Jóòbù 5:1-27
5 “Jọ̀wọ́, pè! Ẹnikẹ́ni ha dá ọ lóhùn bí?Èwo nínú àwọn ẹni mímọ́ sì ni ìwọ yóò yíjú sí?
2 Nítorí pé pákáǹleke ni yóò pa òmùgọ̀,Ṣíṣe ìlara sì ni yóò fi ikú pa ẹni tí ó rọrùn láti ré lọ.
3 Èmi alára ti rí i tí òmùgọ̀ ta gbòǹgbò,+Ṣùgbọ́n lójijì mo bẹ̀rẹ̀ sí fi ibi gbígbé rẹ̀ bú.
4 Àwọn ọmọ rẹ̀ ṣì jìnnà réré sí ìgbàlà,+A sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ẹnubodè láìsí olùdáǹdè.
5 Ohun tí ó kórè ni ẹni tí ebi ń pa jẹ;Àní láti ẹnu ìkọ́ alápatà ni ẹnì kan sì ti mú un,Ìdẹkùn sì ré mọ́ àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn ní ti gidi.
6 Nítorí pé kì í ṣe láti inú ekuru lásán-làsàn ni ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ ti ń jáde lọ,Ìjàngbọ̀n kì í sì í rú láti inú ilẹ̀ lásán-làsàn.
7 Nítorí pé ènìyàn ni a bí fún ìdààmú,Àní bí ìtapàrà ṣe ń fò sókè.
8 Bí ó ti wù kí ó rí, èmi fúnra mi yóò mú ọ̀ràn mi tọ Ọlọ́run lọ,Ọlọ́run ni èmi yóò sì gbé ẹjọ́ mi lé lọ́wọ́,+
9 Lé ọwọ́ Ẹni tí ń ṣe àwọn ohun ńláńlá tí ó jẹ́ àwámáridìí,Àwọn ohun àgbàyanu láìníye;+
10 Lé ọwọ́ Ẹni tí ń rọ òjò sórí ilẹ̀ ayé,+Tí ó sì ń rán omi sórí àwọn pápá gbalasa;+
11 Lé ọwọ́ Ẹni tí ń fi àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sórí ibi gíga,+Tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí ó banú jẹ́ wà lókè nínú ìgbàlà;
12 Lé ọwọ́ Ẹni tí ń mú ìpètepèrò àwọn afọgbọ́nhùwà já sí pàbó,+Tí ó fi jẹ́ pé ọwọ́ wọn kì í ṣiṣẹ́ àṣeyọrí;
13 Lé ọwọ́ Ẹni tí ń mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú àlùmọ̀kọ́rọ́yí wọn,+Tí ó fi jẹ́ pé ìmọ̀ràn àwọn ọlọ́gbọ́n bérébéré ni a taari lógèdèǹgbé;+
14 Wọ́n bá òkùnkùn pàdé àní ní ọ̀sán,Wọ́n sì ń táràrà kiri ní ọjọ́kanrí bí ẹni pé ní òru;+
15 Àti lé ọwọ́ Ẹni tí ń gba òtòṣì là kúrò lọ́wọ́ idà tí ó ti ẹnu wọn jáde,Àti kúrò lọ́wọ́ alágbára,+
16 Tí ó fi jẹ́ pé ìrètí wá wà fún ẹni rírẹlẹ̀,+Ṣùgbọ́n àìṣòdodo pa ẹnu rẹ̀ mọ́ ní ti gidi.+
17 Wò ó! Aláyọ̀ ni ẹni tí Ọlọ́run fi ìbáwí tọ́ sọ́nà;+Má sì kọ ìbáwí Olódùmarè!
18 Nítorí òun fúnra rẹ̀ ń ṣokùnfà ìrora, ṣùgbọ́n a di ọgbẹ́ náà;Ó ń fọ́ sí wẹ́wẹ́, ṣùgbọ́n ọwọ́ òun fúnra rẹ̀ a ṣe ìmúláradá.
19 Yóò dá ọ nídè kúrò nínú wàhálà mẹ́fà,+Àti nínú méje, kò sí ohun aṣeniléṣe kankan tí yóò fọwọ́ kàn ọ́.+
20 Nígbà ìyàn, dájúdájú, yóò tún ọ rà padà kúrò lọ́wọ́ ikú,+Àti nígbà ogun kúrò lọ́wọ́ agbára idà.
21 A ó fi ọ́ pa mọ́ kúrò lọ́wọ́ pàṣán ahọ́n,+Ìwọ kì yóò sì fòyà ìfiṣèjẹ nígbà tí ó bá dé.
22 Ìwọ yóò fi ìfiṣèjẹ àti ebi rẹ́rìn-ín,Kì yóò sì sí ìdí fún ọ láti fòyà ẹranko ẹhànnà ilẹ̀ ayé.
23 Nítorí àwọn òkúta pápá ni ìwọ yóò bá dá májẹ̀mú,A ó sì mú kí ẹranko ẹhànnà inú pápá máa bá ọ gbé ní àlàáfíà.+
24 Dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ̀ pé àlàáfíà ni àgọ́ rẹ,Ó dájú pé ìwọ yóò lọ wo ilẹ̀ ìjẹko rẹ, ìwọ kì yóò sì fẹ́ ohun kan kù.
25 Dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ̀ pé àwọn ọmọ rẹ pọ̀,+Àti pé àwọn ọmọ ìran rẹ dà bí ewéko ilẹ̀.+
26 Ìwọ yóò fi okun inú wá sí ibi ìsìnkú,+Bí ìgbà tí àwọn ìtí bá ga pelemọ ní àkókò wọn.
27 Wò ó! Èyí jẹ́ ohun tí àwa ti wádìí. Bẹ́ẹ̀ ni ó rí.Gbọ́ ọ, àti ìwọ—mọ̀ ọ́n fún ara rẹ.”

