Jeremáyà 11:1-23

11  Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremáyà wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, pé: 2  “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí! “Kí o sì sọ+ ọ́ fún àwọn ènìyàn Júdà àti fún àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, 3  kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: “Ègún ni fún ènìyàn tí kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí,+ 4  èyí tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò nínú ìléru irin,+ pé, ‘Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi, kí ẹ sì ṣe àwọn nǹkan ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún yín;+ dájúdájú, ẹ ó sì di ènìyàn mi, èmi alára yóò sì di Ọlọ́run yín,+ 5  láti lè mú ìbúra tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ,+ láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin,+ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní òní yìí.’”’” Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn pé: “Àmín, Jèhófà.” 6  Jèhófà sì ń bá a lọ láti sọ fún mi pé: “Pòkìkí gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù,+ pé, ‘Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì pa wọ́n mọ́.+ 7  Nítorí mo ṣí àwọn baba ńlá yín létí lọ́nà tí ó wúwo rinlẹ̀ ní ọjọ́ tí mo ń mú wọn gòkè bọ̀ láti ilẹ̀ Íjíbítì+ àti títí di ọjọ́ òní yìí, mo ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń ṣí wọn létí, pé: “Ẹ ṣègbọràn sí ohùn mi.”+ 8  Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dẹ etí wọn sílẹ̀,+ ṣùgbọ́n wọ́n ń rìn ṣáá, olúkúlùkù nínú agídí ọkàn-àyà búburú wọn;+ nítorí náà, mo mú gbogbo ọ̀rọ̀ inú májẹ̀mú yìí wá sórí wọn, èyí tí mo pa láṣẹ fún wọn láti pa mọ́, ṣùgbọ́n tí wọn kò pa mọ́.’” 9  Síwájú sí i, Jèhófà sọ fún mi pé: “A ti rí tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun láàárín àwọn ènìyàn Júdà àti láàárín àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.+ 10  Wọ́n ti padà sínú àwọn ìṣìnà àwọn baba ńlá wọn,+ àwọn ti àkọ́kọ́, tí ó kọ̀ láti ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ mi, ṣùgbọ́n tí àwọn fúnra wọn ti tọ àwọn ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn láti sìn wọ́n.+ Ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà ti da májẹ̀mú mi, èyí tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.+ 11  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù+ wá sórí wọn, tí wọn kò ní lè bọ́ nínú rẹ̀;+ dájúdájú, wọn yóò sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n èmi kì yóò fetí sí wọn.+ 12  Àwọn ìlú ńlá Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù yóò sì ní láti lọ ké pe àwọn ọlọ́run tí wọ́n ń rú èéfín ẹbọ sí,+ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n tí kì yóò mú ìgbàlà wá fún wọn rárá ní àkókò ìyọnu àjálù wọn.+ 13  Nítorí àwọn ọlọ́run rẹ ti pọ̀ bí àwọn ìlú ńlá rẹ ti pọ̀ tó, ìwọ Júdà;+ àwọn pẹpẹ tí ó sì pọ̀ bí àwọn ojú pópó Jerúsálẹ́mù ti pọ̀ tó ni ẹ̀yin ti mọ fún ohun ìtìjú,+ àwọn pẹpẹ láti máa fi rú èéfín ẹbọ sí Báálì.’+ 14  “Àti ní ti ìwọ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn ènìyàn yìí, má sì ṣe gbé ohùn igbe ìpàrọwà tàbí àdúrà sókè nítorí wọn,+ nítorí èmi kò ní fetí sílẹ̀ ní àkókò tí wọ́n bá ń ké pè mí nípa ìyọnu àjálù wọn.+ 15  “Iṣẹ́ wo ni olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n ń ṣe nínú ilé mi,+ tí púpọ̀ nínú wọn fi ní láti ṣe ohun yìí,+ ète ibi?+ Wọn yóò ha sì fi ẹran mímọ́ mú kí ó ré ọ kọjá bí,+ nígbà tí ìyọnu àjálù rẹ bá dé? Ní àkókò yẹn, ìwọ yóò ha yọ ayọ̀ ńláǹlà bí?+ 16  ‘Igi ólífì gbígbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, tí ó rẹwà nínú èso àti ní ìrísí,’ ni Jèhófà ti pe orúkọ rẹ.+ Pẹ̀lú ìró ìkéramúramù tí ó pọ̀, ó ti fi iná jó o, wọ́n sì ti ṣẹ́ àwọn ẹ̀ka rẹ̀.+ 17  “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀, Ẹni tí ó gbìn ọ́,+ sì ti sọ̀rọ̀ ìyọnu àjálù lòdì sí ọ ní tìtorí ìwà búburú ilé Ísírẹ́lì+ àti ilé Júdà tí wọ́n ti hù níhà ọ̀dọ̀ wọn láti mú mi bínú ní rírú èéfín ẹbọ sí Báálì.”+ 18  Jèhófà tìkára rẹ̀ sì ti sọ fún mi kí n lè mọ̀. Ní àkókò yẹn, o mú mi rí ìbálò wọn.+ 19  Mo sì dà bí akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, èyí tí ó ṣe tímọ́tímọ́, tí a mú wá fún pípa,+ èmi kò sì mọ̀ pé èmi ni wọ́n pète-pèrò lòdì sí pé:+ “Ẹ jẹ́ kí a run igi náà pẹ̀lú oúnjẹ rẹ̀, kí a sì ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè,+ kí a má bàa rántí orúkọ rẹ̀ gan-an mọ́.” 20  Ṣùgbọ́n Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ń fi òdodo ṣe ìdájọ́;+ ó ń ṣàyẹ̀wò kíndìnrín àti ọkàn-àyà.+ Jẹ́ kí n rí ẹ̀san rẹ lórí wọn, nítorí ìwọ ni mo ṣí ẹjọ́ mi lábẹ́ òfin payá fún.+ 21  Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí lòdì sí àwọn ènìyàn Ánátótì+ tí wọ́n ń wá ọkàn rẹ, pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ Jèhófà,+ kí o má bàa kú ní ọwọ́ wa”; 22  nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Kíyè sí i, èmi yóò yí àfiyèsí mi sí wọn. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò tipa idà kú.+ Àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn yóò tipa ìyàn kú.+ 23  Kì yóò sì sí àṣẹ́kù kankan fún wọn, nítorí èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí àwọn ènìyàn Ánátótì,+ ní ọdún ti a óò fún wọn ní àfiyèsí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé