Jeremáyà 41:1-18

41  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní oṣù keje pé Íṣímáẹ́lì+ ọmọkùnrin Netanáyà ọmọkùnrin Élíṣámà,+ lára àwọn ọmọ tí ó jẹ́ ti ọba,+ àti ti àwọn ènìyàn sàràkí-sàràkí ọba àti ọkùnrin mẹ́wàá mìíràn pẹ̀lú rẹ̀,+ wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ní Mísípà.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ oúnjẹ pọ̀ níbẹ̀ ní Mísípà.+  Nígbà náà ni Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà àti ọkùnrin mẹ́wàá tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde, wọ́n sì fi idà ṣá Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù ọmọkùnrin Ṣáfánì balẹ̀.+ Nípa bẹ́ẹ̀, ó fi ikú pa ẹni tí ọba Bábílónì fàṣẹ yàn lórí ilẹ̀ náà.+  Gbogbo Júù tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, èyíinì ni, pẹ̀lú Gẹdaláyà, ní Mísípà, àti àwọn ará Kálídíà tí wọ́n rí níbẹ̀, èyíinì ni, àwọn ọkùnrin ogun, ni Íṣímáẹ́lì ṣá balẹ̀.  Ó sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kejì tí a fi ikú pa Gẹdaláyà, tí kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ nípa rẹ̀,+  nígbà náà ni àwọn ọkùnrin kan wá láti Ṣékémù,+ láti Ṣílò+ àti láti Samáríà,+ ọgọ́rin ọkùnrin tí wọ́n fá irùngbọ̀n wọn,+ tí wọ́n gbọn ẹ̀wù ara wọn ya, tí wọ́n sì kọ ara wọn lábẹ,+ ọrẹ ẹbọ ọkà àti oje igi tùràrí+ sì ń bẹ ní ọwọ́ wọn tí wọ́n mú wá sí ilé Jèhófà.  Bẹ́ẹ̀ ni Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà jáde láti Mísípà lọ pàdé wọn, ó ń sunkún bí ó ti ń rìn lọ.+ Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí ó bá wọn pàdé, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù.”  Ṣùgbọ́n ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí wọ́n wọnú ìlú ńlá náà, Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n, ó sì ń sọ wọ́n sínú ìkùdu, òun àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.+  Ṣùgbọ́n ọkùnrin mẹ́wàá wà tí a rí láàárín wọn tí wọ́n wí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ fún Íṣímáẹ́lì pé: “Má fi ikú pa wá, nítorí pé àwọn ìṣúra fífarasin láti inú pápá wà lọ́wọ́ wa, àlìkámà àti ọkà bálì àti òróró àti oyin.”+ Nítorí náà, ó fà sẹ́yìn, kò sì fi ikú pa wọ́n ní àárín àwọn arákùnrin wọn.  Wàyí o, ìkùdu tí Íṣímáẹ́lì+ sọ gbogbo òkú àwọn ọkùnrin tí ó ṣá balẹ̀ sí jẹ́ ìkùdu ńlá, èyí tí Ásà Ọba ṣe nítorí Bááṣà ọba Ísírẹ́lì.+ Èyí ni Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà fi àwọn tí a pa kún. 10  Lẹ́yìn náà, Íṣímáẹ́lì mú gbogbo àṣẹ́kù àwọn ènìyàn tí ó wà ní Mísípà ní òǹdè,+ àwọn ọmọbìnrin ọba+ àti gbogbo ènìyàn tí ó ṣẹ́ kù ní Mísípà,+ àwọn tí Nebusárádánì olórí ẹ̀ṣọ́ ti fi sí ìkáwọ́ Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù.+ Nípa bẹ́ẹ̀, Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà mú wọn ní òǹdè, ó sì lọ láti sọdá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.+ 11  Nígbà tí ó ṣe, Jóhánánì+ ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun+ tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá gbọ́ gbogbo búburú tí Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà ṣe. 12  Nítorí náà, wọ́n kó gbogbo ọkùnrin, wọ́n sì lọ láti bá Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà jà, wọ́n sì rí i lẹ́bàá omi púpọ̀ yanturu tí ó wà ní Gíbéónì.+ 13  Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo ènìyàn tí ó wà pẹ̀lú Íṣímáẹ́lì rí Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀. 14  Gbogbo ènìyàn tí Íṣímáẹ́lì sì ti kó lọ ní òǹdè láti Mísípà+ sì bẹ̀rẹ̀ sí yí padà, wọ́n sì padà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Jóhánánì ọmọkùnrin Káréà. 15  Àti ní ti Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà,+ ó sá lọ kúrò níwájú Jóhánánì pẹ̀lú ọkùnrin mẹ́jọ, kí ó lè lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì. 16  Jóhánánì+ ọmọkùnrin Káréà àti gbogbo olórí ẹgbẹ́ ológun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá kó gbogbo àṣẹ́kù àwọn ènìyàn tí wọ́n mú padà wá láti ọ̀dọ̀ Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà, láti Mísípà, lẹ́yìn tí ó ti ṣá Gẹdaláyà+ ọmọkùnrin Áhíkámù balẹ̀, àwọn abarapá ọkùnrin, àwọn ọkùnrin ogun, àti àwọn aya àti àwọn ọmọ kéékèèké àti àwọn òṣìṣẹ́ láàfin, àwọn tí ó mú padà wá láti Gíbéónì. 17  Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lọ, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní ibùwọ̀ Kímúhámù tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ kí wọ́n bàa lè lọ, kí wọ́n sì wọ Íjíbítì,+ 18  nítorí àwọn ará Kálídíà;+ nítorí àyà ti ń fò wọ́n nítorí wọn,+ níwọ̀n bí Íṣímáẹ́lì ọmọkùnrin Netanáyà ti ṣá Gẹdaláyà ọmọkùnrin Áhíkámù balẹ̀,+ ẹni tí ọba Bábílónì fàṣẹ yàn lórí ilẹ̀ náà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé