Jóòbù 27:1-23

27  Jóòbù sì tún tẹ̀ síwájú láti gbẹ́nu lé gbólóhùn òwe rẹ̀,+ ó sì ń bá a lọ ní wíwí pé:  2  “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ,+ ẹni tí ó mú ìdájọ́ mi kúrò,+Àti bí Olódùmarè ti ń bẹ, ẹni tí ó mú ọkàn mi korò,+  3  Nígbà tí gbogbo èémí mi ṣì ń bẹ nínú mi,Tí ẹ̀mí Ọlọ́run sì wà ní ihò imú mi,+  4  Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ àìṣòdodo,Ahọ́n mi kì yóò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lábẹ́lẹ̀!  5  Kò ṣée ronú kàn níhà ọ̀dọ̀ mi pé èmi yóò polongo yín ní olódodo!+Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi+ kúrò lọ́dọ̀ mi!  6  Mo ti di ìṣẹ̀tọ́ mi mú, èmi kì yóò sì jẹ́ kí ó lọ;+Ọkàn-àyà mi kì yóò ṣáátá mi fún èyíkéyìí nínú àwọn ọjọ́ mi.+  7  Kí ọ̀tá mi di ènìyàn burúkú ní gbogbo ọ̀nà,+Kí ẹni tí ń dìtẹ̀ sí mi sì di oníwà àìtọ́ ní ti gidi.  8  Nítorí kí ni ìrètí apẹ̀yìndà bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó ké e kúrò,+Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé Ọlọ́run gba ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀?+  9  Ọlọ́run yóò ha gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wàhálà dé bá a?+ 10  Tàbí yóò ha ní inú dídùn kíkọyọyọ sí Olódùmarè?Yóò ha máa pe Ọlọ́run nígbà gbogbo? 11  Èmi yóò fún yín ní ìtọ́ni nípa ọwọ́ Ọlọ́run;Èyí tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pa mọ́.+ 12  Wò ó! Gbogbo yín ni ẹ ti rí ìran;Nítorí náà, èé ṣe tí ẹ fi fi ara yín hàn pé asán pátápátá ni yín?+ 13  Èyí ni ìpín ènìyàn burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run;+Ogún àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ni wọn yóò sì gbà láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè fúnra rẹ̀. 14  Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá di púpọ̀, fún idà ni;+Àwọn ọmọ ìran rẹ̀ pàápàá kì yóò ní ànító oúnjẹ. 15  Àwọn tirẹ̀ tí ó là á já ní a ó sin nígbà ìyọnu àjàkálẹ̀ tí ń ṣekú pani,Àwọn opó wọn kì yóò sì sunkún.+ 16  Bí ó ba tilẹ̀ to fàdákà jọ pelemọ bí ekuru,Tí ó sì pèsè aṣọ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amọ̀, 17  Òun yóò pèsè sílẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo ni yóò fi aṣọ náà wọ ara rẹ̀,+Aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sì ni yóò ní ìpín nínú fàdákà náà. 18  Ó ti kọ́ ilé ara rẹ̀ bí òólá lásán-làsàn,Àti bí àtíbàbà+ tí olùṣọ́ ṣe. 19  Òun yóò dùbúlẹ̀ ní ọlọ́rọ̀, ṣùgbọ́n a kì yóò kó nǹkan kan jọ;Ó ti la ojú rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò sí nǹkan kan.+ 20  Ìpayà òjijì yóò dé bá a bí omi;+Ẹ̀fúùfù oníjì yóò jí i gbé lọ dájúdájú ní òru. 21  Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn yóò gbé e lọ,+ yóò sì lọ,Yóò sì fi àjà gbé e lọ kúrò ní ipò rẹ̀.+ 22  Yóò sì fi ara rẹ̀ sọ̀kò lù ú, kì yóò sì ní ìyọ́nú;+Láìsí àní-àní, yóò gbìyànjú láti fẹsẹ̀ fẹ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀.+ 23  Ẹnì kan yóò pàtẹ́wọ́ sí i,+Yóò sì súfèé+ sí i láti ipò rẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé