Jónà 2:1-10
2 Nígbà náà ni Jónà gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja+ náà,
2 ó sì wí pé:“Láti inú wàhálà mi ni mo ti ké pe Jèhófà,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí dá mi lóhùn.+Láti inú ikùn Ṣìọ́ọ̀lù ni mo ti kígbe fún ìrànlọ́wọ́.+Ìwọ gbọ́ ohùn mi.+
3 Nígbà tí ìwọ sọ mi sí ibú, sí àárín òkun gbalasa,+Nígbà náà, àní odò kan yí mi ká.Gbogbo ìrugùdù omi rẹ tí ń fọ́n ká di ìfóófòó àti àwọn ìgbì rẹ—wọ́n kọjá lórí mi.+
4 Àti ní tèmi, mo sọ pé, ‘A ti lé mi kúrò níwájú rẹ!+Báwo ni èmi yóò ṣe tún lè tẹjú mọ́ tẹ́ńpìlì+ mímọ́ rẹ?’
5 Omi ká mi mọ́ títí lọ dé ọkàn;+ ibú omi ń bá a nìṣó ní kíká mi mọ́ yí ká.A fi èpò wé mi ní orí.
6 Mo sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá.Ní ti ilẹ̀ ayé, àwọn ọ̀pá ìdábùú rẹ̀ wà lórí mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.Ṣùgbọ́n o tẹ̀ síwájú láti mú ìwàláàyè mi gòkè wá láti inú kòtò, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi.+
7 Nígbà tí àárẹ̀ mú ọkàn mi nínú mi,+ Jèhófà ni Ẹni tí mo rántí.+Nígbà náà ni àdúrà mi wọlé wá sọ́dọ̀ rẹ, sínú tẹ́ńpìlì+ mímọ́ rẹ.
8 Ní ti àwọn tí ń ṣàkíyèsí àwọn òrìṣà àìjóòótọ́, wọ́n fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ ti ara wọn sílẹ̀.
9 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò fi ohùn ìdúpẹ́ rúbọ sí ọ.+Èmi yóò san+ ohun ti mo jẹ́jẹ̀ẹ́. Ti Jèhófà ni ìgbàlà.”+
10 Nígbà tí ó ṣe, Jèhófà pàṣẹ fún ẹja náà, bẹ́ẹ̀ ni ó pọ Jónà sórí ilẹ̀ gbígbẹ.+

