Jóòbù 23:1-17

23  Jóòbù sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:  2  “Àní lónìí, ipò ìdàníyàn+ mi ni ìṣọ̀tẹ̀;Ọwọ́ mi wúwo ní tìtorí ìmí ẹ̀dùn mi.  3  Ì bá ṣe pé mo mọ ibi tí mo ti lè rí i ní ti gidi!+Èmi ì bá wá títí dé ibi tí ó fìdí kalẹ̀ sí.+  4  Èmi ì bá gbé ẹjọ́ ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ níwájú rẹ̀,Èmi ì bá sì fi ìjiyàn àfidáhùnpadà kún ẹnu mi;  5  Èmi ì bá mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí yóò fi dá mi lóhùn,Èmi ì bá sì ronú nípa ohun tí ó bá sọ fún mi.+  6  Òun yóò ha fi ọ̀pọ̀ yanturu agbára bá mi fà á?Rárá o! Dájúdájú, òun fúnra rẹ̀ yóò kọbi ara sí mi.+  7  Ibẹ̀ ni adúróṣánṣán fúnra rẹ̀ yóò ti mú àwọn ọ̀ràn tọ́ pẹ̀lú rẹ̀ dájúdájú,Èmi ì bá sì lọ láìséwu kúrò lọ́dọ̀ onídàájọ́ mi títí láé.  8  Wò ó! Mo lọ sí ìlà-oòrùn, òun kò sì sí níbẹ̀;Mo sì tún padà, èmi kò sì lè dá a mọ̀;+  9  Mo lọ sí apá òsì níbi tí ó ti ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò lè rí i;Ó yà sí apá ọ̀tún, ṣùgbọ́n èmi kò rí i. 10  Nítorí ó mọ ọ̀nà tí mo ń gbà dáadáa.+Lẹ́yìn tí ó bá ti dán mi wò, èmi yóò jáde wá bí wúrà.+ 11  Èmi ti gbé ẹsẹ̀ mi lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀;Mo ti pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, èmi kò sì yapa.+ 12  Èmi kò kúrò nínú àṣẹ ètè rẹ̀.+Mo ti fi àsọjáde ẹnu rẹ̀ ṣúra ju+ ohun tí a lànà sílẹ̀ fún mi. 13  Èrò inú rẹ̀ sì ṣe ọ̀kan, ta sì ni ó lè dè é lọ́nà?+Ọkàn rẹ̀ sì fẹ́ ohun kan, òun yóò sì ṣe é.+ 14  Nítorí tí yóò mú ohun tí a lànà sílẹ̀ fún mi ṣẹ pátápátá,+Nǹkan bí ìwọ̀nyí sì pọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. 15  Ìdí nìyẹn tí ìyọlẹ́nu fi bá mi nítorí rẹ̀;Mo fi ara mi hàn ní olùfiyèsílẹ̀, mo sì ní ìbẹ̀rùbojo fún un.+ 16  Àní Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti mú kí ojora mú ọkàn-àyà mi,+Olódùmarè fúnra rẹ̀ sì ti yọ mi lẹ́nu.+ 17  Nítorí a kò tíì pa mí lẹ́nu mọ́ nítorí òkùnkùn,Tàbí nítorí pé ìṣúdùdù ti bo ojú mi.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé