Jóòbù 35:1-16

35  Élíhù sì ń bá a lọ ní dídáhùn, ó sì wí pé:   “Ṣé èyí ni ohun tí ìwọ kà sí ìdájọ́ òdodo?Ìwọ wí pé, ‘Òdodo mi ju ti Ọlọ́run lọ.’+   Nítorí ìwọ wí pé, ‘Kí ni ó wúlò fún ọ fún?+Àǹfààní wo ni mo ní ju ti ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ń ṣẹ̀?’+   Èmi fúnra mi yóò fún ọ lésìÀti àwọn alábàákẹ́gbẹ́+ rẹ pẹ̀lú rẹ.   Gbé ojú sókè ọ̀run,+ kí o sì wò,Sì wo àwọsánmà,+ pé wọ́n ga jù ọ́ lọ ní tòótọ́.   Bí o bá dẹ́ṣẹ̀ ní ti tòótọ́, kí ni ìwọ ṣe àṣeparí rẹ̀ lòdì sí i?+Bí àwọn ìdìtẹ̀ rẹ bá sì pọ̀ sí i ní ti tòótọ́, kí ni ìwọ ṣe sí i?   Bí o bá jàre ní tòótọ́, kí ni ìwọ fi fún un,Tàbí kí ni ó rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?+   Ìwà burúkú rẹ lè jẹ́ sí ènìyàn bí ìwọ,+Àti Òdodo rẹ sí ọmọ ará ayé.+   Nítorí ògìdìgbó ìnilára, wọ́n ń pè fún ìrànlọ́wọ́;+Wọ́n ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nítorí apá àwọn ẹni ńlá.+ 10  Síbẹ̀, kò sí ẹnì kankan tí ó sọ pé, ‘Ọlọ́run Olùṣẹ̀dá mi Atóbilọ́lá dà,+Ẹni tí ń fúnni ní orin atunilára ní òru?’+ 11  Òun ni Ẹni tí ń kọ́+ wa ju àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé,+Ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹ̀dá tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá. 12  Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń ké jáde ṣáá, ṣùgbọ́n kò dáhùn,+Nítorí ìgbéraga+ àwọn ẹni búburú. 13  Kìkì pé Ọlọ́run kì í gbọ́ àìṣòótọ́,+Olódùmarè kì í sì í rí i.+ 14  Áńbọ̀sìbọ́sí ìgbà tí o bá wá sọ pé ìwọ kò rí i!+Ẹjọ́ ń bẹ níwájú rẹ̀, nítorí náà kí o fi tàníyàn-tàníyàn dúró dè é.+ 15  Nísinsìnyí, nítorí pé ìbínú rẹ̀ kò tíì béèrè fún ìjíhìn,+Àti pé òun kò tíì fiyè sí ìwàǹwára tí ó dé góńgó.+ 16  Jóòbù alára kàn la ẹnu rẹ̀ lásán;Ó kàn ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìní ìmọ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé