Jóòbù 30:1-31
30 “Nísinsìnyí, wọ́n ń fi mí rẹ́rìn-ín,+Àwọn tí kò tó mi ní ọjọ́ orí,+Àwọn tí ó jẹ́ pé èmi ì bá kọ̀Láti fi baba wọn pẹ̀lú agbo ajá mi.
2 Àní agbára ọwọ́ wọn—kí ni ìwúlò rẹ̀ fún mi?Okun inú ti ṣègbé nínú wọn.+
3 Nítórí àìní àti ebi, wọ́n di aláìlè-méso-jáde,Wọ́n ń ginrin jẹ ní ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi,+Níbi tí ìjì àti ìsọdahoro wà lánàá.
4 Wọ́n ń já ewéko iyọ̀ lẹ́bàá àwọn igi kékeré,Gbòǹgbò igi wíwẹ́ sì ni oúnjẹ wọn.
5 A óò lé wọn kúrò ní àdúgbò;+Àwọn ènìyàn yóò kígbe mọ́ wọn bí ẹní kígbe mọ́ olè.
6 Wọn yóò máa gbé ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àfonífojì olójú ọ̀gbàrá,Nínú àwọn ihò inú ilẹ̀ àti nínú àpáta.
7 Àárín àwọn igi kékeré ni wọn yóò ti ké jáde;Abẹ́ èsìsì ni wọn yóò kó ara wọn jọpọ̀ sí.
8 Àwọn ọmọ òpònú+ àti àwọn ọmọ ẹni tí kò lórúkọ pẹ̀lú,A ti nà wọ́n lọ́rẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà.
9 Nísinsìnyí, mo ti di ẹṣin ọ̀rọ̀ orin wọn,+Ẹni tí a fi ń ṣe ọ̀rọ̀ sọ+ sì ni mo jẹ́ fún wọn.
10 Wọ́n ṣe họ́ọ̀ sí mi, wọ́n jìnnà réré sí mi;+Wọn kò sì ṣíwọ́ láti máa tutọ́ sí mi lójú.+
11 Nítorí ó tú okùn ọrun mi, ó sì tẹ̀ síwájú láti rẹ̀ mí sílẹ̀,Wọ́n sì tú ìjánu sílẹ̀ ní tìtorí mi.
12 Wọ́n dìde ní ọwọ́ ọ̀tún mi bí ọ̀wọ́ àwọn ọmọkọ́mọ;Wọ́n jẹ́ kí ẹsẹ̀ mi lọ,Ṣùgbọ́n wọ́n tẹ̀ síwájú láti mọ àwọn ohun ìdínà wọn tí ń mú àjálù wá sókè lòdì sí mi.+
13 Wọ́n ti ya àwọn òpópónà mi lulẹ̀;Wọ́n ṣàǹfààní fún mi, kìkì sí àgbákò,+Láìjẹ́ pé wọ́n ní olùrànlọ́wọ́ èyíkéyìí.
14 Wọ́n ń bọ̀ bí ẹní gba inú àlàfo gbígbòòrò wá;Wọ́n ń yí gbirigbiri bọ̀ lábẹ́ ìjì.
15 Ìpayà òjijì ni a ti yí lé mi lórí;Ìdúró mi gẹ́gẹ́ bí ọmọlúwàbí ni a lé bí ẹ̀fúùfù,Ìgbàlà mi sì kọjá lọ bí àwọsánmà.
16 Nísinsìnyí, a ti tú ọkàn mi jáde kúrò nínú mi;+Àwọn ọjọ́ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́+ gbá mi mú.
17 Ní òru, àní egungun mi+ ni a dá lu, ó sì já bọ́ kúrò lára mi,Ìrora tí ń já mi jẹ kò sì dúró rárá.+
18 Nípa ọ̀pọ̀ yanturu agbára, ẹ̀wù mi yí padà;Ó yí mi ká bí ọrùn ẹ̀wù mi gígùn.
19 Ó rẹ̀ mí sílẹ̀ sínú amọ̀,Tí mo fi fi ara mi hàn bí ekuru àti eérú.
20 Mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi lóhùn;+Mo dúró, kí o bàa lè fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí mi.
21 Ìwọ yí ara rẹ padà láti ṣe mí níkà;+Ìwọ fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá ọwọ́ rẹ ṣe kèéta sí mi.
22 O gbé mi sókè sí ẹ̀fúùfù, o mú kí n gùn ún;Lẹ́yìn náà, o fi ìfọ́yángá tú mi ká.
23 Nítorí mo mọ̀ dáadáa pé ìwọ yóò mú kí n padà lọ sínú ikú,+Àti sí ilé ìpàdé fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.
24 Kìkì pé kò sí ẹni tí ń na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí òkìtì àwókù lásán-làsàn,+Bẹ́ẹ̀ ni kò sí igbe fún ìrànlọ́wọ́ nípa nǹkan wọnnì nígbà tí ènìyàn bá ń jẹrà.
25 Dájúdájú, mo ti sunkún fún ẹni tí ọjọ́ nira fún;+Ọkàn mi ti kẹ́dùn fún òtòṣì.+
26 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo dúró de ohun rere, síbẹ̀ ohun búburú ni ó dé;+Mo sì ń dúró dé ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ìṣúdùdù ni ó dé.
27 A ti mú kí ìfun mi hó, kò sì dákẹ́ jẹ́ẹ́;Àwọn ọjọ́ ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ kò mí lójú.
28 Mo ń rìn káàkiri nínú ìbànújẹ́+ nígbà tí kò sí ìmọ́lẹ̀ oòrùn;Mo dìde nínú ìjọ, mo ń kígbe ṣáá fún ìrànlọ́wọ́.
29 Mo di arákùnrin àwọn akátá,Àti alábàákẹ́gbẹ́ àwọn abo ọmọ ògòǹgò.+
30 Àní awọ ara mi di dúdú,+ ó sì ṣí kúrò lára mi,Àní egungun mi sì gbóná nítorí pé ó gbẹ.
31 Háàpù mi sì wá jẹ́ fún ọ̀fọ̀ lásán-làsàn,Àti fèrè ape mi fún ohùn àwọn tí ń sunkún.

