Jóòbù 17:1-16

17  “Ìròbìnújẹ́ ti bá ẹ̀mi mi,+ àwọn ọjọ́ mi ni a mú wá sópin;Itẹ́ òkú wà fún mi.+   Dájúdájú, ìfiniṣẹlẹ́yà wà fún mi,+Ojú mi sì ń gbé láàárín ìwà ọ̀tẹ̀ wọn.   Jọ̀wọ́, fi ohun ìdúró mi sọ́dọ̀ ara rẹ.+Ta ni ó tún wà níbẹ̀ tí yóò bọ̀ mí lọ́wọ́+ láti jẹ́jẹ̀ẹ́?   Nítorí ìwọ ti sé ọkàn-àyà wọn kúrò nínú ọgbọ́n inú.+Ìdí nìyẹn tí o kò fi gbé wọn ga.   Ó lè sọ fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ pé kí wọ́n kó ìpín wọn,Ṣùgbọ́n ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò kọṣẹ́.+   Ó sì ti gbé mi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni àfipòwe+ fún àwọn ènìyàn,Tí mo fi di ẹni tí a ń tutọ́ sí lójú.+   Ojú mi sì di bàìbàì láti inú ìbìnújẹ́,+Gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dà bí òjìji.   Àwọn adúróṣánṣán ń wo èyí sùn-ùn pẹ̀lú kàyéfì,Àní aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ ni a sì ru sókè nítorí apẹ̀yìndà.   Olódodo ń di ọ̀nà ara rẹ̀ mú ṣinṣin,+Ẹni tí ó sì ní ọwọ́ tí ó mọ́+ ń pọ̀ sí i ní okun.+ 10  Bí ó ti wù kí ó rí, kí gbogbo yín tún bẹ̀rẹ̀. Nítorí náà, ó yá, ẹ jọ̀wọ́,Níwọ̀n bí èmi kò ti rí ọlọ́gbọ́n kankan nínú yín.+ 11  Àwọn ọjọ́ mi ti kọjá lọ,+ àwọn ìwéwèé mi ni a ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ,+Ìdàníyàn ọkàn-àyà mi. 12  Òru ni wọ́n fi ń dípò ọ̀sán pé:+‘Ìmọ́lẹ̀ sún mọ́lé ní tìtorí òkùnkùn.’ 13  Bí mo bá ń bá a lọ ní dídúró, Ṣìọ́ọ̀lù ni ilé mi;+Inú òkùnkùn+ ni èmi yóò tẹ́ àga ìrọ̀gbọ̀kú gbọọrọ mi sí. 14  Èmi yóò sì ní láti ké sí kòtò+ pé, ‘Ìwọ ni baba mi!’Àti sí ìdin+ pé, ‘Ìyá mi àti arábìnrin mi!’ 15  Nítorí náà, ibo wá ni ìrètí mi wà?+Àti ìrètí mi—ta ní rí i? 16  Wọn yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ síbi àwọn ọ̀pá gbọọrọ Ṣìọ́ọ̀lù,Nígbà tí gbogbo wa, lápapọ̀, yóò sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú ekuru pàápàá.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé