Jóòbù 34:1-37
34 Élíhù sì ń bá a lọ láti dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi, ẹ̀yin ọlọ́gbọ́n;Kí ẹ sì fi etí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ mọ̀.
3 Nítorí etí máa ń dán ọ̀rọ̀ wò,+Gan-an gẹ́gẹ́ bí òkè ẹnu ti máa ń tọ́ nǹkan wò nígbà jíjẹun.+
4 Ẹ jẹ́ kí a yan ìdájọ́ fún ara wa;Ẹ jẹ́ kí a mọ ohun tí ó dára láàárín wa.
5 Nítorí Jóòbù wí pé, ‘Dájúdájú mo jàre,+Ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti yí ìdájọ́ mi sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.+
6 Èmi yóò ha purọ́ lòdì sí ìdájọ́ mi?Ọgbẹ́ mi ríronilára gógó kò ṣeé wò sàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìrélànàkọjá kankan.’+
7 Abarapá ọkùnrin wo ni ó dà bí Jóòbù,+Ẹni tí ń mu ìfiniṣẹ̀sín bí ẹní mu omi?+
8 Dájúdájú, ó sì ti forí lé àtiwọnú ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn aṣenilọ́ṣẹ́Àti láti bá àwọn ènìyàn oníwà burúkú rìn.+
9 Nítorí ó wí pé, ‘Abarapá ọkùnrin kì í jèrè+Nípa níní tí ó ní ìdùnnú sí Ọlọ́run.’
10 Nítorí náà, ẹ̀yin tí ẹ ní ọkàn-àyà,+ ẹ fetí sí mi.Kí a má rí i pé Ọlọ́run tòótọ́ yóò hùwà burúkú,+Àti pé kí Olódùmarè hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu!+
11 Nítorí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí ará ayé bá gbà hùwà ni yóò fi san+ án fún un,Àti ní ìbámu pẹ̀lú ipa ọ̀nà ènìyàn ni yóò mú kí ó wá sórí rẹ̀.
12 Bẹ́ẹ̀ ni, ní tòótọ́, Ọlọ́run kì í ṣe burúkú,+Olódùmarè kì í sì í yí ìdájọ́ po.+
13 Ta ni ó yan ilẹ̀ ayé fún un,Ta sì ni ó yan ilẹ̀ eléso kalẹ̀ fún un, àní gbogbo rẹ̀?
14 Bí ó bá darí ọkàn-àyà rẹ̀ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni,Bí ó bá kó ẹ̀mí àti èémí onítọ̀hún jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,+
15 Gbogbo ẹran ara yóò jùmọ̀ gbẹ́mìí mì,Ará ayé yóò sì padà sínú ekuru gan-an.+
16 Nítorí náà, bí o bá ní òye, fetí sí èyí;Fi etí sí ìró ọ̀rọ̀ mi.
17 Ní ti tòótọ́, ẹnikẹ́ni tí ó kórìíra ìdájọ́ òdodo yóò ha ṣàkóso,+Bí alágbára bá sì jẹ́ olódodo, ìwọ yóò ha pè é ní ẹni burúkú?+
18 Ẹnì kan yóò ha sọ fún ọba pé, ‘Aláìdára fún ohunkóhun ni ọ́’?Fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú pé, ‘Ẹni burúkú ni ọ́’?+
19 Ẹnì kan wà tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ aládé,Tí kì í sì í ka ọ̀tọ̀kùlú sí ju ẹni rírẹlẹ̀ lọ,+Nítorí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọ́n jẹ́.+
20 Ní ìṣẹ́jú kan wọ́n kú,+ àní ní àárín òru;+Àwọn ènìyàn ń mì síwá-sẹ́yìn, wọn a sì kọjá lọ,Àwọn alágbára a sì lọ láìsí ọwọ́ ẹnikẹ́ni níbẹ̀.+
21 Nítorí ojú rẹ̀ ń bẹ ní àwọn ọ̀nà ènìyàn,+Ó sì ń rí ìṣísẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
22 Kò sí òkùnkùn tàbí ibú òjìji èyíkéyìíFún àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ láti fi ara wọn pa mọ́ níbẹ̀.+
23 Nítorí kò yan àkókò kankan kalẹ̀ fún ènìyàn èyíkéyìíLáti lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run nínú ìdájọ́.
24 Ó ń ṣẹ́ àwọn alágbára+ láìsí àyẹ̀wò èyíkéyìí,Ó sì ń mú kí àwọn mìíràn dìde dúró dípò wọn.+
25 Nítorí náà, ó dá ohun tí iṣẹ́ wọ́n jẹ́ mọ̀,+Ó sì ń bì wọ́n ṣubú ní òru, a sì fọ́ wọn túútúú.+
26 Ó gbá wọn lábàrá bí àwọn ẹni burúkúNí àyè àwọn òǹwòran;+
27 Nítorí ìdí náà pé wọ́n ti yí padà kúrò ní títọ̀ ọ́ lẹ́yìn,+Wọn kò sì ronú nípa ìkankan nínú àwọn ọ̀nà rẹ̀,+
28 Láti lè mú kí igbe ẹkún ẹni rírẹlẹ̀ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀;Ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gbọ́ igbe ẹkún àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+
29 Nígbà tí òun fúnra rẹ̀ bá fa ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ta wá ni ó lè dá a lẹ́bi?Nígbà tí ó bá sì fi ojú rẹ̀ pa mọ́,+ ta ní lè rí i,Yálà sí orílẹ̀-èdè+ ni o tàbí sí ènìyàn, ohun kan náà ni bí?
30 Kí apẹ̀yìndà má bàa jọba,+Bẹ́ẹ̀ ni kí ìdẹkùn+ má ṣe sí fún àwọn ènìyàn.
31 Nítorí ẹnikẹ́ni yóò ha sọ fún Ọlọ́run ní ti tòótọ́ pé,‘Mo ti rọ́jú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò hùwà ìbàjẹ́;+
32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò rí nǹkan kan, fún mi ní ìtọ́ni fúnra rẹ;Bí mo bá ti hùwà àìṣòdodo èyíkéyìí,Èmi kì yóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́’?+
33 Òun yóò ha pèsè ohun tí ó ṣàìtó láti ojú ìwòye tìrẹ nítorí pé ìwọ kọ ìdájọ́,Nítorí pé ìwọ fúnra rẹ ni ó yàn án, kì í sì í ṣe èmi?Àní ohun tí ìwọ mọ̀ dáadáa, sọ ọ́.
34 Àwọn ènìyàn tí ó ní ọkàn-àyà+ yóò sọ fún mi—Àní ọlọ́gbọ́n abarapá ọkùnrin tí ń fetí sí mi pé,
35 ‘Jóòbù alára ń sọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀,+Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ láìní ìjìnlẹ̀ òye.’
36 Baba mi, jẹ́ kí a dán Jóòbù wò dé góńgóNítorí èsì rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́.+
37 Nítorí ó fi ìdìtẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀;+Láàárín wa, ó pàtẹ́wọ́, ó sì sọ àwọn àsọjáde rẹ̀ di púpọ̀ lòdì sí Ọlọ́run tòótọ́!”+

