Jeremáyà 17:1-27
17 “Ẹ̀ṣẹ̀ Júdà ni a ti fi kálàmù irin+ kọ sílẹ̀. A ti fi ṣóńṣó dáyámọ́ǹdì fín in sára wàláà ọkàn-àyà wọn,+ àti sára ìwo pẹpẹ wọn,+
2 nígbà tí àwọn ọmọ wọn rántí pẹpẹ wọn àti òpó ọlọ́wọ̀ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ igi gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, lórí àwọn òkè kéékèèké gíga,+
3 lórí àwọn òkè ńláńlá nínú pápá. Ohun àmúṣọrọ̀ rẹ, gbogbo ìṣúra rẹ, ni èmi yóò fi fúnni fún ìpiyẹ́ lásán+—àwọn ibi gíga rẹ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ jákèjádò gbogbo ìpínlẹ̀ rẹ.+
4 Ìwọ, àní láti inú ìdánúṣe ara rẹ, jọ̀wọ́ ohun ìní àjogúnbá rẹ tí mo fi fún ọ lọ́wọ́.+ Èmi pẹ̀lú yóò mú kí o sin àwọn ọ̀tá rẹ ní ilẹ̀ tí o kò mọ̀;+ nítorí bí iná, a ti tanná ràn yín nínú ìbínú mi.+ Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni yóò máa jó.”
5 Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ègún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ará ayé,+ tí ó sì wá fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀,+ tí ọkàn-àyà rẹ̀ sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.+
6 Dájúdájú, òun yóò sì dà bí igi tí ó wà ní òun nìkan ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀, kí yóò sì rí i nígbà tí ohun rere bá dé;+ ṣùgbọ́n òun yóò máa gbé ní ibi gbígbẹ hán-ún hán-ún nínú aginjù, nínú ilẹ̀ iyọ̀ tí kò ṣeé gbé.+
7 Ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí Jèhófà di ìgbọ́kànlé rẹ̀.+
8 Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá omi, tí ó na gbòǹgbò rẹ̀ tààrà lọ sẹ́bàá ipadò; òun kì yóò sì rí i nígbà tí ooru bá dé, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé yóò di èyí tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ti gidi.+ Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀,+ òun kì yóò sì ṣàníyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò dẹ́kun mímú èso jáde.
9 “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà.+ Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?
10 Èmi, Jèhófà, ń wá inú ọkàn-àyà,+ mo sì ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín,+ àní láti fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà rẹ̀,+ ní ìbámu pẹ̀lú èso ìbálò rẹ̀.+
11 Bí àparò ọhẹhẹ tí ó ti kó ohun tí kò yé jọpọ̀ ni ẹni tí ń kó ọrọ̀ jọ, ṣùgbọ́n tí kì í ṣe lọ́nà ìdájọ́ òdodo.+ Ní ìdajì àwọn ọjọ́ rẹ̀ ni yóò fi wọ́n sílẹ̀,+ àti ní paríparí rẹ̀ yóò já sí òpònú.”+
12 Ìtẹ́ ológo wà ní ibi gíga lókè láti ìbẹ̀rẹ̀;+ ibẹ̀ ni ibùjọsìn wa.+
13 Jèhófà, ìrètí Ísírẹ́lì,+ ìtìjú yóò bá gbogbo àwọn tí ń fi ọ́ sílẹ̀.+ Àwọn tí ń pẹ̀yìn dà kúrò lọ́dọ̀ mi+ ni a ó kọrúkọ wọn sílẹ̀, àní ní ilẹ̀ ayé, nítorí wọ́n ti fi Jèhófà, orísun omi ààyè sílẹ̀.+
14 Mú mi lára dá, Jèhófà, ara mi yóò sì dá.+ Gbà mí là, èmi yóò sì rí ìgbàlà;+ nítorí ìwọ ni ìyìn mi.+
15 Wò ó! Àwọn kan wà tí wọ́n ń sọ fún mi pé: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà dà?+ Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ó wà.”
16 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kò ṣe kánkán láti má ṣe jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, èmi kò sì fi ìfàsí-ọkàn hàn fún ọjọ́ ìgbékútà. Ìwọ fúnra rẹ mọ gbólóhùn ètè mi; ní iwájú rẹ ni ó ti wáyé.
17 Má di ohun ìjayà fún mi.+ Ìwọ ni ibi ìsádi mi ní ọjọ́ ìyọnu àjálù.+
18 Jẹ́ kí ìtìjú bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi,+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ìtìjú kankan bá èmi fúnra mi.+ Kí ó jẹ́ àwọn ni ìpayà yóò bá, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ìpayà bá èmi fúnra mi. Mú ọjọ́ ìyọnu àjálù wá sórí wọn,+ kí o sì fi àní ìlọ́po méjì ìwópalẹ̀ fọ́ wọn.+
19 Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: “Lọ, kí o sì dúró ní ẹnubodè àwọn ọmọ ènìyàn náà, èyí tí àwọn ọba Júdà ń gbà wọlé àti èyí tí wọ́n ń gbà jáde, àti ní gbogbo ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.+
20 Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin ọba Júdà àti gbogbo Júdà àti gbogbo ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù, tí ẹ ń gba ẹnubodè wọ̀nyí wọlé.+
21 Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: “Ẹ ṣọ́ra fún ọkàn yín,+ ẹrù èyíkéyìí tí ẹ óò gbé gba àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù wọlé ni kí ẹ má ṣe gbé ní ọjọ́ sábáàtì.+
22 Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbé ẹrù kankan jáde láti inú ilé yín ní ọjọ́ sábáàtì; ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá.+ Kí ẹ sì sọ ọjọ́ sábáàtì di mímọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín;+
23 ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ọrùn wọn le+ kí wọ́n má bàa gbọ́, kí wọ́n má sì gba ìbáwí.”’+
24 “‘“Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, bí ẹ bá ṣègbọràn sí mi délẹ̀délẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “láti má ṣe gbé ẹrù kankan gba àwọn ẹnubodè ìlú ńlá yìí wọlé ní ọjọ́ sábáàtì+ àti láti sọ ọjọ́ sábáàtì di mímọ́ nípa ṣíṣàìṣe iṣẹ́ èyíkéyìí nínú rẹ̀,+
25 dájúdájú, àwọn ọba pẹ̀lú àwọn ọmọ aládé,+ tí wọ́n jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì,+ tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin, àwọn àti àwọn ọmọ aládé wọn, àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, yóò gba àwọn ẹnubodè ìlú ńlá yìí wọlé pẹ̀lú; dájúdájú, a óò máa gbé inú ìlú ńlá yìí fún àkókò tí ó lọ kánrin.
26 Ní ti gidi, àwọn ènìyàn yóò sì wá láti àwọn ìlú ńlá Júdà àti láti àyíká Jerúsálẹ́mù àti láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ àti láti ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀+ àti láti ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá+ àti láti Négébù,+ ní mímú odindi ọrẹ ẹbọ sísun+ àti ẹbọ+ àti ọrẹ ẹbọ ọkà+ àti oje igi tùràrí+ wá àti ní mímú ẹbọ ìdúpẹ́ wá sínú ilé Jèhófà.+
27 “‘“Ṣùgbọ́n bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí mi nípa sísọ ọjọ́ sábáàtì di mímọ́ àti nípa ṣíṣàìgbé ẹrù kankan,+ ṣùgbọ́n tí ẹ gbé e wọlé gba ti àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù ní ọjọ́ sábáàtì, ṣe ni èmi yóò ti iná bọ àwọn ẹnubodè rẹ̀ pẹ̀lú,+ dájúdájú, yóò jẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé Jerúsálẹ́mù run,+ a kì yóò sì pa iná náà.”’”+