Jóòbù 32:1-22
32 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ṣíwọ́ dídá Jóòbù lóhùn, nítorí tí ó jẹ́ olódodo ní ojú ara rẹ̀.+
2 Ṣùgbọ́n ìbínú Élíhù ọmọkùnrin Bárákélì ọmọ Búsì+ ti ìdílé Rámù wá gbóná. Ìbínú rẹ̀ ru sí Jóòbù lórí pípolongo tí ó polongo ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.+
3 Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìbínú rẹ̀ ru sí àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta lórí òtítọ́ náà pé wọn kò rí ìdáhùn, ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí pe Ọlọ́run ní ẹni burúkú.+
4 Élíhù alára sì dúró kí Jóòbù sọ̀rọ̀ tán, nítorí tí wọ́n jù ú lọ ní ọjọ́ orí.+
5 Élíhù sì rí i ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ pé kò sí ìdáhùn lẹ́nu+ àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà, ìbínú rẹ̀ sì túbọ̀ ń gbóná sí i.
6 Élíhù ọmọkùnrin Bárákélì ọmọ Búsì sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:“Ọ̀dọ́ ni mí ní ọjọ́ orí,Àgbàlagbà sì ni ẹ̀yin.+Ìdí nìyẹn tí mo fi fà sẹ́yìn, àyà sì fò míLáti polongo ìmọ̀ mi fún yín.
7 Mo sọ pé, ‘Àní àwọn ọjọ́ ni kí ó sọ̀rọ̀,Ògìdìgbó ọdún sì ni ó yẹ kí ó sọ ọgbọ́n di mímọ̀.’+
8 Dájúdájú, ẹ̀mí tí ó wà nínú àwọn ẹni kíkúÀti èémí Olódùmarè ni ó ń fún wọn ní òye.+
9 Kì í ṣe àwọn tí ó wulẹ̀ pọ̀ yanturu ní ọjọ́ orí ni ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n,+Tàbí àwọn tí ó kàn darúgbó ni ó lóye ìdájọ́.+
10 Nítorí náà, mo wí pé, ‘Fetí sí mi.Èmi yóò polongo ìmọ̀ mi, àní èmi.’
11 Wò ó! Mo ti dúró de ọ̀rọ̀ yín,Mo ń fi etí sí ìfèròwérò yín,+Títí ẹ fi lè wá ọ̀rọ̀ láti sọ.
12 Mo sì yí àfiyèsí mi sọ́dọ̀ yín,Sì kíyè sí i, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ìbáwí tọ́ Jóòbù sọ́nà,Kò sí ìkankan lára yín tí ó dá a lóhùn àwọn àsọjáde rẹ̀,
13 Kí ẹ má sọ pé, ‘Àwa ti rí ọgbọ́n;+Ọlọ́run ni ó lé e lọ, kì í ṣe ènìyàn.’
14 Níwọ̀n bí kò ti to ọ̀rọ̀ lẹ́sẹẹsẹ lòdì sí mi,Nítorí náà, èmi kì yóò fi àsọjáde yín fún un lésì.
15 A ti já wọn láyà, wọn kò dáhùn mọ́;Ọ̀rọ̀ ti ṣí kúrò lọ́dọ̀ wọn.
16 Mo sì ti dúró, nítorí wọn kò sọ̀rọ̀ mọ́;Nítorí wọ́n dúró jẹ́ẹ́, wọn kò dáhùn mọ́.
17 Èmi yóò dáhùn ipa tèmi, àní èmi;Èmi yóò polongo ìmọ̀ mi, àní èmi;
18 Nítorí mo ti kún fún ọ̀rọ̀;Ẹ̀mí ti kó ìdààmú+ bá mi nínú ikùn mi.
19 Wò ó! Ikùn mi dà bí wáìnì tí kò ní ojú ìtújáde;Bí àwọn ìgò awọ tuntun, ó fẹ́ bẹ́.+
20 Jẹ́ kí n sọ̀rọ̀, kí ara lè tù mí.Èmi yóò ṣí ètè mi kí n lè dáhùn.+
21 Jọ̀wọ́, kí n má ṣe ojúsàájú ènìyàn;+Èmi kì yóò sì fi orúkọ oyè jíǹkí ará ayé;+
22 Nítorí ó dájú pé èmi kò mọ bí a ti ń fi orúkọ oyè jíǹkí ẹni;Tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn ni Olùṣẹ̀dá+ mi yóò gbé mi kúrò.

