Léfítíkù 13:1-59

13  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, pé: 2  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àwúfọ́ tàbí ẹ̀yi+ tàbí àmì àbààwọ́n yọ ní awọ ara ènìyàn kan, tí ó sì yọrí sí àrùn ẹ̀tẹ̀+ ní awọ ara rẹ̀, nígbà náà, kí a mú un wá sọ́dọ̀ Áárónì àlùfáà tàbí sọ́dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àlùfáà.+ 3  Kí àlùfáà sì wo àrùn inú awọ ara náà.+ Bí irun inú àrùn náà bá ti di funfun, tí ìrísí àrùn náà sì jì n ju awọ ara rẹ̀ lọ, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Kí àlùfáà sì wò ó, kí ó sì polongo rẹ̀ ní aláìmọ́. 4  Ṣùgbọ́n bí àmì àbààwọ́n náà bá funfun ní awọ ara rẹ̀, tí ìrísí rẹ̀ kò sì jì n ju awọ ara lọ, tí irun rẹ̀ kò sì tíì funfun, nígbà náà, kí àlùfáà sé àrùn náà mọ́+ fún ọjọ́ méje. 5  Kí àlùfáà sì wò ó ní ọjọ́ keje, bí ó bá sì jẹ́ pé bí ó ṣe rí ni pé, àrùn náà ti dáwọ́ dúró, àrùn náà kò tíì gbèèràn ní awọ ara, kí àlùfáà tún sé e mọ́ nítorí àrùn+ fún ọjọ́ méje mìíràn. 6  “Kí àlùfáà sì wò ó ní ọjọ́ keje ní ìgbà kejì , bí àrùn náà bá sì rí bàìbàì, tí àrùn náà kò sì tíì gbèèràn ní awọ ara náà, kí àlùfáà sì pè é ní ẹni tí ó mọ́. Ẹ̀yi ni. Kí ó sì fọ àwọn ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì mọ́. 7  Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yi náà, láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, bá ti gbèèràn ní awọ ara náà lẹ́yìn tí ó fara hàn níwájú àlùfáà fún ìfìdímúlẹ̀ ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀, nígbà náà, kí ó fara hàn ní ìgbà kejì níwájú àlùfáà,+ 8  kí àlùfáà sì wò ó; bí ẹ̀yi náà bá sì ti gbèèràn ní awọ ara náà, nígbà náà, kí àlùfáà polongo rẹ̀ ní aláìmọ́. Ẹ̀tẹ̀ ni.+ 9  “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ yọ lára ènìyàn kan, nígbà náà, kí a mú un wá sọ́dọ̀ àlùfáà. 10  Kí àlùfáà sì wò ó;+ bí àwúfọ́ funfun bá sì wà ní awọ ara rẹ̀, tí ó sì sọ irun rẹ̀ di funfun, tí ẹran ààyè tútù+ sì wà nínú àwúfọ́ náà, 11  ẹ̀tẹ̀ bárakú+ ni ó wà ní awọ ara rẹ̀; kí àlùfáà polongo ẹni náà ní aláìmọ́. Kí ó má ṣe sé e mọ́ nítorí àrùn,+ nítorí pé aláìmọ́ ni. 12  Wàyí o, bí ẹ̀tẹ̀ náà, láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, bá sọ jáde ní awọ ara, tí ẹ̀tẹ̀ bá sì bo gbogbo awọ ara ẹni tí ó ní àrùn náà láti orí rẹ̀ dé ẹsẹ̀ rẹ̀, ní gbogbo ibi tí ojú àlùfáà ń wò; 13  tí àlùfáà náà sì wò ó, sì kíyè sí i, ẹ̀tẹ̀ náà ti bo gbogbo ara rẹ̀, nígbà náà, kí ó pe àrùn náà ni ohun tí ó mọ́. Gbogbo rẹ̀ ti di funfun. Ẹni náà mọ́. 14  Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ tí ẹran ààyè bá fara hàn nínú rẹ̀, òun yóò di aláìmọ́. 15  Kí àlùfáà+ sì wo ẹran ààyè náà, kí ó sì polongo ẹni náà ní aláìmọ́. Ẹran ààyè náà jẹ́ aláìmọ́. Ẹ̀tẹ̀ ni.+ 16  Tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹran ààyè náà para dà, tí ó sì di funfun, nígbà náà, kí ó wá sọ́dọ̀ àlùfáà. 17  Kí àlùfáà sì wò ó,+ bí àrùn náà bá sì ti yí padà di funfun, nígbà náà, kí àlùfáà pe àrùn náà ní ohun tí ó mọ́. Ẹni náà mọ́. 18  “Ní ti ara náà, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé oówo+ yọ ní awọ rẹ̀, tí ó sì sàn ní ti gidi, 19  àti ní ipò oówo náà, tí àwúfọ́ funfun sì yọ tàbí àmì àbààwọ́n aláwọ̀ funfun àdàpọ̀-mọ́-pupa, nígbà náà, kí ó fi ara rẹ̀ han àlùfáà. 20  Kí àlùfáà sì wò ó,+ bí ìrísí rẹ̀ bá jì n ju awọ ara, tí irun rẹ̀ sì ti di funfun, nígbà náà, kí àlùfáà polongo ẹni náà ní aláìmọ́. Àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. Ó sọ jáde nínú oówo náà. 21  Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá wò ó, àti ní báyìí, sì kíyè sí i, kò sí irun funfun nínú rẹ̀, tí kò sì jì n ju awọ ara lọ, tí ó sì rí bàìbàì, nígbà náà, kí àlùfáà sé e mọ́ nítorí àrùn+ fún ọjọ́ méje. 22  Bí ó bá sì gbèèràn ní awọ ara lọ́nà tí ó hàn kedere, kí àlùfáà polongo ẹni náà ní aláìmọ́. Àrùn ni. 23  Ṣùgbọ́n bí àmì àbààwọ́n bá dúró ní ipò rẹ̀, tí kò gbèèràn, ìwúlé oówo ni;+ kí àlùfáà sì pè é ní ẹni tí ó mọ́.+ 24  “Tàbí, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àpá wà ní awọ ara tí iná jó, tí ẹran ara tútù àpá náà sì di àmì àbààwọ́n aláwọ̀ funfun àdàpọ̀-mọ́-pupa tàbí funfun, 25  nígbà náá, kí àlùfáà wò ó; bí irun náà bá sì ti yí padà di funfun nínú àmì àbààwọ́n náà, tí ìrísí rẹ̀ sì jì n ju awọ ara lọ, ẹ̀tẹ̀ ni. Ó sọ jáde nínú àpá ni, kí àlúfáà polongo ẹni náà ní aláìmọ́. Àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 26  Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá wò ó, àti ní báyìí, sì kíyè sí i, kò sí irun funfun nínú àmì àbààwọ́n náà, tí kò sì jì n ju awọ ara lọ, tí ó sì rí bàìbàì, nígbà náà, kí àlùfáà sé e mọ́ nítorí àrùn fún ọjọ́ méje. 27  Kí àlùfáà sì wò ó ní ọjọ́ keje. Bí ó bá sì gbèèràn ní awọ ara lọ́nà tí ó hàn kedere, nígbà náà, kí àlùfáà polongo ẹni náà ní aláìmọ́. Àrùn ẹ̀tẹ̀ ni. 28  Ṣùgbọ́n bí àmì àbààwọ́n bá dúró ní ipò rẹ̀, tí kò gbèèràn ní awọ ara, tí ó sì rí bàìbàì, àwúfọ́ àpá ni; kí àlùfáà pè é ní ẹni tí ó mọ́, nítorí pé ìwúlé àpá ni. 29  “Ní ti ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àrùn yọ lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní orí tàbí ní àgbọ̀n, 30  nígbà náà, kí àlùfáà+ wo àrùn náà; bí ìrísí rẹ̀ bá sì jì n ju awọ ara lọ, tí irun náà sì jẹ́ yẹ́lò, tí ó sì rí gátagàta nínú rẹ̀, nígbà náà, kí àlùfáà polongo irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní aláìmọ́. Irun ríre lódìlódì ni.+ Ẹ̀tẹ̀ orí tàbí ti àgbọ̀n ni. 31  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àlùfáà rí àrùn irun ríre lódìlódì, sì wò ó! ìrísí rẹ̀ kò jì n ju awọ ara lọ, tí kò sì sí irun dúdú nínú rẹ̀, nígbà náà, kí àlùfáà sé àrùn irun ríre lódìlódì náà mọ́+ fún ọjọ́ méje.+ 32  Kí àlùfáà sì wo àrùn náà ní ọjọ́ keje; bí irun ríre lódìlódì náà kò bá sì gbèèràn, tí irun tí ó jẹ́ yẹ́lò kò sì yọ nínú rẹ̀, tí ìrísí irun ríre lódìlódì+ náà kò sì jì n ju awọ ara lọ, 33  nígbà náà, kí ó fá irun rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó má ṣe fá irun ríre lódìlódì+ náà; kí àlùfáà sì sé irun ríre lódìlódì náà mọ́ fún ọjọ́ méje lẹ́ẹ̀kan sí i. 34  “Kí àlùfáà sì wo irun ríre lódìlódì náà ní ọjọ́ keje; bí irun ríre lódìlódì náà kò bá sì gbèèràn ní awọ ara, tí ìrísí rẹ̀ kò sì jì n ju awọ ara lọ, nígbà náà, kí àlùfáà pè é ní ẹni tí ó mọ́,+ kí ó sì fọ àwọn ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì mọ́. 35  Ṣùgbọ́n bí irun ríre lódìlódì náà bá gbèèràn ní awọ ara lọ́nà tí ó hàn kedere lẹ́yìn ìfìdímúlẹ̀ ìwẹ̀mọ́gaara rẹ̀, 36  nígbà náà, kí àlùfáà+ wò ó; bí irun ríre lódìlódì náà bá sì ti gbèèràn ní awọ ara, àlùfáà kò ní láti ṣe àyẹ̀wò láti rí irun tí ó jẹ́ yẹ́lò; aláìmọ́ ni. 37  Ṣùgbọ́n ní ìrí rẹ̀, bí irun ríre lódìlódì náà bá dúró, tí irun dúdú sì ti hù nínú rẹ̀, irun ríre lódìlódì náà ti sàn. Ẹni náà mọ́, kí àlùfáà sì pè é ní ẹ̀ni tí ó mọ́.+ 38  “Ní ti ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àmì àbààwọ́n+ yọ ní awọ ara wọn, àmì àbààwọ́n funfun, 39  nígbà náà, kí àlùfáà+ wò ó; bí àmì àbààwọ́n inú awọ ara wọn bá jẹ́ funfun bàìbàì, àwúfọ́ aláìlè-panilára ni. Ó sọ jáde ní awọ ara. Ẹni náà mọ́. 40  “Ní ti ọkùnrin kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé orí rẹ̀ pá,+ ìpárí ni. Ó mọ́. 41  Bí orí rẹ̀ bá sì pá ní iwájú, ìpárí iwájú orí ni. Ó mọ́. 42  Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àrùn aláwọ̀ funfun àdàpọ̀-mọ́-pupa yọ nínú ìpárí látàrí tàbí níwájú orí, ẹ̀tẹ̀ ni, ó sọ jáde nínú ìpárí rẹ̀ látàrí tàbí níwájú orí rẹ̀. 43  Kí àlùfáà+ sì wò ó; bí àwúfọ́ àrùn aláwọ̀ funfun àdàpọ̀-mọ́-pupa bá wà nínú ìpárí rẹ̀ látàrí tàbí níwájú ori rẹ̀, bí ìrísí ẹ̀tẹ̀ inú awọ ara, 44  adẹ́tẹ̀ ni. Aláìmọ́ ni. Kí àlùfáà polongo rẹ̀ ní aláìmọ́. Àrùn rẹ̀ ń bẹ ní orí rẹ̀. 45  Ní ti adẹ́tẹ̀ tí àrùn náà wà lára rẹ̀, kí a ya àwọn ẹ̀wù rẹ̀,+ kí orí rẹ̀ sì wà láìtọ́jú,+ kí ó sì bo túbọ̀mu,+ kí ó sì ké jáde pé, ‘Aláìmọ́, aláìmọ́!’+ 46  Gbogbo ọjọ́ tí àrùn náà bá fi wà lára rẹ̀ ni yóò fi jẹ́ aláìmọ́. Aláìmọ́ ni. Kí ó máa gbé ní àdádó. Òde ibùdó+ ni ibi gbígbé rẹ̀. 47  “Ní ti ẹ̀wù kan, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé àrùn ẹ̀tẹ̀ yọ lára rẹ̀, yálà lára ẹ̀wù onírun àgùntàn tàbí lára ẹ̀wù aṣọ ọ̀gbọ̀, 48  tàbí lára òwú títa+ tàbí lára òkùkù aṣọ ọ̀gbọ̀ tàbí ti irun àgùntàn, tàbí lára awọ tàbí lára ohunkóhun tí a fi awọ ṣe,+ 49  tí àrùn aláwọ̀ ewéko àdàpọ̀-mọ́-yẹ́lò tàbí aláwọ̀ pupa rúsúrúsú sì yọ lára ẹ̀wù tàbí lára awọ tàbí lára òwú títa tàbí lára òkùkù tàbí lára ohun èlò awọ èyíkéyìí, àrùn ẹ̀tẹ̀ ni, kí a fi í han àlùfáà. 50  Kí àlùfáà+ sì wo àrùn náà, kí ó sì sé àrùn náà mọ́+ fún ọjọ́ méje. 51  Nígbà tí ó bá ti rí àrùn náà ní ọjọ́ keje, pé àrùn náà ti gbèèràn lára ẹ̀wù tàbí lára òwú títa tàbí lára òkùkù+ tàbí lára awọ fún ìlò èyíkéyìí tí a torí rẹ̀ ṣe awọ náà, àrùn ẹ̀tẹ̀ afòòró-ẹ̀mí ni.+ Ó jẹ́ aláìmọ́. 52  Kí ó sì fi iná sun ẹ̀wù tàbí òwú títa tàbí òkùkù inú irun àgùntàn tàbí ti inú aṣọ ọ̀gbọ̀+ tàbí ohun èlò awọ èyíkéyìí tí àrùn náà lè yọ lára rẹ̀, nítorí pé ẹ̀tẹ̀ afòòró-ẹ̀mí+ ni. Kí a fi iná sun ún. 53  “Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá wò ó, àti ní báyìí, sì kíyè sí i, àrùn náà kò gbèèràn lárá ẹ̀wù tàbí lára òwú títa tàbí lára òkùkù tàbí lára ohun èlò èyíkéyìí tí a fi awọ ṣe,+ 54  kí àlùfáà sì tún pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohun tí àrùn náà wà nínú rẹ̀, kí ó sì sé e mọ́ nítorí àrùn fún ọjọ́ méje mìíràn sí i. 55  Kí àlùfáà sì wo àrùn náà lẹ́yìn tí a ti fọ̀ ọ́ kúrò, bí àrùn náà kò bá sì tíì yí ìrí rẹ̀ padà, síbẹ̀ tí àrùn náà kò gbèèràn, aláìmọ́ ni. Kí o sun ún nínú iná. Ibi tí ó jẹ kan fọ́nrán òwú lára aṣọ ni, ní abẹ́ rẹ̀ tàbí ní òde rẹ̀. 56  “Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá ti wò ó, àti ní báyìí, kíyè sí i, àrùn náà rí bàìbàì lẹ́yìn tí a ti fọ̀ ọ́ kúrò, nígbà náà, kí ó ya á kúrò lára ẹ̀wù tàbí awọ tàbí òwú títa tàbí òkùkù náà. 57  Àmọ́ ṣá o, bí ó bá ṣì fara hàn nínú ẹ̀wù tàbí nínú òwú títa tàbí nínú òkùkù+ tàbí ohun èlò èyíkéyìí tí a fi awọ ṣe, ó sọ jáde ni. Kí ó sun+ ohun yòówù tí àrùn náà bá wà lára rẹ̀ nínú iná. 58  Ní ti ẹ̀wù tàbí òwú títa tàbí òkùkù tàbí ohun èlò awọ èyíkéyìí tí o bá fọ̀, nígbà tí àrùn náà bá dàwátì kúrò lára wọn, nígbà náà, kí a fọ̀ ọ́ lẹ́ẹ̀kejì ; kí ó sì mọ́. 59  “Èyí ni òfin àrùn ẹ̀tẹ̀ ara ẹ̀wù tí a fi irun àgùntàn ṣe tàbí aṣọ ọ̀gbọ̀,+ tàbí ti ara òwú títa tàbí ti ara òkùkù tàbí ti ara ohun èlò èyíkéyìí tí a fi awọ ṣe, láti pè é ní ohun tí ó mọ́ tàbí láti polongo rẹ̀ ní aláìmọ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé