Léfítíkù 24:1-23
24 Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:
2 “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n bá ọ wá ògidì òróró ólífì tí a fún, tí ó wà fún orísun ìmọ́lẹ̀,+ láti máa fi tan fìtílà nígbà gbogbo.+
3 Òde aṣọ ìkélé Gbólóhùn Ẹ̀rí nínú àgọ́ ìpàdé ni kí Áárónì ṣètò rẹ̀ sí, láti alẹ́ títí di òwúrọ̀ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo. Ìlànà àgbékalẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin ni, ní ìran-ìran yín.
4 Orí ọ̀pá fìtílà+ tí a fi ògidì wúrà ṣe ni kí ó ṣètò àwọn fìtílà+ náà sí níwájú Jèhófà nígbà gbogbo.+
5 “Kí o sì mú ìyẹ̀fun kíkúnná, kí o sì fi yan àkàrà méjì lá onírìísí òrùka. Ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà ni kí a lò fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àkàrà onírìísí òrùka náà.
6 Kí o sì tò wọ́n ní ipele méjì , mẹ́fà ní ipele+ kan, lórí tábìlì tí a fi ògidì wúrà ṣe tí ó wà níwájú Jèhófà.+
7 Kí o sì fi ògidì oje igi tùràrí sórí ọ̀wọ́ ipele kọ̀ọ̀kan, kí ó sì wà gẹ́gẹ́ bí búrẹ́dì fún ohun ìránnilétí,+ ọrẹ ẹbọ àfinásun sí Jèhófà ni.
8 Ní ọjọ́ sábáàtì kan tẹ̀ lé èkejì ni kí ó ṣètò rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà nígbà gbogbo.+ Májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni fún àkókò tí ó lọ kánrin.
9 Kí ó sì di ti Áárónì àti ti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀,+ kí wọ́n sì jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ nítorí pé ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún un láti inú àwọn ọrẹ ẹbọ Jèhófà tí a fi iná sun, gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”
10 Wàyí o, ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti obìnrin Ísírẹ́lì kan, ṣùgbọ́n, tí ó jẹ́ ọmọ ti ọkùnrin ará Íjíbítì,+ jáde lọ sí àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti ọmọbìnrin Ísírẹ́lì náà àti ọkùnrin Ísírẹ́lì kan sì bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jì jàkadì+ nínú ibùdó.
11 Ọmọkùnrin tí ó jẹ́ ti obìnrin Ísírẹ́lì náà sì kẹ́gàn Orúkọ+ náà, ó sì pe ibi wá sórí rẹ̀.+ Nítorí náà, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ Mósè.+ Ó ṣẹlẹ̀ pé, orúkọ ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ṣẹ́lómítì, ọmọbìnrin Díbírì ti ẹ̀yà Dánì.
12 Nígbà náà ni wọ́n fi í sínú ìhámọ́+ títí di ìgbà tí ìpolongo tí ó ṣe kedere sí wọn yóò fi wà gẹ́gẹ́ bí àsọjáde Jèhófà.+
13 Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè sọ̀rọ̀, pé:
14 “Mú ẹni náà tí ó pe ibi wá sí òde ibùdó;+ kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ sì gbé ọwọ́+ wọn lé orí rẹ̀, kí gbogbo àpéjọ náà pátá sì sọ ọ́ ní òkúta.+
15 Kí o sì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, pé, ‘Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnikẹ́ni pe ibi wá sórí Ọlọ́run rẹ̀, nígbà náà, kí ó dáhùn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
16 Nítorí náà, olùkẹ́gàn orúkọ Jèhófà ni kí a fi ikú pa láìkùnà.+ Kí gbogbo àpéjọ náà pátá sọ ọ́ ní òkúta láìkùnà. Kí a fi ikú pa àtìpó lọ́nà kan náà bí ọmọ ìbílẹ̀ fún kíkẹ́gàn tí ó kẹ́gàn Orúkọ+ náà.
17 “‘Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan kọlu ọkàn èyíkéyìí nínú aráyé lọ́nà tí ó yọrí sí ikú, kí a fi ikú pa á láìkùnà.+
18 Kí ẹni tí ó sì kọlu ọkàn ẹran agbéléjẹ̀ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú san àsanfidípò fún un, ọkàn fún ọkàn.+
19 Bí ó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ènìyàn kan fa àbùkù sí ara ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, nígbà náà, gan-an bí òun ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni kí a ṣe sí i.+
20 Ìṣẹ́léegun fún ìṣẹ́léegun, ojú fún ojú, eyín fún eyín; irú àbùkù kan náà tí ó lè fà sí ara ẹni náà, ìyẹn ni kí a fà sí ara òun náà.+
21 Kí ẹni tí ó kọlu ẹranko+ lọ́nà tí ó yọrí sí ikú san àsanfidípò+ fún un, ṣùgbọ́n kí a fi ikú pa+ ẹni tí ó kọlu ènìyàn lọ́nà tí ó yọrí sí ikú.
22 “‘Ìpinnu ìdájọ́ kan ṣoṣo ni kí ó wà fún yín. Kí ti àtìpó jẹ́ ọ̀kan náà bí ti ọmọ ìbílẹ̀,+ nítorí pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’”+
23 Lẹ́yìn ìyẹn, Mósè bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọ́n sì mú ẹni náà tí ó pe ibi wá sí òde ibùdó, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta.+ Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè.

