Léfítíkù 11:1-47
11 Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti bá Mósè àti Áárónì sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé:
2 “Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé, ‘Èyí ni ẹ̀dá alààyè tí ẹ lè jẹ+ nínú gbogbo ẹranko tí ó wà lórí ilẹ̀:
3 Gbogbo ẹ̀dá tí ó la pátákò tí ó sì ní àlàfo ní pátákò tí ó sì ń jẹ àpọ̀jẹ nínú àwọn ẹranko, ìyẹn ni èyí tí ẹ lè jẹ.+
4 “‘Kì kì èyí ni ohun tí ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn tí ń jẹ àpọ̀jẹ àti àwọn tí ó la pátákò: ràkúnmí, nítorí èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ ni, ṣùgbọ́n kò la pátákò. Aláìmọ́ ni fún yín.+
5 Àti gárá orí àpáta pẹ̀lú,+ nítorí èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ ni, ṣùgbọ́n kò la pátákò. Aláìmọ́ ni fún yín.
6 Àti ehoro pẹ̀lú,+ nítorí èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ ni, ṣùgbọ́n kò la pátákò. Aláìmọ́ ni fún yín.
7 Àti ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lú,+ nítorí tí ó la pátákò tí ó sì ní àlàfo ní pátákò, ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ni fún yín.
8 Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ èyíkéyìí nínú ẹran wọn, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fara kan òkú wọn.+ Aláìmọ́ ni wọ́n fún yín.+
9 “‘Èyí ni ohun tí ẹ lè jẹ nínú gbogbo ohun tí ó wà nínú omi:+ Ohun gbogbo tí ó ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́+ nínú omi, nínú òkun àti nínú ọ̀gbàrá, àwọn wọ̀nyẹn ni ẹ lè jẹ.
10 Àti gbogbo ohun tí ó wà nínú òkun àti ọ̀gbàrá tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́, láti inú gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn inú omi àti gbogbo alààyè ọkàn tí ó wà nínú omi, wọ́n jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín.
11 Bẹ́ẹ̀ ni, wọn yóò máa jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín. Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ èyíkéyìí nínú ẹran wọn,+ kí ẹ sì kórìíra òkú wọn tẹ̀gbintẹ̀gbin.
12 Ohun gbogbo tí ó wà nínú omi tí kò ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́ jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín.
13 “‘Àwọn wọ̀nyí ni ohun tí ẹ ó sì máa kórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin láàárín ẹ̀dá tí ń fò.+ A kò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. Ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin ni wọ́n: idì+ àti idì ajẹja àti igún dúdú,
14 àti àwòdì pupa àti àwòdì dúdú+ ní irú tirẹ̀,
15 àti gbogbo ẹyẹ ìwò+ ní irú tirẹ̀,
16 àti ògòǹgò+ àti òwìwí àti ẹyẹ àkẹ̀ àti àṣáǹwéwé ní irú tirẹ̀,
17 àti òwìwí kékeré àti ẹyẹ àgò àti òwìwí elétí gígùn,+
18 àti ògbùgbú àti ẹyẹ òfú àti igún,+
19 àti ẹyẹ àkọ̀, ẹyẹ wádòwádò ní irú tirẹ̀, àti àgbìgbò àti àdán.+
20 Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn jẹ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin fún yín.+
21 “‘Kì kì èyí ni ohun tí ẹ lè jẹ nínú gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, àwọn tí wọ́n ní tete lókè ẹsẹ̀ wọn láti fi tọ lórí ilẹ̀.
22 Ìwọ̀nyí ni àwọn tí ó wà nínú wọn tí ẹ lè jẹ: eéṣú aṣíkiri+ ní irú tirẹ̀, àti eéṣú tí ó ṣeé jẹ+ ní irú tirẹ̀, àti ìrẹ̀ ní irú tirẹ̀, àti tata+ ní irú tirẹ̀.
23 Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn abìyẹ́lápá yòókù tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin sì jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin+ fún yín.
24 Nítorí náà, nípa ìwọ̀nyí ni ẹ ó sọ ara yín di aláìmọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá fara kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
25 Àti gbogbo ẹni tí ó bá gbé èyíkéyìí lára òkú wọn yóò fọ+ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
26 “‘Ní ti ẹranko èyíkéyìí tí ó la pátákò, ṣùgbọ́n tí kò ní àlàfo ní pátákò, tí kì í sì í ṣe èyí tí ń jẹ àpọ̀jẹ, aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tí ó bá fara kàn wọ́n yóò di aláìmọ́.+
27 Ní ti gbogbo ẹ̀dá tí ń fi àtẹ́sẹ̀ rẹ̀ rìn nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn, aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín. Gbogbo ẹni tí ó bá fara kan òkú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
28 Ẹni tí ó bá sì gbé òkú wọn+ yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀,+ kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.
29 “‘Èyí sì ni aláìmọ́ fún yín láàárín àwọn ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀:+ ẹ̀lírí àti eku àgó+ àti aláǹgbá ní irú tirẹ̀,
30 àti ọmọńlé ẹlẹ́sẹ̀-abẹ̀bẹ̀ àti awọ́nríwọ́n àti aláàmù àti ọlọ́yọ̀ọ́ǹbẹ́rẹ́ àti ọ̀gà.
31 Ìwọ̀nyí jẹ́ aláìmọ́ fún yín láàárín gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn.+ Gbogbo ẹni tí ó bá fara kàn wọ́n nígbà tí wọ́n ti kú yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
32 “‘Wàyí o, ohunkóhun tí èyíkéyìí nínú wọn nígbà tí ó bá ti kú bá já bọ́ lé lórí, yóò di aláìmọ́, yálà ó jẹ́ ohun èlò kan tí a fi igi ṣe+ tàbí ẹ̀wù tàbí awọ+ tàbí aṣọ àpò ìdọ̀họ.+ Ohun èlò èyíkéyìí tí a lò ni kí a fi sínú omi, yóò sì di aláìmọ́ títí di alẹ́, lẹ́yìn náá, yóò sì di ohun tí ó mọ́.
33 Ní ti èyíkéyìí nínú ohun èlò amọ̀+ tí èyìkéyìí nínú wọn bá já bọ́ sí, ohunkóhun tí ó bá wà nínú rẹ̀ yóò di aláìmọ́, kí ẹ sì fọ́ ọ túútúú.+
34 Irú oúnjẹ èyíkéyìí tí a lè jẹ tí omi ara rẹ̀ bá kán sí, yóò di aláìmọ́, ohun mímu èyíkéyìí tí a bá sì mu nínú ohun èlò èyíkéyìí yóò di aláìmọ́.
35 Ohun gbogbo tí èyíkéyìí lára òkú wọn bá sì já bọ́ lé lórí yóò di aláìmọ́. Yálà ó jẹ́ ààrò tàbí ibi tí a ń gbé ìṣà lé, a óò fọ́ ọ túútúú ni. Aláìmọ́ ni wọ́n, wọn yóò sì di aláìmọ́ fún yín.
36 Kì kì ìsun àti kòtò ìwọ́jọpọ̀ omi ni yóò máa bá a lọ láti jẹ́ ohun tí ó mọ́, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú wọn yóò di aláìmọ́.
37 Bí èyíkéyìí lára òkú wọn bá sì já bọ́ sórí irúgbìn èyíkéyìí nínú ọ̀gbìn tí a óò fúnrúgbìn, ó mọ́.
38 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé omi wà lára irúgbìn, tí ohun kan lára òkú wọn sì já bọ́ sórì rẹ̀, aláìmọ́ ni fún yín.
39 “‘Wàyí o, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹranko èyíkéyìí tí ó jẹ́ tiyín tí ó wà fún oúnjẹ bá kú, ẹni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.+
40 Ẹni tí ó bá sì jẹ+ ohun èyíkéyìí lára òkú rẹ̀ yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́; ẹni tí ó bá sì gbé òkú rẹ̀, yóò fọ ẹ̀wù rẹ̀, kí ó sì jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́.
41 Gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀ sì jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin.+ A kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.
42 Ní ti ẹ̀dá èyíkéyìí tí ń fi ikùn+ wọ́ àti ẹ̀dá èyíkéyìí tí ń fi mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rìn tàbí èyíkéyìí tí ó ní ẹsẹ̀ púpọ̀ nínú gbogbo ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀, ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin.+
43 Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń gbá yìn-ìn sọ ọkàn yín di ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ fi wọ́n sọ ara yín di aláìmọ́, ní títipasẹ̀ wọn di aláìmọ́+ ní ti tòótọ́.
44 Nítòrí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín;+ kí ẹ sì sọ ara yín di mímọ́, kí ẹ sì jẹ́ mímọ́,+ nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.+ Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ fi èyíkéyìí lára ẹ̀dá agbáyìn-ìn tí ń rìn lórí ilẹ̀ sọ ọkàn yín di aláìmọ́.
45 Nítorí èmi ni Jèhófà tí ó mú yín gòkè kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti fi ara mi hàn ní Ọlọ́run fún yín;+ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́,+ nítorí pé mo jẹ́ mímọ́.+
46 “‘Èyí sì ni òfin nípa ẹranko àti ẹ̀dá tí ń fò àti gbogbo alààyè ọkàn tí ń lọ káàkiri nínú omi+ àti nípa gbogbo ọkàn tí ń gbá yìn-ìn lórí ilẹ̀,
47 láti fi ìyàtọ̀+ sáàárín aláìmọ́ àti èyí tí ó mọ́ àti sáàárín ẹ̀dá alààyè tí ó ṣée jẹ àti ẹ̀dá alààyè tí a kò gbọ́dọ̀ jẹ.’”

