Jeremáyà 2:1-37
2 Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ̀ mí wá,+ pé:
2 “Lọ, kí o sì ké jáde ní etí Jerúsálẹ́mù, pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà wí:+ “Mo rántí dáadáa, níhà ọ̀dọ̀ rẹ, inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ìgbà èwe rẹ,+ ìfẹ́ tí o ní nígbà tí a ń fẹ́ ọ sọ́nà láti gbé ọ níyàwó,+ bí o ti ń tọ̀ mí lẹ́yìn ní aginjù, ní ilẹ̀ tí a kò fún irúgbìn sí.+
3 Ohun mímọ́ ni Ísírẹ́lì jẹ́ lójú Jèhófà,+ èso àkọ́so fún Un.”’+ ‘Àwọn tí ó bá jẹ ẹ́ run yóò sọ ara wọn di ẹlẹ́bi.+ Àní ìyọnu àjálù yóò já lù wọ́n,’ ni àsọjáde Jèhófà.”+
4 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ilé Jékọ́bù,+ àti gbogbo ẹ̀yin ìdílé ti ilé Ísírẹ́lì.+
5 Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Kí ni àwọn baba yín rí nínú mi tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu,+ tí wọ́n fi jìnnà réré sí mi,+ tí wọ́n sì ń tọ òrìṣà asán lẹ́yìn,+ tí àwọn fúnra wọn sì di asán?+
6 Wọn kò sì sọ pé, ‘Jèhófà dà, Ẹni tí ó mú wa gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì,+ Ẹni tí ó mú wa rìn la aginjù kọjá, la ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀+ àti kòtò kọjá, la ilẹ̀ aláìlómi+ àti ibú òjìji kọjá,+ la ilẹ̀ tí ènìyàn kankan kò gbà kọjá, tí ará ayé kankan kò sì gbé?’
7 “Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọgbà igi eléso, láti máa jẹ èso rẹ̀ àti àwọn ohun rere rẹ̀.+ Ṣùgbọ́n ẹ wọlé wá, ẹ sì sọ ilẹ̀ mi di ẹlẹ́gbin; ẹ sì sọ ogún tèmi di ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí.+
8 Àwọn àlùfáà pàápàá kò sọ pé, ‘Jèhófà dà?’+ Àwọn ẹni náà tí ń mú òfin lò kò sì mọ̀ mí;+ àwọn olùṣọ́ àgùntàn pàápàá sì ré ìlànà mi kọjá,+ àní àwọn wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Báálì,+ àwọn tí kò sì lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan ni wọ́n tọ̀ lẹ́yìn.+
9 “‘Nítorí náà, èmi yóò bá yín fà á síwájú sí i,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi yóò sì bá àwọn ọmọ ọmọ yín fà á.’+
10 “‘Ṣùgbọ́n ẹ kọjá lọ sí ilẹ̀ etí òkun àwọn ará Kítímù+ kí ẹ sì wò ó. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ ránṣẹ́ lọ sí Kídárì pàápàá,+ kí ẹ sì fún un ní àkànṣe àfiyèsí, kí ẹ sì rí i bóyá ohunkóhun bí èyí ti ṣẹlẹ̀ rí.+
11 Orílẹ̀-èdè kan ha ti ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ọlọ́run,+ àní fún àwọn tí kì í ṣe ọlọ́run bí?+ Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tèmi ti ṣe pàṣípààrọ̀ ògo mi fún ohun tí kò lè ṣe wọ́n láǹfààní kankan.+
12 Ẹ wo èyí sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì, ẹ̀yin ọ̀run; ẹ sì dìde gàn-ùn gàn-ùn bí irun ti ń dìde nínú ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ńláǹlà,’ ni àsọjáde Jèhófà,+
13 ‘nítorí ohun búburú méjì ni àwọn ènìyàn mi ṣe: Wọ́n ti fi èmi pàápàá,+ orísun omi ààyè sílẹ̀,+ láti gbẹ́ àwọn ìkùdu fún ara wọn, àwọn ìkùdu fífọ́, tí kò lè gba omi dúró.’
14 “‘Ìránṣẹ́ ha ni Ísírẹ́lì,+ tàbí ẹrú tí a bí nínú agbo ilé? Èé ṣe tí ó fi wá jẹ́ ohun tí a piyẹ́?
15 Àwọn ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ké ramúramù mọ́ ọn;+ wọ́n ti na ohùn wọn jáde.+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun ìyàlẹ́nu. A ti sọ iná sí àwọn ìlú ńlá rẹ̀, tí kò fi ní àwọn olùgbé kankan.+
16 Àní àwọn ọmọ Nófì+ àti àwọn Tápánésì+ pàápàá ń fi ọ ṣe oúnjẹ jẹ ní àtàrí rẹ.+
17 Èyí ha kọ́ ni ohun tí o bẹ̀rẹ̀ sí ṣe sí ara rẹ nípa fífi Jèhófà Ọlọ́run rẹ sílẹ̀+ ní àkókò tí ó ń mú ọ rìn lójú ọ̀nà?+
18 Wàyí o, ìdàníyàn wo ni ó yẹ kí o ní fún ọ̀nà Íjíbítì,+ láti mu omi Ṣíhórì?+ Ìdàníyàn wo sì ni ó yẹ kí o ní fún ọ̀nà Ásíríà,+ láti mu omi Odò?
19 Ó yẹ kí ìwà búburú rẹ tọ́ ọ sọ́nà,+ kí ìwà àìṣòótọ́ rẹ sì fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà.+ Mọ̀, nígbà náà, kí o sì rí i pé fífi tí o fi Jèhófà Ọlọ́run rẹ sílẹ̀ jẹ́ ohun búburú tí ó sì korò,+ ìwọ kò sì ní ìbẹ̀rùbojo fún mi,’+ ni àsọjáde Olúwa Ọba Aláṣẹ,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.
20 “‘Nítorí pé ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn ni mo ti ṣẹ́ àjàgà rẹ sí wẹ́wẹ́;+ mo fa ọ̀já rẹ já. Ṣùgbọ́n, ìwọ wí pé: “Èmi kì yóò sìn,” nítorí pé orí gbogbo òkè kékeré gíga àti abẹ́ olúkúlùkù igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ ni ìwọ dùbúlẹ̀ gbalaja sí,+ tí o ń fi ara rẹ ṣe iṣẹ́ kárùwà.+
21 Ní tèmi, mo ti gbìn ọ́ bí ààyò àjàrà pupa,+ gbogbo rẹ̀ irúgbìn tòótọ́. Báwo ni a ṣe yí ọ padà di ọ̀mùnú àjàrà ilẹ̀ òkèèrè tí ó jẹrà bàjẹ́ sí mi?’+
22 “‘Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá tilẹ̀ fi ákáláì wẹ̀, tí o sì mú ìwọ̀n ọṣẹ ìfọṣọ púpọ̀ fún ara rẹ,+ dájúdájú, ìṣìnà rẹ yóò jẹ́ àbààwọ́n níwájú mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ.
23 Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Èmi kò sọ ara mi di ẹlẹ́gbin.+ Èmi kò tọ Báálì lẹ́yìn’?+ Wo ọ̀nà rẹ ní àfonífojì.+ Fiyè sí ohun tí o ti ṣe. Ẹgbọrọ abo ràkúnmí yíyára tí ń sálọ-sábọ̀ jàbàjàbà ní ọ̀nà rẹ̀;
24 kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà+ tí aginjù ti mọ́ lára, nínú ìfàsí ọkàn rẹ̀, tí ń fa ẹ̀fúùfù símú;+ nígbà tí ó bá tó àkókò fún un láti gùn, ta ni ó lè dá a padà? Gbogbo àwọn tí ń wá a kì yóò kó àárẹ̀ bá ara wọn. Wọn yóò wá a rí ní oṣù rẹ̀.
25 Fa ẹsẹ̀ rẹ sẹ́yìn kúrò nínú àìwọ bàtà, àti ọ̀fun rẹ kúrò nínú òùngbẹ.+ Ṣùgbọ́n o bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Ìrètí kò sí!+ Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n mo ti kó sínú ìfẹ́ pẹ̀lú àwọn àjèjì,+ àwọn ni èmi yóò sì máa tọ̀ lẹ́yìn.’+
26 “Bí ojú ṣe máa ń ti olè nígbà tí a bá mú un, bẹ́ẹ̀ ni ojú ti àwọn ti ilé Ísírẹ́lì,+ àwọn, àwọn ọba wọn, àwọn ọmọ aládé wọn àti àwọn àlùfáà wọn àti àwọn wòlíì wọn.+
27 Wọ́n ń sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’+ àti fún òkúta pé, ‘Ìwọ fúnra rẹ ni o bí mi.’ Ṣùgbọ́n wọ́n yí ẹ̀yìn ọrùn sí mi, kì í sì í ṣe ojú wọn.+ Ní àkókò ìyọnu àjálù wọn, wọn yóò sì wí pé, ‘Dìde, kí o sì gbà wá là!’+
28 “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́run rẹ tí o ti ṣe fún ara rẹ dà?+ Kí wọ́n dìde bí wọ́n bá lè gbà ọ́ là ní àkókò ìyọnu àjálù rẹ.+ Nítorí pé bí iye ìlú ńlá rẹ ti pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni iye àwọn ọlọ́run rẹ ti pọ̀ tó, ìwọ Júdà.+
29 “‘Èé ṣe tí ẹ fi ń bá mi fà á?+ Èé ṣe tí ẹ̀yin, àní gbogbo yín, fi ré ìlànà mi kọjá?’+ ni àsọjáde Jèhófà.
30 Lásán ni mo kọlu àwọn ọmọ yín.+ Wọn kò tẹ́wọ́ gba ìbáwí rárá.+ Idà yín ti jẹ àwọn wòlíì yín run, bí kìnnìún tí ń fa ìparun.+
31 Ìran yìí, ẹ fúnra yín wo ọ̀rọ̀ Jèhófà.+
“Mo ha ti di aginjù lásán lójú Ísírẹ́lì+ tàbí ilẹ̀ òkùnkùn biribiri? Èé ṣe tí àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ènìyàn mi fi wí pé, ‘A ti rìn kiri. A kì yóò wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́’?+
32 Wúńdíá ha lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ bí, kí ìyàwó sì gbàgbé ọ̀já ìgbàyà rẹ̀? Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi—wọ́n ti gbàgbé mi fún àwọn ọjọ́ tí kò níye.+
33 “Èé ṣe tí ìwọ, obìnrin, fi mú ọ̀nà rẹ sunwọ̀n sí i láti wá ìfẹ́? Nítorí náà, ẹ̀kọ́ àwọn ohun búburú ni o tún fi kọ́ àwọn ọ̀nà rẹ.+
34 Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ti rí àmì ẹ̀jẹ̀ ọkàn+ àwọn òtòṣì aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ nínú ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ.+ Kì í ṣe lẹ́nu fífọ́lé ni mo ti rí i, bí kò ṣe lára gbogbo ìwọ̀nyí.+
35 “Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Mo ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀. Dájúdájú, ìbínú rẹ̀ ti yí padà kúrò lórí mi.’+
“Kíyè sí i, èmi yóò wọnú ìjà pẹ̀lú rẹ ní tìtorí ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’+
36 Èé ṣe tí o fi ka yíyí ọ̀nà rẹ padà sí aláìjámọ́ nǹkan kan rárá?+ Ojú yóò tì ọ́ nítorí Íjíbítì pẹ̀lú,+ gan-an gẹ́gẹ́ bí ojú ti tì ọ́ nítorí Ásíríà.+
37 Fún ìdí yìí pẹ̀lú, ìwọ yóò káwọ́ lérí jáde lọ,+ nítorí pé Jèhófà ti kọ àwọn ohun àgbọ́kànlé rẹ, ìwọ kì yóò sì ní àṣeyọrí sí rere kankan pẹ̀lú wọn.”

