Jóòbù 37:1-24

37  “Ní tòótọ́, ọkàn-àyà mi bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì sí èyí,+Ó sì tọ sókè láti ipò rẹ̀.   Ẹ fara balẹ̀ fetí sí kíkù rìrì ohùn rẹ̀,+Àti kíkùn hùn-ùn tí ń jáde lọ láti ẹnu rẹ̀.   Ó ń tú u sílẹ̀ lábẹ́ gbogbo ojú ọ̀run,Mànàmáná+ rẹ̀ sì wà títí dé àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé.   Lẹ́yìn rẹ̀, ìró kan bú ramúramù;Ó fi ìró ìlọ́lájù+ rẹ̀ sán ààrá,+Kò sì dá wọn dúró nígbà tí a gbọ́ ohùn rẹ̀.+   Ọlọ́run ń fi ohùn rẹ̀+ sán ààrá lọ́nà àgbàyanu,Ó ń ṣe àwọn ohun ńlá tí a kò lè mọ̀.+   Nítorí ó sọ fún ìrì dídì pé, ‘Rọ̀ sí ilẹ̀ ayé,’+Àti sí eji wọwọ òjò, àní sí eji wọwọ òjò líle rẹ̀.+   Ó fi èdìdì sí ọwọ́ gbogbo ará ayé,Kí gbogbo ẹni kíkú lè mọ iṣẹ́ rẹ̀.   Ẹranko ìgbẹ́ sì wá sínú ibùba,Ó sì ń gbé nínú ibi ìfarapamọ́ rẹ̀.+   Inú yàrá inú lọ́hùn-ún+ ni ẹ̀fúùfù oníjì ti ń wá,Inú ẹ̀fúùfù àríwá sì ni òtútù ti ń wá.+ 10  Nípa èémí Ọlọ́run ni a fi ń pèsè omi dídì,+Ìbú omi sì wà ní ìhámọ́ pinpin.+ 11  Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń fi ọ̀rinrin mú àwọsánmà wúwo,Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀+ ń tú ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ká, 12  A sì ń yí i káàkiri nípa dídarí tí ó ń darí wọn fún iṣẹ́ wọnNíbikíbi tí ó bá pa láṣẹ+ fún wọn lórí ilẹ̀ eléso ti ilẹ̀ ayé. 13  Yálà fún ọ̀pá+ tàbí fún ilẹ̀ rẹ̀+Tàbí fún inú-rere-onífẹ̀ẹ́,+ ó ń mú kí ó mú ìyọrísí iṣẹ́ jáde. 14  Fi etí sí èyí, Jóòbù;Dúró jẹ́ẹ́, kí o sì fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.+ 15  Ìwọ ha mọ ìgbà tí Ọlọ́run fi wọ́n sí ipò wọn,+Tí ó sì mú kí ìmọ́lẹ̀ àwọsánmà rẹ̀ tàn yanran? 16  Ìwọ ha mọ̀ nípa ìsorọ̀ gígún régé àwọsánmà,+Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ẹni tí ó pé nínú ìmọ̀?+ 17  Bí ẹ̀wù rẹ ṣe gbónáNígbà tí ilẹ̀ ayé fi ìdákẹ́jẹ́ẹ́ hàn láti gúúsù wá?+ 18  Pẹ̀lú rẹ̀, ìwọ ha lè rọ sánmà,+Kí ó le bí dígí dídà? 19  Kí a mọ ohun tí a ó sọ fún un;A kò lè mú ọ̀rọ̀ jáde nítorí òkùnkùn. 20  Ṣé kí a ṣèròyìn rẹ̀ fún un pé èmi yóò sọ̀rọ̀?Tàbí ènìyàn èyíkéyìí ha ti sọ pé a ó ta ọ̀rọ̀ náà látagbà bí?+ 21  Wàyí o, wọn kò rí ìmọ́lẹ̀ ní ti gidi;Ó tàn yòò ní sánmà,Nígbà tí ẹ̀fúùfù ti kọjá lọ, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ̀ wọ́n mọ́. 22  Ìdángbinrin oníwúrà ń wá láti àríwá.Lára Ọlọ́run, iyì+ jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù. 23  Ní ti Olódùmarè, àwa kò lè rídìí rẹ̀;+Ó ga ní agbára,+Òun kì yóò sì fi ojú kékeré wo+ ìdájọ́ òdodo+ àti ọ̀pọ̀ yanturu òdodo.+ 24  Nítorí náà, kí àwọn ènìyàn bẹ̀rù rẹ̀.+Òun kò ka àwọn ènìyàn èyíkéyìí tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà ara wọn sí.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé