Jeremáyà 31:1-40

31  “Ní àkókò yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “èmi yóò di Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì; ní tiwọn, wọn yóò di ènìyàn mi.”+  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ olùlàájá láti ọwọ́ idà rí ojú rere ní aginjù,+ nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn láti gba ìsinmi rẹ̀.”+  Láti ibi jíjìnnàréré, Jèhófà fúnra rẹ̀ fara hàn mí, pé: “Ìfẹ́ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni mo fi nífẹ̀ẹ́ rẹ.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fà ọ́.+  Síbẹ̀, èmi yóò tún ọ kọ́,+ a ó sì tún ọ kọ́ ní ti gidi, ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì. Ìwọ yóò ṣì fi ìlù tanboríìnì rẹ ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́, ìwọ yóò sì jáde lọ nínú ijó àwọn tí ń rẹ́rìn-ín.+  Ìwọ yóò ṣì gbin àwọn ọgbà àjàrà sórí àwọn òkè ńlá Samáríà.+ Dájúdájú, àwọn olùgbìn yóò gbìn, wọn yóò sì bẹ̀rẹ̀ sí lò wọ́n.+  Nítorí ọjọ́ kan wà, nígbà tí àwọn alóre ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá Éfúráímù yóò ké jáde ní ti gidi pé, ‘Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a gòkè lọ sí Síónì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa.’”+  Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ kígbe rara sí Jékọ́bù pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀, ẹ sì ké lọ́nà híhan gan-an-ran síbi orí àwọn orílẹ̀-èdè.+ Ẹ kéde rẹ̀ fáyé gbọ́.+ Ẹ bu ìyìn, ẹ sì wí pé, ‘Gba àwọn ènìyàn rẹ, àṣẹ́kù Ísírẹ́lì là, Jèhófà.’+  Kíyè sí i, èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá,+ ṣe ni èmi yóò sì kó wọn jọpọ̀ láti apá jíjìnnàréré jù lọ ní ilẹ̀ ayé.+ Láàárín wọn ni afọ́jú àti èyí tí ó yarọ yóò wà, aboyún àti ẹni tí ó fẹ́ bímọ, gbogbo wọn pa pọ̀.+ Bí ìjọ títóbi ni wọn yóò padà sí ìhín.+  Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún sísun,+ pẹ̀lú ìpàrọwà wọn fún ojú rere ni èmi yóò sì mú wọn wá. Èmi yóò mú wọn rìn lọ sí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní omi,+ ní ọ̀nà tí ó tọ́, nínú èyí tí a kì yóò ti mú wọn kọsẹ̀. Nítorí mo ti di Baba fún Ísírẹ́lì;+ ní ti Éfúráímù, òun ni àkọ́bí mi.”+ 10  Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ sì sọ ọ́ láàárín àwọn erékùṣù jíjìnnàréré,+ pé: “Ẹni tí ó tú Ísírẹ́lì ká ni yóò fúnra rẹ̀ kó o jọpọ̀,+ dájúdájú, òun yóò pa á mọ́ bí olùṣọ́ àgùntàn ti ń ṣe sí agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀.+ 11  Nítorí Jèhófà yóò tún Jékọ́bù+ rà padà ní ti gidi, yóò sì tún un gbà padà kúrò ní ọwọ́ ẹni tí ó lágbára jù ú lọ.+ 12  Dájúdájú, wọn yóò wá, wọn yóò sì fi ìdùnnú ké jáde ní ibi gíga Síónì,+ wọn yóò sì máa tàn yinrin nítorí oore Jèhófà,+ nítorí ọkà àti nítorí wáìnì tuntun+ àti nítorí òróró àti nítorí àwọn ọmọ agbo ẹran àti nítorí àwọn màlúù.+ Ọkàn wọn yóò sì wulẹ̀ dà bí ọgbà tí a bomi rin dáadáa,+ wọn kì yóò sì tún láálàṣí mọ́.”+ 13  “Ní àkókò yẹn, wúńdíá yóò máa yọ̀ nínú ijó, bákàn náà ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin àti àwọn àgbààgbà, gbogbo wọn pa pọ̀.+ Ṣe ni èmi yóò sì yí ọ̀fọ̀ wọn padà di ayọ̀ ńláǹlà, èmi yóò sì tù wọ́n nínú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa yọ̀, kúrò nínú ẹ̀dùn-ọkàn wọn.+ 14  Dájúdájú, èmi yóò fi ọ̀rá tẹ́ ọkàn àwọn àlùfáà lọ́rùn ní kíkún,+ oore mi yóò sì tẹ́ àwọn ènìyàn mi lọ́rùn,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 15  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Ní Rámà,+ a gbọ́ ohùn kan, ìdárò àti ẹkún kíkorò;+ Rákélì+ ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀.+ Ó kọ̀ láti gba ìtùnú nítorí àwọn ọmọ rẹ̀,+ nítorí pé wọn kò sí mọ́.’”+ 16  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “‘Dá ohùn rẹ dúró nínú ẹkún sísun, àti ojú rẹ nínú omijé,+ nítorí èrè wà fún ìgbòkègbodò rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘dájúdájú, wọn yóò sì padà láti ilẹ̀ ọ̀tá.’+ 17  “‘Ìrètí+ sì wà fún ọjọ́ ọ̀la rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘dájúdájú, àwọn ọmọ yóò sì padà sí ìpínlẹ̀ tiwọn.’”+ 18  “Àní mo ti gbọ́ tí Éfúráímù ń kédàárò nípa ara rẹ̀ pé,+ ‘Ìwọ ti tọ́ mi sọ́nà, kí èmi lè gba ìtọ́sọ́nà,+ bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́.+ Mú mi yí padà. Èmi yóò sì yí padà wéréwéré,+ nítorí ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run mi.+ 19  Nítorí pé lẹ́yìn tí mo padà, mo kábàámọ̀;+ lẹ́yìn tí a sì mú mi mọ̀, mo gbá itan mi.+ Ìtìjú bá mi, a sì tún tẹ́ mi lógo,+ nítorí mo ti ru ẹ̀gàn ìgbà èwe mi.’”+ 20  “Ọmọ àtàtà ha ni Éfúráímù jẹ́ sí mi, tàbí ọmọ tí a hùwà sí lọ́nà ìfẹ́ni?+ Nítorí dé àyè tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí i dé, láìkùnà, èmi yóò rántí rẹ̀ síwájú sí i.+ Ìdí nìyẹn tí ìfun mi fi di èyí tí ó ru gùdù fún un.+ Dájúdájú, èmi yóò ṣe ojú àánú sí i,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 21  “Gbé àmì ojú ọ̀nà ró fún ara rẹ. Gbé àwọn òpó àmì kalẹ̀ fún ara rẹ.+ Fi ọkàn-àyà rẹ sí òpópó ọ̀nà, ọ̀nà tí ìwọ yóò gbà lọ.+ Padà wá, ìwọ wúńdíá Ísírẹ́lì. Padà wá sí àwọn ìlú ńlá rẹ wọ̀nyí.+ 22  Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa yà síhìn-ín sọ́hùn-ún,+ ìwọ ọmọbìnrin aláìṣòótọ́?+ Nítorí Jèhófà ti dá ohun tuntun kan ní ilẹ̀ ayé: Àní obìnrin kan yóò pọ̀rẹ̀rẹ̀ yí abarapá ọkùnrin kan ká.” 23  Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Wọn yóò ṣì sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilẹ̀ Júdà àti ní àwọn ìlú ńlá rẹ̀, nígbà tí èmi yóò kó àwọn òǹdè wọn jọ, ‘Kí Jèhófà bù kún ọ,+ ìwọ ibi gbígbé òdodo,+ ìwọ òkè ńlá mímọ́.’+ 24  Inú rẹ̀ sì ni Júdà àti gbogbo àwọn ìlú ńlá rẹ̀ yóò máa jùmọ̀ gbé dájúdájú, àwọn àgbẹ̀ àti àwọn tí ó ṣí lọ pẹ̀lú agbo ẹran ọ̀sìn.+ 25  Nítorí ọkàn tí àárẹ́ mú ni èmi yóò tẹ́ lọ́rùn ní kíkún, olúkúlùkù ọkàn tí ó sì ń láálàṣí ni èmi yóò kún.”+ 26  Lórí èyí ni mo jí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wò; àti ní ti oorun mi, ó dùn mọ́ mi. 27  “Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “ṣe ni èmi yóò gbin irúgbìn tí í ṣe ènìyàn àti irúgbìn tí í ṣe ẹran agbéléjẹ̀ sí ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà.”+ 28  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti wà lójúfò sí wọn+ láti fà tu àti láti bì wó àti láti ya lulẹ̀ àti láti pa run àti láti bàjẹ́,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò wà lójúfò sí wọn láti kọ́ àti láti gbìn,”+ ni àsọjáde Jèhófà. 29  “Ní àwọn ọjọ́ wọnnì, wọn kì yóò tún wí pé, ‘Àwọn baba ni ó jẹ èso àjàrà tí kò pọ́n, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ni eyín kan.’+ 30  Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú nítorí ìṣìnà rẹ̀.+ Ènìyàn èyíkéyìí tí ó bá jẹ èso àjàrà tí kò pọ́n, eyín tirẹ̀ ni yóò kan.” 31  “Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì+ àti ilé Júdà+ dá májẹ̀mú tuntun;+ 32  kì í ṣe èyí tí ó rí bí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo di ọwọ́ wọn mú láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ ‘májẹ̀mú mi èyí tí àwọn fúnra wọn dà,+ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ni ọkọ olówó orí wọn,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 33  “Nítorí èyí ni májẹ̀mú+ tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ọjọ́ wọnnì,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Ṣe ni èmi yóò fi òfin mi sínú wọn,+ inú ọkàn-àyà wọn sì ni èmi yóò kọ ọ́ sí.+ Èmi yóò sì di Ọlọ́run wọn, àwọn fúnra wọn yóò sì di ènìyàn mi.”+ 34  “Olúkúlùkù wọn kì yóò sì tún máa kọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀, àti olúkúlùkù wọn arákùnrin rẹ̀+ pé, ‘Ẹ mọ Jèhófà!’+ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti orí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn àní dé orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn,”+ ni àsọjáde Jèhófà. “Nítorí èmi yóò dárí ìṣìnà wọn jì, ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni èmi kì yóò sì rántí mọ́.”+ 35  Èyí ni ohun tí Jèhófà, Olùfúnni ní oòrùn fún ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,+ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀+ òṣùpá+ àti àwọn ìràwọ̀ fún ìmọ́lẹ̀ ní òru,+ Ẹni tí ń ru òkun sókè kí ìgbì rẹ̀ lè di aláriwo líle,+ Ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ wí: 36  “‘Bí a bá lè mú àwọn ìlànà wọ̀nyí kúrò níwájú mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àwọn tí wọ́n jẹ́ irú-ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú lè ṣíwọ́ jíjẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi nígbà gbogbo.’”+ 37  Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “‘Bí a bá lè díwọ̀n ọ̀run lókè, tí a sì lè wá ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀ kàn,+ èmi fúnra mi pẹ̀lú lè kọ gbogbo irú-ọmọ Ísírẹ́lì pátá ní tìtorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 38  “Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,” ni àsọjáde Jèhófà, “ìlú ńlá náà ni a ó sì kọ́+ fún Jèhófà láti Ilé Gogoro Hánánélì+ dé Ẹnubodè Igun.+ 39  Síbẹ̀, okùn ìwọ̀n+ yóò jáde lọ tààrà ní ti gidi sí òkè kékeré Gárébù dájúdájú, yóò sì lọ yí ká dé Góà. 40  Àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ àwọn òkú+ àti ti eérú ọlọ́ràá,+ àti gbogbo ilẹ̀ onípele títẹ́jú títí dé àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kídírónì,+ títí lọ dé igun Ẹnubodè Ẹṣin,+ síha yíyọ oòrùn, yóò jẹ́ ohun mímọ́ lójú Jèhófà.+ A kì yóò fà á tu, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò ya á lulẹ̀ mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé