Jóòbù 7:1-21

7  “Òpò àpàpàǹdodo+ kò ha sí fún ẹni kíkú lórí ilẹ̀,Àwọn ọjọ́ rẹ̀ kò ha sì dà bí àwọn ọjọ́ lébìrà tí a háyà?+  Bí ẹrú, ó ń fi ìháragàgà ṣàfẹ́rí òjìji,+Àti bí lébìrà tí a háyà, ó ń dúró de owó ọ̀yà rẹ̀.+   Nípa báyìí, a ti mú kí n ní àwọn oṣù òṣùpá tí kò ní láárí,+Àwọn òru ìdààmú+ ni wọ́n sì ti ka iye rẹ̀ fún mi.   Nígbà tí mo dùbúlẹ̀, mo tún sọ pé, ‘Ìgbà wo ni èmi yóò dìde?’+Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́ tán ní ti gidi, a tún fi àìlègbéjẹ́ rọ mí yó títí di wíríwírí òwúrọ̀.   Ìdin+ àti ìṣùpọ̀ ekuru+ ti bo ara mi;Awọ ara mi ti séèépá, ó sì yọ́.+   Àwọn ọjọ́ mi pàápàá yára+ ju ọkọ̀ ìhunṣọ,Wọ́n sì ti wá sí òpin ní àìnírètí.+   Rántí pé ẹ̀fúùfù ni ìwàláàyè mi;+Pé ojú mi kì yóò tún rí ire mọ́.   Ojú ẹni tí ń rí mi kì yóò rí mi mọ́;Ojú rẹ yóò wà lára mi, ṣùgbọ́n èmi kì yóò sí mọ́.+   Dájúdájú, àwọsánmà ń wá sí òpin rẹ̀, ó sì ń lọ;Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Ṣìọ́ọ̀lù kì yóò gòkè wá.+ 10  Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́,Ipò rẹ̀ kì yóò sì mọ̀ ọ́n mọ́.+ 11  Èmi, àní, èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́.Dájúdájú, èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú wàhálà ẹ̀mí mi;Èmi yóò ṣàníyàn nípa ìkorò ọkàn mi!+ 12  Ṣé òkun tàbí ẹran ńlá abàmì inú òkun ni mí ni,Tí ìwọ yóò fi yan ẹ̀ṣọ́ tì mí?+ 13  Nígbà tí mo sọ pé, ‘Àga ìnàyìn mi yóò tù mí nínú,Ibùsùn mi yóò ṣèrànwọ́ ní ríru ìdàníyàn mi,’ 14  Àní ìwọ ti fi àwọn àlá dáyà já mi,O sì fi àwọn ìran mú mi ta gìrì nítorí jìnnìjìnnì, 15  Tí ọkàn mi fi yan ìfúnpa,Ikú+ dípò egungun mi. 16  Mo kọ̀ ọ́;+ èmi kì yóò wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé èémí àmíjáde ni àwọn ọjọ́ mi.+ 17  Kí ni ẹni kíkú+ tí ìwọ yóò fi máa tọ́ ọ dàgbà,Tí ìwọ yóò sì máa ṣàníyàn nípa rẹ̀ nínú ọ̀kàn-àyà rẹ, 18  Tí ìwọ yóò fi máa fetí sí i ní òròòwúrọ̀,Tí ìwọ yóò fi máa dán an wò ní ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú?+ 19  Èé ṣe tí ìwọ kì yóò fi yí ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi,+Tàbí kí o jọ̀wọ́ mi jẹ́ẹ́ títí èmi yóò fi dá itọ́ mi mì? 20  Bí mo bá dẹ́ṣẹ̀, kí ni mo lè ṣe àṣeparí rẹ̀ lòdì sí ọ, ìwọ Olùkíyèsí aráyé?+Èé ṣe tí o fi fi mí ṣe àfojúsùn rẹ, tí èmi yóò fi di ẹrù ìnira fún ọ? 21  Èé sì ti ṣe tí ìwọ kò dárí ìrélànàkọjá mi jì,+Kí o sì gbójú fo ìṣìnà mi dá?Nítorí èmi yóò dùbúlẹ̀ sínú ekuru+ nísinsìnyí;Dájúdájú, ìwọ yóò wá mi, èmi kì yóò sì sí mọ́.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé