Jóòbù 38:1-41

38  Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì ẹ̀lẹ́fùúùfù,+ ó sì wí pé:   “Ta nìyí tí ń ṣú òkùnkùn bo ìmọ̀rànNípasẹ̀ ọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀?+   Jọ̀wọ́, di abẹ́nú rẹ lámùrè bí abarapá ọkùnrin,Sì jẹ́ kí n bi ọ́ léèrè, kí o sì sọ fún mi.+   Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀?+Sọ fún mi, bí o bá mòye.   Ta ní fi ìwọ̀n rẹ̀ lélẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ mọ̀,Tàbí ta ní na okùn ìdiwọ̀n sórí rẹ̀?   Inú kí ni a ri ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀+ rẹ̀ sí,Tàbí ta ní fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,   Nígbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀+ jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde,Tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run+ sì bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn?   Ta sì ni ó fi àwọn ilẹ̀kùn ṣe odi ìdènà òkun,+Èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ bí ìgbà tí ó ya jáde láti inú ilé ọlẹ̀;   Nígbà tí mo fi àwọsánmà ṣe ẹ̀wù rẹ̀Àti ìṣúdùdù nínípọn ṣe ọ̀já ìwémọ rẹ̀, 10  Mo sì tẹ̀ síwájú láti fọ́ ìlànà mi sórí rẹ̀,Mo sì ṣe ọ̀pá ìdábùú àti àwọn ilẹ̀kùn,+ 11  Mo sì ń bá a lọ láti sọ pé, ‘Ìhín yìí ni o lè dé mọ, má sì ṣe ré kọjá;+Ìhín yìí sì ni kí ìgbì rẹ tí ń ru gùdù mọ’?+ 12  Ṣé láti àwọn ọjọ́ rẹ wá ni ìwọ ti pàṣẹ fún òwúrọ̀?+Ìwọ ha ni ó jẹ́ kí ọ̀yẹ̀ mọ ipò rẹ̀, 13  Láti di àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé mú,Kí a lè gbọn àwọn ẹni burúkú dànù kúrò nínú rẹ̀?+ 14  Ó ń pa ara rẹ̀ dà bí amọ̀+ lábẹ́ èdìdì,Àwọn nǹkan sì mú ìdúró wọn bí ẹni pé nínú aṣọ. 15  A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹni burúkú,+Àní apá gíga sì ṣẹ́.+ 16  Ìwọ ha ti rìnnà dé àwọn orísun òkun,Tàbí ìwọ ha ti rìn káàkiri+ ní wíwá ibú omi ká?+ 17  A ha ti ṣí àwọn ẹnubodè ikú+ fún ọ,Tàbí ìwọ ha lè rí àwọn ẹnubodè ibú òjìji?+ 18  Ìwọ ha ti fi làákàyè ronú nípa àwọn àyè fífẹ̀ ilẹ̀ ayé?+Sọ, bí ìwọ bá ti wá mọ gbogbo rẹ̀. 19  Ibo wá ni ọ̀nà sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ ń gbé?+Ní ti òkùnkùn, ibo wá ni ipò rẹ̀ wà, 20  Tí ìwọ yóò fi mú un lọ sí ààlà rẹ̀,Kí o sì lóye àwọn òpópónà tí ó lọ sí ilé rẹ̀? 21  Ìwọ ha ti wá mọ̀ nítorí pé a ti bí ọ ní àkókò yẹn,+Àti nítorí pé ọjọ́ orí rẹ̀ pọ̀ níye? 22  Ìwọ ha ti wọ àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti ìrì dídì,+Tàbí ìwọ ha rí àní àwọn ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́ ti yìnyín,+ 23  Èyí tí mo pa mọ́ de àkókò wàhálà,De ọjọ́ ìjà àti ogun?+ 24  Ibo wá ni ọ̀nà tí ìmọ́lẹ̀ gbà ń pín ara rẹ̀ wà,Tí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn+ sì gbà ń tú káàkiri lórí ilẹ̀ ayé? 25  Ta ní la ipa ojú ọ̀nà fún ìkún omiÀti ọ̀nà fún àwọsánmà ìjì tí ń sán ààrá,+ 26  Láti mú kí ó rọ̀ sórí ilẹ̀ níbi tí ènìyàn kankan kò sí,+Sórí aginjù nínú èyí tí ará ayé kankan kò sí, 27  Láti tẹ́ àwọn ibi tí ìjì kọlù àti ibi ahoro lọ́rùn,Kí ó sì mú kí èéhù koríko hù?+ 28  Òjò ha ní baba,+Tàbí, ta ní bí ìsẹ̀-ìrì?+ 29  Ikùn ta ni omi dídì ti jáde wá ní ti gidi,Ní ti ìrì dídì wínníwínní+ ojú ọ̀run, ta sì ni ó bí i ní tòótọ́? 30  Àní omi fi ara rẹ̀ pa mọ́ bí ẹni pé nípasẹ̀ òkúta,Ojú ibú omi sì mú ara rẹ̀ ṣùpọ̀ mọ́ra digbí.+ 31  Ìwọ ha lè so àwọn ìdè àgbájọ ìràwọ̀ Kímà pinpin,Tàbí ìwọ ha lè tú àní àwọn okùn àgbájọ ìràwọ̀ Késílì?+ 32  Ìwọ ha lè mú àgbájọ ìràwọ̀ Másárótì jáde wá ní àkókò rẹ̀ tí a yàn kalẹ̀?Àti ní ti àgbájọ ìràwọ̀ Ááṣì lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ ha lè darí wọn? 33  Ìwọ ha ti wá mọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ ọ̀run,+Tàbí ìwọ ha lè fi ọlá àṣẹ rẹ̀ lélẹ̀ ní ilẹ̀ ayé? 34  Ìwọ ha lè gbé ohùn rẹ sókè àní dé àwọsánmà,Kí ìrọ́sókè-sódò àgbájọ omi lè bò ọ́?+ 35  Ìwọ ha lè rán mànàmáná jáde, kí wọ́n lè lọKí wọ́n sì sọ fún ọ pé, ‘Àwa rèé!’? 36  Ta ní fi ọgbọ́n+ sínú àwọn ipele àwọsánmà,Tàbí tí ó fi òye+ fún ohun àrà ojú sánmà? 37  Ta ní lè fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmà ní pàtó,Tàbí àwọn ìṣà omi ọ̀run—ta ní lè mú wọn dà jáde,+ 38  Nígbà tí ekuru dà jáde bí ẹni pé sínú ìṣùpọ̀ tí a mọ,Tí àwọn ògúlùtu sì lẹ̀ mọ́ra? 39  Ìwọ ha lè ṣọdẹ ẹran fún kìnnìún,Ìwọ ha sì lè tẹ́ ìdálọ́rùn amú-bí-ẹyá ti àwọn ẹgbọrọ kìnnìún lọ́rùn,+ 40  Nígbà tí wọ́n lúgọ ní àwọn ibi ìfarapamọ́,+Tàbí tí wọ́n ń ba ní ibi kọ́lọ́fín fún ibùba? 41  Ta ní ń pèsè oúnjẹ ẹyẹ ìwò+ fún un,Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́,Nígbà tí wọ́n ń rìn káàkiri nítorí pé kò sí nǹkan kan láti jẹ?

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé