Jóṣúà 12:1-24

12  Wàyí o, ìwọ̀nyí ni àwọn ọba ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn lẹ́yìn náà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì níhà yíyọ oòrùn,+ láti àfonífoj ì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì+ dé Òkè Ńlá Hámónì+ àti gbogbo Árábà+ níhà yíyọ oòrùn:  Síhónì+ ọba àwọn Ámórì, tí ń gbé Hẹ́ṣíbónì,+ tí ó ń ṣàkóso láti Áróérì,+ èyí tí ó wà ní bèbè àfonífoj ì olójú ọ̀gbàrá ti Áánónì,+ àti ní àárín àfonífoj ì olójú ọ̀gbàrá náà, àti ààbọ̀ Gílíádì títí dé àfonífoj ì olójú ọ̀gbàrá ti Jábókù,+ ààlà àwọn ọmọ Ámónì,  àti Árábà+ títí dé òkun Kínérétì+ níhà ìlà-oòrùn àti títí dé òkun Árábà, Òkun Iyọ̀,+ níhà ìlà-oòrùn sí ìhà Bẹti-jẹ́ṣímótì+ àti sí ìhà gúúsù lábẹ́ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.+  Àti ní ìpínlẹ̀ Ógù+ ọba Báṣánì, lára ohun tí ó ṣẹ́ kù lára Réfáímù,+ tí ń gbé ní Áṣítárótì+ àti Édíréì,+  tí ó sì ṣàkóso ní Òkè Ńlá Hámónì+ àti ní Sálékà àti ní gbogbo Báṣánì,+ títí dé ààlà àwọn ará Géṣúrì+ àti àwọn ará Máákátì+ àti ààbọ̀ Gílíádì, níhà ìpínlẹ̀ Síhónì+ ọba Hẹ́ṣíbónì.+  Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni ó ṣẹ́gun wọn,+ lẹ́yìn èyí tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà fi ibẹ̀ fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì+ àti àwọn ọmọ Gádì+ àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè+ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.  Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jọ́dánì níhà ìwọ̀-oòrùn, láti Baali-gádì+ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífoj ì Lẹ́bánónì+ títí dé Òkè Ńlá Hálákì,+ èyí tí ó lọ dé Séírì,+ lẹ́yìn èyí, Jóṣúà fi í fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín ilẹ̀ ìní wọn,+  ní ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá àti Ṣẹ́fẹ́là àti ní Árábà àti ní àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àti ní aginjù àti ní Négébù+​—⁠àwọn ọmọ Hétì, àwọn Ámórì+ àti àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Híf ì àti àwọn ará Jébúsì:+  Ọba Jẹ́ríkò,+ ọ̀kan; ọba Áì,+ èyí tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tẹ́lì, ọ̀kan; 10  ọba Jerúsálẹ́mù,+ ọ̀kan; ọba Hébúrónì,+ ọ̀kan; 11  ọba Jámútì,+ ọ̀kan; ọba Lákíṣì,+ ọ̀kan; 12  ọba Ẹ́gílónì,+ ọ̀kan; ọba Gésérì,+ ọ̀kan; 13  ọba Débírì,+ ọ̀kan; ọba Gédérì, ọ̀kan; 14  ọba Hóómà, ọ̀kan; ọba Árádì, ọ̀kan; 15  ọba Líbínà,+ ọ̀kan; ọba Ádúlámù, ọ̀kan; 16  ọba Mákédà,+ ọ̀kan; ọba Bẹ́tẹ́lì,+ ọ̀kan; 17  ọba Tápúà, ọ̀kan; ọba Héfà,+ ọ̀kan; 18  ọba Áfékì, ọ̀kan; ọba Lasiṣárónì, ọ̀kan; 19  ọba Mádónì,+ ọ̀kan; ọba Hásórì,+ ọ̀kan; 20  ọba Ṣimuroni-mérónì, ọ̀kan; ọba Ákíṣáfù,+ ọ̀kan; 21  ọba Táánákì, ọ̀kan; ọba Mẹ́gídò,+ ọ̀kan; 22  ọba Kédéṣì, ọ̀kan; ọba Jókínéámù+ ní Kámẹ́lì, ọ̀kan; 23  ọba Dórì lórí ọ̀wọ́ àwọn òkè ńlá Dórì,+ ọ̀kan; ọba Góíímù ní Gílígálì, ọ̀kan; 24  ọba Tírísà, ọ̀kan;gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé