Jóṣúà 5:1-15

5  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gbàrà tí gbogbo ọba Ámórì,+ tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, àti gbogbo ọba àwọn ọmọ Kénáánì,+ tí ó wà lẹ́bàá òkun, gbọ́ pé Jèhófà ti gbẹ omi Jọ́dánì táútáú níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí wọ́n fi ré kọjá, ìgbà náà ni ọkàn-àyà wọn bẹ̀rẹ̀ sí domi,+ kò sì sí ẹ̀mí kankan nínú wọn mọ́ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+  Ní àkókò yẹn gan-⁠an, Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: “Fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ fún ara rẹ, kí o sì dádọ̀dọ́+ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kan sí i, ní ìgbà kej ì .”  Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, Jóṣúà fi akọ òkúta ṣe àwọn ọ̀bẹ fún ara rẹ̀, ó sì dádọ̀dọ́ àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì ní Gibeati-háárálótì.+  Èyí sì ni ìdí tí Jóṣúà fi ṣe ìdádọ̀dọ́ náà: gbogbo ènìyàn tí ó jáde kúrò ní Íjíbítì, àwọn ọkùnrin, gbogbo ọkùnrin ogun, ti kú+ nínú aginjù ní ojú ọ̀nà nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì.  Nítorí gbogbo ènìyàn tí ó jáde kúrò níbẹ̀ ni a dádọ̀dọ́ wọn, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn tí a bí nínú aginjù ní ojú ọ̀nà nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì ni a kò tí ì dádọ̀dọ́ wọn.  Nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rìn fún ogój ì ọdún+ nínú aginjù, títí gbogbo àwùjọ ọkùnrin ogun tí wọ́n jáde kúrò ní Íjíbítì, tí wọn kò fetí sí ohùn Jèhófà, fi wá sí òpin rẹ̀, àwọn tí Jèhófà búra fún pé òun kì yóò jẹ́ kí wọ́n rí ilẹ̀ náà+ láé, èyí tí Jèhófà ti búra fún àwọn baba ńlá wọn láti fi fún wa,+ ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.+  Àwọn ọmọkùnrin wọn ni ó sì gbé dìde dípò wọn.+ Àwọn wọ̀nyí ni Jóṣúà dádọ̀dọ́ wọn, nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìdádọ̀dọ́, nítorí wọn kò tí ì dádọ̀dọ́ wọn ní ojú ọ̀nà.  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n parí dídádọ̀dọ́ gbogbo àwùjọ náà, wọ́n ń bá a nìṣó ní jíjókòó ní àyè wọn ní ibùdó títí wọ́n fi sàn.+  Nígbà náà ni Jèhófà wí fún Jóṣúà pé: “Lónìí, èmi ti yí ẹ̀gàn Íjíbítì kúrò lórí yín.”+ Nítorí náà, orúkọ ibẹ̀ yẹn ni a wá pè ní Gílígálì+ títí di òní yìí. 10  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ń bá a lọ láti dó sí Gílígálì, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù,+ ní alẹ́, lórí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ Jẹ́ríkò. 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ nínú àmújáde ilẹ̀ náà ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé ìrékọjá, àwọn àkàrà aláìwú+ àti àwọn àyangbẹ ọkà, ní ọjọ́ yìí kan náà. 12  Mánà wá kásẹ̀ nílẹ̀ ní ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e nígbà tí wọ́n ti jẹ nínú àmújáde ilẹ̀ náà, mánà kò sì wáyé mọ́ rárá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ nínú èso ilẹ̀ Kénáánì ní ọdún yẹn.+ 13  Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí Jóṣúà wà léti Jẹ́ríkò, ó gbé ojú rẹ̀ sókè, sì wò ó, níbẹ̀ ni ọkùnrin+ kan sì dúró sí ní iwájú rẹ̀ ti òun ti idà rẹ̀ tí ó fà yọ ní ọwọ́ rẹ̀.+ Nítorí náà, Jóṣúà rìn tọ̀ ọ́ lọ, ó sì wí fún un pé: “Ṣé àwa ni o wà fún tàbí fún àwọn elénìní wa?” 14  Ó fèsì pé: “Rárá, ṣùgbọ́n èmi​—⁠gẹ́gẹ́ bí olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà ni mo ṣe wá+ nísinsìnyí.” Pẹ̀lú ìyẹn, Jóṣúà dojú bolẹ̀, ó sì wólẹ̀,+ ó sì wí fún un pé: “Kí ni olúwa mi ń sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀?” 15  Ní tirẹ̀, ọmọ aládé ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé orí ibi tí ìwọ dúró lé yìí jẹ́ mímọ́.” Ní kíá, Jóṣúà ṣe bẹ́ẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé