Jóòbù 22:1-30

22  Élífásì ará Témánì sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, ó sì wí pé:   “Abarapá ọkùnrin ha lè wúlò fún Ọlọ́run,+Pé ẹni tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò wúlò fún un?   Olódùmarè ha ní inú dídùn rárá sí jíjẹ́ tí o jẹ́ olódodo,+Tàbí èrè èyíkéyìí nínú ṣíṣe tí o ṣe ọ̀nà rẹ ní aláìlẹ́bi?+   Òun yóò ha fi ìbáwí tọ́ ọ sọ́nà nítorí ìfọkànsìn rẹ,Òun yóò ha bá ọ wá sínú ìdájọ́?+   Ìwà búburú rẹ kò ha ti pọ̀ jù nísinsìnyí,+Àwọn ìṣìnà rẹ kì yóò ha sì lópin?   Nítorí tí ìwọ fi ipá gba ohun ìdógò lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ láìnídìí,+Ìwọ sì bọ́ ẹ̀wù pàápàá lára àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìhòòhò.   Ìwọ kò fún ẹni tí ó ti rẹ̀ ní omi mu,Ìwọ sì fawọ́ oúnjẹ sẹ́yìn fún ẹni tí ebi ń pa.+   Ní ti ènìyàn tí ó lókun, òun ni ó ni ilẹ̀,+Ẹni tí a ṣe ojúsàájú sí sì ń gbé inú rẹ̀.   Àwọn opó ni ìwọ ti rán lọ lọ́wọ́ òfo,Apá àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba ni a sì ṣẹ́.+ 10  Ìdí nìyẹn tí àwọn pańpẹ́ ẹyẹ fi wà yí ọ ká,+Tí ìbẹ̀rùbojo òjijì sì ń yọ ọ́ lẹ́nu; 11  Tàbí òkùnkùn, tí o kò fi lè ríran,Ìrọ́sókè-sódò àgbájọ omi sì bò ọ́. 12  Ọlọ́run kò ha ga bí ọ̀run?+Pẹ̀lúpẹ̀lù, wo àròpọ̀ iye àwọn ìràwọ̀,+ pé wọ́n ga. 13  Síbẹ̀, ìwọ wí pé: ‘Kí tilẹ̀ ni Ọlọ́run mọ̀?Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú ìṣúdùdù nínípọn? 14  Àwọsánmà jẹ́ ibi ìlùmọ́ fún un, tí kò fi lè ríran,Ó sì ń rìn káàkiri lórí ìsálú ọ̀run.’ 15  Ìwọ yóò ha máa bá a lọ lójú ọ̀nà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìnTí àwọn ènìyàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́ ti rìn, 16  Àwọn ènìyàn tí a ti já gbà lọ, kí àkókò wọn tó pé,+Àwọn tí a gbọ́n ìpìlẹ̀ wọn+ dànù gẹ́gẹ́ bí odò, 17  Àwọn tí ń sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: ‘Yí padà kúrò lọ́dọ̀ wa!+Kí sì ni Olódùmarè lè ṣàṣeparí lòdì sí wa?’ 18  Síbẹ̀, òun fúnra rẹ̀ ti fi àwọn ohun rere kún ilé wọn;+Àní ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú ti jìnnà réré sí mi.+ 19  Àwọn olódodo yóò rí èyí, wọn yóò sì máa yọ̀,+Aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ alára yóò sì fi wọ́n ṣẹ̀sín pé: 20  ‘Lóòótọ́, a ti pa àwọn tí ó dojú ìjà kọ wá rẹ́;Ohun tí ó sì ṣẹ́ kù lára wọn ni iná yóò jẹ dájúdájú.’ 21  Jọ̀wọ́, di ojúlùmọ̀ rẹ̀, kí o sì pa àlàáfíà mọ́;Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ohun rere yóò wá bá ọ. 22  Jọ̀wọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀,Kí o sì fi àsọjáde rẹ̀ sí ọkàn-àyà rẹ.+ 23  Bí o bá padà sọ́dọ̀ Olódùmarè,+ a óò gbé ọ ró;Bí ìwọ yóò bá mú àìṣòdodo jìnnà réré sí àgọ́ rẹ, 24  Bí fífi ẹta ṣíṣeyebíye sínú ekuru bá sì wà,Bí wúrà Ófírì+ bá sì wà nínú àpáta àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá, 25  Olódùmarè pẹ̀lú yóò di ẹta rẹ ṣíṣeyebíye ní tòótọ́,Àti fàdákà, ààyò jù lọ, fún ọ.+ 26  Nítorí ìwọ yóò rí inú dídùn kíkọyọyọ rẹ+ nínú Olódùmarè nígbà náà,Ìwọ yóò sì gbé ojú rẹ sókè sí Ọlọ́run fúnra rẹ̀.+ 27  Ìwọ yóò pàrọwà sí i, òun yóò sì gbọ́ ọ;+Ìwọ yóò sì san àwọn ẹ̀jẹ́ rẹ.+ 28  Ìwọ yóò sì pinnu lórí ohun kan, yóò sì dúró fún ọ;Dájúdájú, ìmọ́lẹ̀ yóò sì tàn sí àwọn ọ̀nà rẹ.+ 29  Nítorí ìtẹ́lógo yóò wà nígbà tí o bá sọ̀rọ̀ lọ́nà ìṣefọ́nńté;+Ṣùgbọ́n ẹni tí ojú rẹ̀ ń ṣe kọ́íkọ́í ni yóò gbà là.+ 30  Yóò gba aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ènìyàn sílẹ̀,+A ó sì gbà ọ́ sílẹ̀ dájúdájú nítorí ìmọ́tónítóní ọwọ́ rẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé