóò sì fa idà yọ láti inú àkọ̀ tọ̀ yín lẹ́yìn;+ ilẹ̀ yín yóò sì di ahoro,+ àwọn ìlú ńlá yín yóò sì di ìparundahoro.
34 “‘Ní àkókò yẹn, ilẹ̀ náà yóò san àwọn sábáàtì rẹ̀ tán ní gbogbo ọjọ́ tí ó fi wà ní ahoro, nígbà tí ẹ bá wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín. Ní àkókò yẹn, ilẹ̀ náà yóò pa sábáàtì mọ́, nítorí yóò san àwọn sábáàtì rẹ̀ padà.+
35 Gbogbo ọjọ́ tí ó fi wà ní ahoro ni yóò pa sábáàtì mọ́, nítorí ìdí náà pé kò pa sábáàtì mọ́ nígbà àwọn sábáàtì yín, nígbà tí ẹ ń gbé lórí rẹ̀.
36 “‘Ní ti àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú yín,+ èmi yóò mú ojora wá sínú ọkàn-àyà wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn; ìró ewé tí a ń gbá kiri yóò lé wọn sá lọ ní ti gidi, wọn yóò sì fẹsẹ̀ fẹ bí ẹni fẹsẹ̀ fẹ nítorí idà, wọn yóò sì ṣubú láìsí ẹni tí ń lépa wọn.+
37 Wọn yóò sì kọlu ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹni ń sá níwájú idà láìsí ẹni tí ń lépa wọn, àti fún ẹ̀yin, kì yóò sì sí agbára fún yín láti dúró ní ìkọjú-ìjà-sí àwọn ọ̀tá yín.+
38 Ẹ ó sì ṣègbé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín yóò sì jẹ yín tán.
39 Ní ti àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú yín, wọn yóò jẹrà dànù+ nítorí ìṣìnà wọn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá yín. Bẹ́ẹ̀ ni, àní nítorí ìṣìnà àwọn baba wọn,+ pẹ̀lú wọn ni wọn yóò jẹrà dànù.
40 Dájúdájú, wọn yóò jẹ́wọ́ ìṣìnà+ àwọn fúnra wọn àti ìṣìnà àwọn baba wọn nínú ìwà àìṣòótọ́ wọn nígbà tí wọ́n hùwà àìṣòótọ́ sí mi, bẹ́ẹ̀ ni, àní nígbà tí wọ́n rìn ní ìlòdì sí mi.+
41 Nígbà náà ni èmi, àní èmi pàápàá, bẹ̀rẹ̀ sí rìn ní ìlòdì sí wọn,+ tí ó fi wá di pé mo mú wọn wá sí ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn.+
“‘Bóyá ní àkókò yẹn, a ó rẹ ọkàn-àyà+ wọn tí a kò dádọ̀dọ́ rẹ̀ sílẹ̀,+ àti ní àkókò yẹn, wọn yóò jì yà ìṣìnà wọn.
42 Èmi ní ti gidi yóò sì rántí májẹ̀mú mi pẹ̀lú Jékọ́bù;+ májẹ̀mú mi pẹ̀lú Ísákì+ pàápàá àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Ábúráhámù+ pàápàá ni èmi yóò rántí, èmi yóò sì rántí ilẹ̀ náà.
43 Ní gbogbo àkókò náà, wọ́n pa ilẹ̀ náà tì, ó sì ń san àwọn sábáàtì+ rẹ̀ nígbà tí ó wà ní ahoro láìsí wọn, àwọn fúnra wọn sì ń jì yà ìṣìnà wọn,+ nítorí pé, àní nítorí pé, wọ́n ti kọ àwọn ìpinnu ìdájọ́+ mi sílẹ̀, ọkàn wọn sì fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi.+
44 Síbẹ̀, nínú gbogbo èyí, nígbà tí wọ́n ń bá a lọ láti wà ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn, dájúdájú, èmi kì yóò kọ̀ wọ́n,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò kórìíra wọn+ tẹ̀gàntẹ̀gàn láti pa wọ́n run pátápátá, láti da májẹ̀mú+ mi pẹ̀lú wọn; nítorí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.
45 Nítorí wọn, èmi yóò si rántí májẹ̀mú àwọn baba ńlá ìgbàanì+ tí mo mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lójú àwọn orílẹ̀-èdè,+ láti fi hàn pé èmi ni Ọlọ́run wọn. Èmi ni Jèhófà.’”
46 Ìwọ̀nyí ni ìlànà àti ìpinnu ìdájọ́+ àti òfin tí Jèhófà fi lélẹ̀ láàárín òun fúnra rẹ̀ àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òkè Ńlá Sínáì nípasẹ̀ Mósè.+

